Ohun Tó Mú Kí N Fi Iṣẹ́ Olówó Gọbọi Sílẹ̀
Ohun Tó Mú Kí N Fi Iṣẹ́ Olówó Gọbọi Sílẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí Martha Teresa Márquez ṣe sọ
ỌJỌ́ pẹ́ tí mo ti nífẹ̀ẹ́ orin kíkọ, débi pé láti kékeré ló ti máa ń wù mí pé kí n máa kọrin lórí rédíò. Iléèwé jẹ́lé-ó-sinmi nìkan ni mo lọ, àmọ́ nígbà tó yá mo gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí orin kíkọ ní ìlú Mexico City lábẹ́ ìdarí ẹni tó ń bójú tó ẹgbẹ́ akọrin orílẹ̀-èdè yẹn.
Ní ọdún 1969, nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24], ọ̀rẹ́ mi kan tó jẹ́ oníjó ní kí n wá kópa nínú ìdíje orin kíkọ kan ní ilé àrójẹ tí wọ́n ń pè ní La Rampa Azul, táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mọ owó nígbà yẹn. Orin Tomás Méndez ti ilẹ̀ Mẹ́síkò tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Cucurrucucú Paloma, táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó ni mo kọ, àwọn èèyàn sì gbádùn ẹ̀ gan-an. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ orin kíkọ nìyẹn. Mo máa ń dá kọrin, orúkọ tí mo sì ń jẹ́ nídìí iṣẹ́ orin kíkọ nígbà náà ni Romelia Romel.
Mo bá Tomás Méndez ṣiṣẹ́, bákan náà mo tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn olórin ilẹ̀ Mẹ́síkò míì tí wọ́n mọ bá a ṣe ń kó ọ̀rọ̀ orin jọ, tí wọ́n sì mọ orin kọ, irú bíi Cuco Sánchez àti Juan Gabriel. Inú mi wá ń dùn gan-an pé mo ti di ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń wà nínú àwọn àkọlé tó wà káàkiri ìlú àti nínú àwọn ìwé ìròyìn. Mo máa ń kọrin ní àwọn ilé ìgbafẹ́ alaalẹ́, lórí rédíò àti káàkiri orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò àti Belize. Mo tún ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Leonorilda Ochoa tó jẹ́ ẹlẹ́fẹ̀ tó gbajúmọ̀ lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣeré lórí tẹlifíṣọ̀n ní Mẹ́síkò.
Nígbà tó yá, mo di gbajúmọ̀ dé àyè kan, owó tó tówó sì ń wọlé fún mi, owó náà sì tó fún mi láti ra àwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́ lóríṣiríṣi, kóòtù olówó iyebíye àti ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì olówó iyebíye. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ní gbogbo nǹkan tí mo nílò, mi ò láyọ̀. Mo nímọ̀lára pé ìgbésí ayé mi ò tíì nítumọ̀. Inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, àmọ́ ojú máa ń tì mí láti lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Àwọn ìwà àìmọ́ tí mò ń hù jẹ́ kí ń máa rò pé mi ò lè sin Ọlọ́run.
Bí Mó Ṣe Dẹni Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Nígbà tí mò ń fi orin àkọ́kọ́ tí mo fẹ́ ṣe sórí àwo dánra wò, mo sọ ohun tó ń dùn mí lọ́kàn fún ọ̀rẹ́ mi kan tóun náà jẹ́ olórin, ìyẹn Lorena Wong. Mo sọ fún un pé ó wù mí kí n di ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kí n lè máa ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Ó wá kígbe pé: “Ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kẹ̀? Ṣó o mohun tó ò ń sọ ṣá!”
Lẹ́yìn náà ó bi mí pé: “Ṣó o mọ orúkọ Ọlọ́run?”
Mo dá a lóhùn pé: “Olúwa wa Jésù Kristi ni.”
Ó wá dáhùn pé: “Rárá o, Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù.”
Mo wá sọ pé: “Jèhófà kẹ̀?” Mi ò gbọ́ orúkọ yẹn rí. Lorena fún mi ní Bíbélì kan, ó sì ṣèlérí pé òun máa ní kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá bẹ̀ mí wò. a
Gbogbo ìgbà tí mo bá ti rí Lorena ni mo máa ń bi í pé, “Ìgbà wo lẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa wá mi wá?” Mo fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run.
Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì fúnra mi, mo sì wá rí i pé Jèhófà lorúkọ Ọlọ́run lóòótọ́. (Sáàmù 83:18) Èyí yà mí lẹ́nu. Nígbà tí mo ka àwọn Òfin Mẹ́wàá, ó ṣe mí ní kàyéfì láti rí òfin tó sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.” (Ẹ́kísódù 20:14) Nígbà tí mò ń wí yìí, ọ̀dọ̀ ọkùnrin kan tó ti níyàwó ni mò ń gbé, òun sì ni bàbá ọmọ mi ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ oṣù mẹ́jọ. Èyí sì ni ọmọ mi kejì. Mo ti bí ọmọ ọkùnrin kan fún ẹlòmíì tí mi ò bá ṣègbéyàwó.
Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mò ń múra orin tí mo fẹ́ kọ níbi eré kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ṣe, ẹnì kan kanlẹ̀kùn mi. Ẹni tó ń kọ́ Lorena lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni, ìyẹn Mauricio Linares àti ìyàwó rẹ̀. Wọ́n fi ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé hàn mí, wọ́n sì fún mi ní ìwé náà, Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye. b Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún mi láti lóye àwọn ọ̀rọ̀ tó le nínú ìwé náà, alẹ́ ọjọ́ kan ni mo fi kà á tán. Láti ìgbà náà lọ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.
Mo Yí Ìgbésí Ayé Mi Pa Dà
Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń kọ́ mi bí mo ṣe lè túbọ̀ mọ̀wé kà, mo wá rí i pé mo gbọ́dọ̀ yí àwọn nǹkan kan pa dà ní ìgbésí ayé mi, kí n lè múnú Jèhófà dùn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ère, àmì ẹ̀yẹ àtàwọn oògùn oríire tí mo ní dànù láìka pé góòlù ni wọ́n fi ṣe é.
Ó ṣòro fún mi gan-an láti jáwọ́ nínú sìgá mímu àti ọtí àmujù. Kò sígbà tí mo kọjá níwájú ibi tí wọ́n ti ń ta ọtí, tí ọtí kì í wù mí mu. Mi ò bá gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi kẹ́gbẹ́ mọ́, torí wọn ò mọ̀ ju kí wọ́n máa pè mí láti wá mutí tàbí kí wọ́n máa pè mí lọ sáwọn ilé àrójẹ ńlá-ńlá láti lọ jẹun, ká sì mutí. Mo mọ̀ pé tí mo bá tẹ̀ lé wọn pẹ́nrẹ́n, màá mu àmupara.
Ó tún ṣòro fún mi láti ṣíwọ́ lílọ sí àpèjẹ àwọn èèyàn ńláńlá àtàwọn gbajúmọ̀. Nígbà tí gbajúgbajà akànṣẹ́ kan lórílẹ̀-èdè Cuba pè mí síbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀, mo sọ fún Jèhófà pé: “Jọ̀ọ́ Jèhófà, jẹ́ kí n lọ lẹ́ẹ̀kan yìí. Mo ṣèlérí pé mi ò tún ní lọ sírú ayẹyẹ yìí tàbí kí n lọ́wọ́ sí ìwà tínú rẹ ò dùn sí.” Mi ò sì ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́ lóòótọ́.
Mo jáwọ́ níní àjọṣe pẹ̀lú bàbá ọmọ mi kejì. Mo fi í sílẹ̀ láìka bó ṣe lówó tó sí àti àwọn nǹkan tó ṣèlérí láti fún mi bí mi ò bá fi òun sílẹ̀. Ó ṣòro gan-an fún mi láti fi ọkùnrin yìí sílẹ̀, torí mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an, òun náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó fi ìgbéraga sọ̀rọ̀ pé: “Èmi ni Ọlọ́run rẹ! Èmi sì ni Kristi rẹ!”
Mo wá dá a lóhùn pé, “Ó ṣeé ṣe kọ́rọ̀ rí bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí, Jèhófà ni Ọlọ́run mi.” Ó halẹ̀ mọ́ mi pé, òun máa gba ọmọ tí mo bí fún òun lọ́wọ́ mi àti pé òun á ṣe mí léṣe.
Nígbà yẹn, àwọn kan sọ fún mi pé iṣẹ́ orin kíkọ kò yàtọ̀ sí àwọn iṣẹ́ míì, pé mo jẹ́ Ẹlẹ́rìí kò ní kí n má kọrin. Àmọ́, àwọn míì rán mi létí pé: “Kò sí nǹkan tó máa gbà ẹ́ lọ́wọ́ sìgá mímu, ọtí àtàwọn ìwàkíwà táwọn tó gba tìẹ máa fẹ́ kó o máa hù.” Mo rí i pé ọgbọ́n wà nínú ìmọ̀ràn kejì yìí.
