Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Múra Sílẹ̀ De Ìṣòro

Múra Sílẹ̀ De Ìṣòro

Múra Sílẹ̀ De Ìṣòro

“Mo pinnu láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, nígbà tí mo ro ti àkóbá tó lè ṣe fún ìlera ọmọ wa tuntun. Torí náà, mo lẹ àkọlé náà, ‘Má Ṣe Mu Sìgá’ sínú ilé wa. Àmọ́, kò ju wákàtí kan lọ lẹ́yìn náà tí sìgá fi bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí mu gan-an, bí mo ṣe ṣáná sí sìgá kan nìyẹn.”—Yoshimitsu, Japan.

OHUN tó ṣẹlẹ̀ sí Yoshimitsu yìí fi hàn pé àwọn ìṣòro kan máa dojú kọ ẹni tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu. Bákan náà, ìwádìí fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó tún pa dà mu sìgá lẹ́yìn tí wọ́n ti pinnu láti jáwọ́ ńbẹ̀ ló tún sọ ọ́ dàṣà. Torí náà, bó o bá ń gbìyànjú láti jáwọ́, ó ṣeé ṣe kó o kẹ́sẹ járí tó o bá múra sílẹ̀ de ìṣòro. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó sábà máa ń yọjú?

Á máa wù ẹ́ gan-an láti mu sìgá: Èyí sábà máa ń le gan-an lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tó o bá jáwọ́ nínú sìgá mímu, ó sì máa tó nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì kí ara rẹ tó balẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni kan tó máa ń mu sìgá nígbà kan sọ pé: “Ìgbà míì wà tó máa ń wu èèyàn gan-an láti mu sìgá, tó bá sì tún yá kò ní fi bẹ́ẹ̀ wuni mọ́.” Kódà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, sìgá kàn lè ṣàdédé wù ẹ́ mu. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o fara balẹ̀. Dúró fún nǹkan bí ìṣẹ́jú márùn-ún, wàá rí i pé kò ní wù ẹ́ mu mọ́.

Àwọn ìṣòro míì: Téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fi sìgá mímu sílẹ̀, oorun lè máa kùn ún ṣáá tàbí kó ṣòro fún un láti pọkàn pọ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì lè máa sanra sí i. Lára àwọn ìṣòro tó tún lè jẹ yọ ni, ara ríro, ara yíyún, ìlàágùn, ikọ́ àti ìṣesí tó ṣàdédé yí ń pa dà, èyí tí kì í jẹ́ kéèyàn ní sùúrù, tó lè mú kéèyàn tètè máa bínú tàbí tó lè fa ìsoríkọ́. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìṣòro yìí ló máa ń lọ sílẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́rin sí mẹ́fà.

Láàárín àkókò líle koko yìí, àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ:

● Máa sùn dáadáa.

● Máa mu omi tàbí omi èso dáadáa. Máa jẹ oúnjẹ tó máa ṣara lóore.

● Máa ṣe eré ìmárale níwọ̀n tó yẹ.

● Mí kanlẹ̀, kó o sì máa wò ó bíi pé ò ń rí afẹ́fẹ́ tó mọ́ tó ò ń mí sínú.

Àwọn nǹkan tó lè mú kí sìgá máa wù ẹ́ mu: Èyí kan àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tàbí èrò tó lè mú kó o fẹ́ láti mu sìgá. Bí àpẹẹrẹ, bóyá tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, tó o bá ń mu ọtí tàbí nǹkan míì, ńṣe lo máa ń mu sìgá pẹ̀lú rẹ̀. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, bó o bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu, má ṣe máa pẹ́ rárá nídìí ọtí tàbí ohun mímu mìíràn. Tó bá yá, wàá máa fẹ̀sọ̀ gbádùn àwọn ohun tó o bá ń mu.

Síbẹ̀, sìgá ṣì lè máa wù ẹ́ mu, bó bá tiẹ̀ ti pẹ́ tó o ti fi í sílẹ̀. Torben tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Lẹ́yìn ọdún mọ́kàndínlógún tí mo ṣíwọ́ sìgá mímu, ó ṣì máa ń wù mí mu nígbà tá a bá ń mu kọfí ní ibiṣẹ́.” Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé, tó bá yá sìgá kò ní wù ẹ́ mu mọ́ nígbà tó o bá ń ṣe àwọn ohun tó máa ń jẹ́ kó wù ẹ́ mu tẹ́lẹ̀, wàá sì lè tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ sìgá mímu.

Ọ̀rọ̀ ọtí mímu tún wá yàtọ̀ o. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, bó o bá ń gbìyànjú láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, ó lè gba pé kó o má ṣe mutí rárá, kó o má sì lọ síbi táwọn èèyàn ti ń mutí, torí pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ti jáwọ́ nínú sìgá ló tún máa ń pa dà sínú àṣà náà nígbà tí wọ́n bá ń mutí. Kí nìdí tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀?

● Ì báà tiẹ̀ jẹ́ ìwọ̀nba ọtí díẹ̀ lo mu, ó máa jẹ́ kí sìgá túbọ̀ máa wù ẹ́ mu.

● Táwọn èèyàn bá ń mutí, wọ́n sábà máa ń mu sìgá.

● Ọtí mímu kì í jẹ́ kéèyàn lè ronú bó ṣe yẹ, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn máa hùwà àìnítìjú. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: ‘Wáìnì máa ń gba ète rere kúrò.’—Hós. 4:11.

Àwọn tó ò ń bá kẹ́gbẹ́: Máa fọgbọ́n yan ọ̀rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, yẹra fún àwọn tó ń mu sìgá àtàwọn tó lè fi sìgá lọ̀ ẹ́. Bákan náà, yẹra fún àwọn tó lè mú kó o juwọ́ sílẹ̀ nínú ìpinnu rẹ láti jáwọ́ nínú sìgá mímu, bóyá nípa fífi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́.

Ìmọ̀lára rẹ: Ìwádìí kan fi hàn pé, ìdá méjì nínú mẹ́ta lára àwọn tó tún bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá ni nǹkan máa ń tojú sú tàbí ni inú máa ń bí kí wọ́n tó pa dà sínú àṣà náà. Bí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ tó mú kí sìgá máa wù ẹ́ mu, ńṣe ni kó o wá nǹkan míì ṣe, bóyá kó o mu omi, kó o jẹ ṣingọ́ọ̀mù tàbí kó o nasẹ̀ jáde lọ. Gbìyànjú láti máa ronú nípa ohun tó dáa, o lè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ tàbí kó o ka Bíbélì.—Sáàmù 19:14.

Ṣọ́ra fún Àwáwí

Mi ò ní fà ju ọwọ́ kan péré lọ.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Bó o bá fa sìgá lẹ́ẹ̀kan péré, ọpọlọ rẹ lè gba ìdá àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún èròjà olóró inú sìgá sínú fún wákàtí mẹ́ta. Ohun tí èyí sì sábà máa ń yọrí sí ni pé, ńṣe ni wàá tún pa dà sínú àṣà náà ní pẹrẹu.

Sìgá ni mo máa fi ń pa ìrònú rẹ́.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Ìwádìí fi hàn pé èròjà olóró inú sìgá máa ń mú kéèyàn ní àìfararọ tó pọ̀ sí i. Tó bá dà bíi pé sìgá mímu dín ìdààmú ọkàn rẹ kù, ó lè jẹ́ pé ńṣe ni àwọn ìṣòro tó máa ń yọjú nígbà téèyàn bá fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀ kàn dín kù fúngbà díẹ̀ ni.

Ọjọ́ pẹ́ tí mo ti ń mu sìgá, mi ò rò pé mo lè jáwọ́.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Béèyàn bá ń ní èrò pé nǹkan ò lè dáa, kì í jẹ́ kéèyàn lè ní ìtẹ̀síwájú. Bíbélì sọ pé: “Ìwọ ha ti jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ní ọjọ́ wàhálà bí? Agbára rẹ yóò kéré jọjọ.” (Òwe 24:10) Torí náà, má ronú pé o ò lè jáwọ́ ńbẹ̀. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu lóòótọ́ lè ṣàṣeyọrí, bó bá fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, bí irú èyí tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí.

Àwọn ìṣòro tí mò ń kojú nítorí pé mo fẹ́ fi sìgá mímu sílẹ̀ ti pọ̀ jù fún mi.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Òótọ́ ni pé, àwọn ìṣòro yẹn lè kọ́kọ́ ka èèyàn láyà, àmọ́ ká tó rí ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, gbogbo ẹ̀ máa dàwátì. Torí náà, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì! Bó bá tiẹ̀ tún ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o mu sìgá lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọ̀pọ̀ ọdún, ìmọ̀lára yẹn náà máa dàwátì láàárín ìṣẹ́jú bíi mélòó kan, ìyẹn bí o kò bá tún tanná sí sìgá.

Mo ní àìsàn ọpọlọ.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Bó bá jẹ́ pé ò ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ fún oríṣi àìsàn ọpọlọ kan, bóyá ìsoríkọ́ tàbí ọpọlọ dídàrú, sọ fún dókítà rẹ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè jáwọ́ nínú sìgá mímu. Ó ṣeé ṣe kí inú rẹ̀ dùn gan-an láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, bóyá kó ṣe ìyípadà díẹ̀ nínú ìtọ́jú tó ń fún ẹ, kí ìpinnu tó o ṣe yìí má bàa ṣe ìpalára kankan fún ìlera rẹ tàbí kó má bàa ṣèdíwọ́ fún oògùn tó ò ń lò.

Bí mo bá tún fẹnu kan sìgá pẹ́nrẹ́n, ńṣe ni màá gbà pé mi ò lè ṣàṣeyọrí.

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Bó bá ṣẹlẹ̀ pé o tún mu sìgá nígbà tó o ní ìṣòro kan, ọ̀rọ̀ rẹ kò tíì kọjá àtúnṣe, ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn nìyẹn. Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì, ńṣe ni kó o ṣara gírí. Béèyàn bá ṣubú, kò túmọ̀ sí pé kò lè ṣàṣeyọrí mọ́, àmọ́ ẹni tó ṣubú, tó sì kọ̀ láti dìde ni kò lè ṣàṣeyọrí. Torí náà, túbọ̀ máa sapá. Bó pẹ́ bó yá, wàá ṣàṣeyọrí!

Wo àpẹẹrẹ Romualdo, ẹni tó fi ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] mu sìgá, àmọ́ tó ti jáwọ́ nínú rẹ̀ ní ohun tó lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Mi ò lè ka iye ìgbà tí mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í mu sìgá, gbogbo ìgbà tí mo bá tún ṣe bẹ́ẹ̀ ni inú mi máa ń bà jẹ́, tó sì máa ń ṣe mí bíi pé aláṣetì ni mí. Àmọ́, nígbà tí mo ṣe ìpinnu tó lágbára pé mo fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run, tí mi ò sì yéé gbàdúrà pé kó ràn mí lọ́wọ́, mo bọ́ lọ́wọ́ sìgá mímu ní gbẹ̀yìn-gbẹ́yín.”

Nínú àpilẹ̀kọ kan tó kù nínú ọ̀wọ́ yìí, a máa ṣàyẹ̀wò àwọn àbá tó wúlò díẹ̀ sí i tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣàṣeyọrí nínú ìsapá rẹ láti jáwọ́ nínú sìgá mímu.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ó LÉWU NÍ GBOGBO Ọ̀NÀ

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n gbà ń lo tábà. Wọ́n tiẹ̀ máa ń ta àwọn nǹkan tí wọ́n mú jáde látara tábà láwọn ilé ìtajà tí wọ́n ti máa ń ta àwọn oúnjẹ tó lè mú kéèyàn túbọ̀ ní ìlera tó dáa àti oògùn ìbílẹ̀. Síbẹ̀, Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé: “Ọ̀nà yòówù kéèyàn gbà lo tábà, ewu wà ńbẹ̀.” Èyíkéyìí lára àwọn àrùn tí tábà máa ń fà ló lè já sí ikú, irú bí àrùn jẹjẹrẹ àti àrùn tó jẹ mọ́ ọkàn àtàwọn òpó ẹ̀jẹ̀. Àwọn aboyún tó ń mu sìgá tiẹ̀ lè ṣèpalára fún ọmọ wọn. Àwọn ọ̀nà wo tiẹ̀ ni wọ́n máa ń gbà lo àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe?

