Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wá Ìrànlọ́wọ́

Wá Ìrànlọ́wọ́

Wá Ìrànlọ́wọ́

“Bí ẹnì kan bá . . . lè borí ẹni tí ó dá wà, ẹni méjì tí ó wà pa pọ̀ lè mú ìdúró wọn láti dojú kọ ọ́.”—Oníwàásù 4:12.

PẸ̀LÚ ìtìlẹ́yìn àwọn míì, ó lè ṣeé ṣe fún wa láti borí ọ̀tá, ì báà jẹ́ èèyàn ni ọ̀tá náà tàbí ohun míì. Torí náà, bó o bá fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu, á dáa kó o wá ìrànlọ́wọ́ tẹbí-tọ̀rẹ́ tàbí ẹlòmíì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tọkàntọkàn tó sì jẹ́ onísùúrù.

O lè wá ìrànlọ́wọ́ àwọn tó ti jáwọ́ nínú sìgá mímu, torí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ á mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ, wọ́n á sì tún jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè jáwọ́. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Torben lórílẹ̀-èdè Denmark sọ pé: “Ìrànlọ́wọ́ tó wúlò gan-an làwọn míì ṣe fún mi.” Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Abraham lórílẹ̀-èdè India sọ pé: “Ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí ìdílé mi àtàwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni fi hàn sí mi ló jẹ́ kí n jáwọ́ nínú sìgá mímu.” Àmọ́ nígbà míì, ohun téèyàn nílò ju ìrànlọ́wọ́ tẹbí-tọ̀rẹ́ lọ.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bhagwandas sọ pé: “Ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] ni mo fi mu sìgá, àmọ́ nígbà tí mo wá mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwà àìmọ́, mo pinnu láti jáwọ́. Mo gbìyànjú láti dín iye sìgá tí mò ń mu kù. Mo fi àwọn tí mò ń bá kẹ́gbẹ́ tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ àwọn agbaninímọ̀ràn. Àmọ́ gbogbo èyí kò ṣiṣẹ́ rárá. Nígbà tó yá, lọ́jọ́ kan mo sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún Jèhófà Ọlọ́run, mo bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè jáwọ́. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, mo jáwọ́ nínú sìgá mímu!”

Ohun míì tó yẹ kó o ṣe ni pé, kó o múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kó o dojú kọ. Kí ni àwọn ìṣòro wọ̀nyí? A ó ṣàlàyé nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

ǸJẸ́ Ó YẸ KÓ O LO OÒGÙN?

Bí ọ̀pọ̀ èèyàn tó fẹ́ jáwọ́ nínú sìgá mímu ṣe ń lo oògùn lóríṣiríṣi, irú bí èròjà olóró inú sìgá tí wọ́n máa ń fi sára awọ, ti wá sọ ṣíṣe àwọn oògùn náà di iṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé. Kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn èyíkéyìí, á dáa kó o ṣàyẹ̀wò àwọn ìbéèrè yìí:

Àwọn àǹfààní wo ló wà níbẹ̀? Wọ́n ní àwọn ìtọ́jú kan tó máa ń jẹ́ kéèyàn jáwọ́ nínú sìgá mímu máa ń jẹ́ kí àìfararọ tó máa ń wáyé nígbà téèyàn bá fẹ́ jáwọ́ dín kù. Àmọ́ ṣá, àríyànjiyàn ṣì wà lórí bí àǹfààní rẹ̀ á ṣe pẹ́ tó.

Àwọn ewu wo ló wà níbẹ̀? Àwọn oògùn kan wà tó máa ń fa àwọn ìṣòro, irú bíi kí èébì máa gbéni, ìdààmú ọkàn tàbí kéèyàn máa ronú láti pa ara rẹ̀. Tún fi sọ́kàn pé, ńṣe ni àwọn ìtọ́jú tí wọ́n máa ń fi èròjà olóró inú sìgá ṣe wulẹ̀ jẹ́ lílo oògùn olóró lọ́nà míì, èyí pẹ̀lú sì léwu. Òótọ́ ibẹ̀ ni pe, ńṣe làwọn tó bá ń lo irú àwọn oògùn yìí ṣì ń sọ oògùn olóró di bára kú.

Àwọn àfidípò wo ló wà? Nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn kan tó ti jáwọ́ nínú sìgá mímu, ìdá méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] nínú ọgọ́rùn-ún [100] ló sọ pé ńṣe làwọn kàn jáwọ́ ńbẹ̀, àwọn ò lo oògùn kankan.