Nígbà tí mo ṣì jẹ́ gbajúgbajà olórin, báwọn ọkùnrin ṣe ń pè mí lọ́tùn-ún ni wọ́n ń pè mí lósì. Mo pinnu pé mi ò ní lọ́wọ́ sírú nǹkan báyìí mọ́, torí pé ó lè sún mi dẹ́ṣẹ̀. Torí náà, lọ́dún 1975, mo jáwọ́ nínú àdéhùn tí mo fọwọ́ sí láti lọ kọrin káàkiri orílẹ̀-èdè China, ní oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, mo ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Àwọn Ìṣòro àti Ayọ̀ Tí Mo Ní
Báwo ni màá ṣe máa gbọ́ bùkátà ara mi àti ti ìdílé mi? Kí n ṣáà sọ pé mi ò kàwé rárá ni, mi ò sì mọ nǹkan míì ṣe yàtọ̀ sí kí n kọrin. Èmi ni mò
ń gbọ́ bùkátà ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ lrma àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pẹ̀lú àwọn ọmọ tèmi méjèèjì. Ó wá di dandan fún wa láti kó kúrò ní ilé olówó ńlá tá à ń gbé lọ sínú yàrá kékeré méjì. Ó ṣòro gan-an fún mi láti fara da ìyípadà látorí gbígbé ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ sí ìgbésí ayé ẹni tí kò rí já jẹ. Ẹ̀gbọ́n mi àtàwọn ọmọ kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ sí mi, wọ́n sì ń rọ̀ mí ṣáá pé kí n máa bá iṣẹ́ orin kíkọ lọ, àmọ́ mi ò yẹsẹ̀ lórí ìpinnu mi láti ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ kí n lè sin Jèhófà.Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ta àwọn nǹkan ìní mi tó níye lórí, irú bí àwọn nǹkan ẹ̀ṣọ́, kóòtù olówó iyebíye, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, a sì ń fí owó wọn jẹun. Nígbà tó yá, owó ọ̀hún tán. Ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀sín tí bàbá ọmọ mi kejì lè fẹ́ fi wá ṣe, lọ́dún 1981, a ṣí lọ sí ìlú kan tó wà lápá ibòmíì lórílẹ̀-èdè wa, a mọ̀ pé kò ní lè wá wa débẹ̀.
Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú yìí ló wá kọ́ mi bí mo ṣe lè máa ṣe àwọn ìpápánu bíi tamale, dónọ́ọ̀tì àtàwọn oúnjẹ míì fún títà. Nígbà tó yá mo rí iṣẹ́ alẹ́ sí ilé-iṣẹ́ kan, àmọ́ iṣẹ́ náà ò jẹ́ kí n lè máa pésẹ̀ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, ó sì ń dí ìjọsìn mi lọ́wọ́. Èyí mú ki n fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe tamale nílé. Màá wá kó o sínú apẹ̀rẹ̀ láti lọ tà á ní òpópónà. Iṣẹ́ yìí ni mo fi ń gbọ́ bùkátà ara mi lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.
Mi Ò Kábàámọ̀ Ìpinnu Tí Mo Ṣe
Bí wọ́n bá bi mí pé, kí ni èrò mi nípa bí mo ṣe fi iṣẹ́ orin kíkọ tó lè sọ mí dolówó sílẹ̀, mo máa ń sọ fún wọn pé, kò sí nǹkan náà láyé yìí tí mo lè torí rẹ̀ yááfì òye tí mo ní nípa Jèhófà àtàwọn ohun àgbàyanu tó ní lọ́kàn láti ṣe. Inú mi ń dùn gan-an bí mo ṣe ń rí i táwọn ọmọ mi túbọ̀ ń lóye Bíbélì, tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, tí wọ́n sì fẹ́ onígbàgbọ́ bíi tiwọn. Àwọn ọmọ mi méjèèjì, pẹ̀lú ìyàwó wọn ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa sin Jèhófà Ọlọ́run wa.
Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n ọdún báyìí tí mo ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, èyí ni orúkọ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pe àwọn tó bá ń lo púpọ̀ nínú àkókò wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ọlọ́run ti mú kó ṣeé ṣe fún mi láti ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì kí wọ́n sì ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ sí Ọlọ́run, lára wọn ni Irma, ẹ̀gbọ́n mi àti ọmọ rẹ̀ obìnrin. Inú mi máa ń dùn gan-an tí mo bá ń rí i pé àwọn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n dà bí ọmọ fún mi, kò yẹsẹ̀ nínú òtítọ́, púpọ̀ nínú wọn ló ti di aṣáájú-ọ̀nà. (3 Jòhánù 4) Ní báyìí tí mo ti pé ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64], mò ń kọ́ àwọn èèyàn méjìdínlógún [18] lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Mo ti wá mọ àwọn ohun tí mi ò mọ̀ nípa Ọlọ́run nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ tó ń kọrin, ọkàn mi sì ti balẹ̀ pé mo ti lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ bí mo ṣe ń fẹ́ nígbà yẹn, nípa ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Jésù láti ‘lọ sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’ (Mátíù 28:19, 20) Mo dúpẹ́ gan-an pé Jèhófà tì mí lẹ́yìn láti àwọn ọdún yìí wá, ó sì ń bá a lọ láti ṣe bẹ́ẹ̀! Ní tòdodo, mo ti ‘tọ́ ọ wò, mo sì rí i pé ó jẹ́ ẹni rere.’—Sáàmù 34:8.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tó yá, Lorena Wong di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Èmi àtàwọn ọmọ mi, ìyàwó wọn àti ẹ̀gbọ́n mi tá à ṣì jọ ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Mo ṣì ń ta ‘tamale’ lójú pópó láti gbọ́ bùkátà mi lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún