Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà!”

“Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà!”

Àpéjọ Àgbègbè

“Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà!”

ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

● Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àpéjọ àgbègbè ọlọ́jọ́ mẹ́ta yìí, tá a ṣètò pé kó bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́jọ́ kọkànlélógún [21] sí ìkẹtàlélógún [23] oṣù May la máa ṣe fún àwọn oṣù mélòó kan lẹ́yìn ìgbà náà kárí ayé. Orin la máa fi bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà láàárọ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ní déédéé aago mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Inú Sáàmù 73:28 la ti mú ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ Friday, tá a pè ní, “Sísúnmọ́ Ọlọ́run Dára fún Mi.” Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ tí alága àpéjọ máa fi ṣí ìpàdé yìí, a máa gbọ́ àwọn àsọyé tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Àwọn Àpéjọ Àgbègbè Ń Mú Ká Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà” àti “Ọmọ Fẹ́ Láti Ṣí Ọlọ́run Payá.” Lẹ́yìn náà, àpínsọ àsọyé tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Tó Sún Mọ́ Jèhófà Tímọ́tímọ́” máa jẹ́ ká mọ bí Ábúráhámù, Rúùtù, Hesekáyà àti Màríà ṣe sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́. Lájorí àsọyé tá a máa fi kádìí ìpàdé àárọ̀ ni, “Bí Jèhófà Ṣe Ń Sún Mọ́ Wa.”

Lọ́sàn-án Friday, àsọyé tá a máa kọ́kọ́ gbọ́ ni, “Ìdáhùn Sáwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ Nípa Jèhófà,” lẹ́yìn ìyẹn la máa wá gbọ́ àwọn àsọyé tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Jẹ́ Kí Ìbáwí Jèhófà Mọ Ẹ́” àti “Má Ṣe Dẹni Tó ‘Kún fún Ìhónú sí Jèhófà.’” Àpínsọ àsọyé alápá márùn-ún ló máa tẹ̀ lé e, àkòrí rẹ̀ sì ni, “Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Máa Ń Jẹ́ Kí Ìdílé Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà.” Apá márùn-ún tó pín sí ni, “Jèhófà, Olùbánisọ̀rọ̀ Tó Ta Yọ,” “Ẹ̀yin Ọkọ, Ẹ Máa Bá Aya Yín Sọ̀rọ̀!,” “Ẹ̀yin Aya, Ẹ Máa Bá Ọkọ Yín Sọ̀rọ̀!,” “Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Máa Bá Àwọn Ọmọ Yín Sọ̀rọ̀!” àti “Ẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Máa Bá Àwọn Òbí Yín Sọ̀rọ̀!” Àsọyé tá a máa fi kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Friday ni, “Ìṣẹ̀dá Ń Jẹ́ Ká Mọ̀ Nípa ‘Ọlọ́run Alààyè’!”

Ẹṣin ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Sátidé ni “Ìbárẹ́ Tímọ́tímọ́ Rẹ̀ Wà Pẹ̀lú Àwọn Adúróṣánṣán,” a gbé e ka ìwé Òwe 3:32. Apá márùn-ún tí àpínsọ àsọyé tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè ‘Padà Bá Ọlọ́run Rẹ́’” máa pín sí ni, “Wọ́n Di Àjèjì, Wọn Kò sì Ní Ìrètí,” “Ó Bi Wọ́n Ní Ìbéèrè,” “Ṣe Ojúṣe Rẹ Tí O Bá Ń Bá Ẹnì Kan Ṣiṣẹ́ Lóde Ẹ̀rí,” “Ẹ Fi Ìwà Rere Yín Jèrè Wọn” àti “Tẹra Mọ́ Ìsapá Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́.” Lẹ́yìn àwọn àsọyé náà, àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ tí a óò tún jíròrò ni, “Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Máa Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà” àti “‘Kò Sí Ohun Ìkọ̀sẹ̀’ fún Àwọn Tó Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.” Àsọyé tó dá lórí ìrìbọmi la máa fi kádìí ìpàdé àárọ̀, lẹ́yìn ìyẹn, àwọn tó bá kúnjú ìwọ̀n máa láǹfààní láti ṣèrìbọmi.

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán Sátidé máa ní àpínsọ àsọyé alápá mẹ́jọ tá a fún ní àkòrí náà, “Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Mú Ọ Jìnnà sí Jèhófà,” apá mẹ́jọ tó sì máa pín sí ni, “Ọgbọ́n Àrékérekè Sátánì,” “Ìgbéraga,” “Owó,” “Ọ̀rọ̀ ìlera,” “Iṣẹ́,” “Eré Ìnàjú,” “Ìdílé” àti “Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ.” Àkànṣe ìtàn tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Má Ṣe Rẹ̀wẹ̀sì Nígbà Tí Jèhófà Bá Tọ́ Ọ Sọ́nà!” ló máa tẹ̀ lé e. Àsọyé tá a máa fi kádìí ìpàdé ọjọ́ náà ni, “Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà Bíi Ti Jeremáyà.”

Inú ìwé Jóṣúà 23:8 la ti mú ẹṣin ọ̀rọ̀ fún ọjọ́ Sunday tó sọ pé, “Jèhófà . . . Ni Kí Ẹ Rọ̀ Mọ́.” Lẹ́yìn orin àti àdúrà tá a máa fi bẹ̀rẹ̀ ìpàdé àárọ̀, àpínsọ àsọyé náà, “Mọyì Àwọn Ànímọ́ Tó Fani Mọ́ra Tí Jèhófà Ní” máa jíròrò mẹ́jọ lára àwọn ànímọ́ náà, ìyẹn “Ó Ṣeé Sún Mọ́,” “Ó Ní Ẹ̀mí Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò,” “Ó Jẹ́ Onímọrírì,” “Ó Jẹ́ Ọ̀làwọ́,” “Kì Í Ṣojúsàájú,” “Ó Ń Dárí Jini,” “Ó Ń Fòye Báni Lò” àti “Ó Jẹ́ Adúróṣinṣin.” Àsọyé fún gbogbo ènìyàn tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Báwo Lo Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run?” ló máa tẹ̀ lé e. Àkópọ̀ Ilé Ìṣọ́ tá a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ la máa fi kádìí ìpàdé àárọ̀ ọjọ́ Sunday.

Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tá a máa gbádùn lọ́sàn-án Sunday ni àwòkẹ́kọ̀ọ́, èyí tí àwọn tó máa kópa nínú rẹ̀ ti máa múra bíi tàwọn tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní. Ó dá lórí báwọn Kristẹni ṣe sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù, àkòrí rẹ̀ ni, “Ẹ Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́, Ẹ Má Ṣe Rìn Nípa Ohun Tí Ẹ̀ Ń Rí.” Lẹ́yìn àwòkẹ́kọ̀ọ́ yìí, Àsọyé tá a máa fi kádìí àpéjọ àgbègbè náà ni, “Má Ṣe Fi ‘Ibi Ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ’ Sílẹ̀.”

Bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò bó o ṣe máa wà níbẹ̀. Tó o bá fẹ́ mọ ibi tó sún mọ́ ẹ jù lọ nínú àwọn ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ yìí, béèrè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí. A kọ àwọn ibi tá a ti máa ṣe é lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà sórí ìkànnì www.pr418.com lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.