Bídì (sìgá àwọn ará Éṣíà): Oríṣi sìgá tí kò fi bẹ́ẹ̀ tóbi yìí ló wọ́pọ̀ ní ilẹ̀ Éṣíà. Sìgá yìí yàtọ̀, torí pé eérú, èròjà olóró inú sìgá àti èéfín tó máa ń ti ara rẹ̀ jáde pọ̀ ju tàwọn sìgá yòókù lọ.

Tábà: Wọ́n máa ń lọ̀ ọ́ mọ́ àwọn nǹkan míì, wọ́n á wá fi ewé tábà pọ́n ọn tàbí kí wọ́n pọ́n ọn sínú bébà tí wọ́n fi ewé tábà ṣe. Èròjà tó wà nínú tábà yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú àwọn sìgá yòókù, ìdí nìyẹn tí èròjà olóró inú tábà fi lè gba ẹnu wọ inú ara láì tiẹ̀ ṣáná sí i rárá.

Sìgá tí wọ́n lọ òdòdó olóòórùn dídùn mọ́: Èyí jẹ́ àpapọ̀ tábà àti òdòdó olóòórùn dídùn. Tábà inú rẹ̀ jẹ́ ìdá mẹ́fà nínú mẹ́wàá nígbà tí ìdá mẹ́rin yòókù jẹ́ òdòdó olóòórùn dídùn. Eérú, èròjà olóró àti èéfín tó máa ń jáde látara rẹ̀ pọ̀ ju tàwọn sìgá yòókù lọ.

Ìkòkò: Mímu ìkòkò kì í ṣe àṣà tó dáa téèyàn lè fi rọ́pò sìgá mímu, méjèèjì ló lè fa àrùn jẹjẹrẹ àtàwọn àrùn míì.

Tábà tí kò léèéfín: Irú bíi tábà tí wọ́n máa ń jẹ, áṣáà àti gutkha, ìyẹn tábà tí wọ́n máa ń lọ èròjà atasánsán mọ́, èyí tó wọ́pọ̀ ní apá Gúúsù Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Éṣíà. Látẹnu ni èròjà olóró inú rẹ̀ ti máa ń wọ inú ẹ̀jẹ̀ lọ. Gbogbo ọ̀nà ni tábà tí kò léèéfín fi léwu bíi tàwọn oríṣi tábà yòókù.

Àwọn ìkòkò olómi: Bí wọ́n ṣe ṣe èyí ni pé, èéfín tábà á gba àárín omi kọjá kó tó di pé èèyàn fà á ságbárí. Síbẹ̀ kò dájú pé èyí máa dín èròjà olóró tó ń lọ sínú ẹ̀dọ̀ fóró kù, tó fi mọ́ èròjà tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

BÓ O ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÚN ẸNI TÓ BÁ FẸ́ JÁWỌ́

Ní èrò tó dáa. Ó sàn kó o máa gbóríyìn, kó o sì máa sọ̀rọ̀ rere fún ẹni náà ju kó o máa ṣàròyé, kó o sì máa nà án lẹ́gba ọ̀rọ̀ lọ. Ó dáa kó o sọ pé, “Mo ronú pé wàá ṣàṣeyọrí tó o bá tún gbìyànjú” ju kó o sọ pé, “O tún ti fìdí rẹmi, àbí?”

Máa dárí jini. Ńṣe ni kó o gbójú fo ìbínú tàbí ìjákulẹ̀ látọ̀dọ̀ ẹni tó ń sapá láti jáwọ́ nínú sìgá mímu. Máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára bíi, “Mo mọ̀ pé kò rọrùn, àmọ́ inú mi dùn fún bó o ṣe ṣe é.” Má ṣe sọ pé, “Ó kúkú sàn fún ẹ nígbà tó ò ń mu sìgá ju báyìí lọ!”

Jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Ńṣe ni kó o máa ní sùúrù kó o sì máa fìfẹ́ hàn sí ẹni tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu “ní gbogbo ìgbà,” tàbí àsìkò yòówù kó jẹ́, kó o sì máa fara da ohun yòówù kí onítọ̀hún ṣe sí ọ.