Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Wo Ni Ẹ̀mí Èṣù?

Àwọn Wo Ni Ẹ̀mí Èṣù?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Àwọn Wo Ni Ẹ̀mí Èṣù?

ÀWỌN èèyàn látinú onírúurú ẹ̀sìn gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí kan wà tí wọ́n máa ń ṣoore, àwọn kan sì wà tí wọ́n máa ń ṣe ìkà. Bákan náà, wọ́n tún gbà pé ṣèkà-ṣoore làwọn míì. Lára àwọn orúkọ tí wọ́n máa ń pe irú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí ni àkúdàáyà, àǹjọ̀nú, iwin tàbí ẹ̀mí èṣù. Àwọn èèyàn kan sì rò pé ìgbàgbọ́ asán ló jẹ́ láti gbà pé ẹ̀mí àìrí wà àti pé àwọn èèyàn kàn ló ń hùmọ̀ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Kí ni Bíbélì sọ?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ẹ̀mí ni Ẹlẹ́dàá àti pé àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ló fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀. (Jòhánù 4:24; Hébérù 1:13, 14) Síwájú sí i, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀mí búburú, láwọn ibì kan ó pè wọ́n ní ẹ̀mí èṣù. (1 Kọ́ríńtì 10:20, 21; Jákọ́bù 2:19) Àmọ́ o, Bíbélì ò kọ́ wa pé Ọlọ́run ló dá àwọn ẹ̀mí èṣù. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn wo ni ẹ̀mí èṣù, ibo ni wọ́n sì ti wá?

“Àwọn Áńgẹ́lì Tó Dẹ́ṣẹ̀”

Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí lọ́nà tí wọ́n á fi lè dá pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe, wọ́n lè yàn láti ṣe rere tàbí búburú. Ó bani nínú jẹ́ pé, lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ìran èèyàn, àwọn áńgẹ́lì tí Bíbélì kò sọ iye wọn, yàn láti ṣe búburú nípa ṣíṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run.

Ẹ̀dá ẹ̀mí tó kọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run tó sì burú jù lọ ló di Sátánì. Jésù Kristi sọ pé: ‘Kò dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.’ (Jòhánù 8:44) Kí ló mú kí Sátánì kẹ̀yìn sí Ọlọ́run? Ojú kòkòrò tó ní mú kó fẹ́ gba ìjọsìn tí Ẹlẹ́dàá nìkan lẹ́tọ̀ọ́ sí, èyí sì mú kó fẹ́ láti bá Ọlọ́run dọ́gba. Nípa báyìí ó sọ ara rẹ̀ di “Sátánì,” ìyẹn ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí “alátakò.” Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, kí Ìkún Omi ọjọ́ Nóà tó wáyé, àwọn áńgẹ́lì míì dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀, wọ́n fi ipò wọn ní ọ̀run sílẹ̀, wọ́n gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, wọ́n sì wá gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-4; Jákọ́bù 1:13-15) Nígbà tí Ìkún Omi náà wáyé, “àwọn áńgẹ́lì tí ó ṣẹ̀” nípa sísọ ara wọn di èèyàn pa dà sí ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí. (2 Pétérù 2:4; Jẹ́nẹ́sísì 7:17-24) Nígbà tó yá, àwọn ni wọ́n wá ń pè ní ẹ̀mí èṣù.—Diutarónómì 32:17; Máàkù 1:34.

Àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn yẹn wá bá ara wọn ní ipò tó yàtọ̀ pátápátá sí ipò tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀. Júúdà 6 sọ pé: “Àwọn áńgẹ́lì tí kò . . . dúró ní ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì ni [Ọlọ́run] ti fi pa mọ́ de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá náà pẹ̀lú àwọn ìdè ayérayé lábẹ́ òkùnkùn biribiri.” Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run kò gba àwọn ẹ̀mí èṣù yẹn láyè láti máa gbádùn àwọn àǹfààní tí wọ́n ní tẹ́lẹ̀ ní ọ̀run, àmọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ó fi wọ́n sínú “àwọn kòtò òkùnkùn biribiri,” ìyẹn ni pé kò jẹ́ kí wọ́n ní òye kankan nípa tẹ̀mí.

Wọ́n “Ń Ṣi Gbogbo Ilẹ̀ Ayé Tí A Ń Gbé Pátá Lọ́nà”

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kò jẹ́ kí àwọn áńgẹ́lì yẹn tún sọ ara wọn di èèyàn mọ́, síbẹ̀ wọ́n ṣì lágbára gan-an, wọ́n sì tún nípa tó pọ̀ lórí èrò àti ìgbé ayé àwọn èèyàn. Kódà, Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9; 16:14) Lọ́nà wo? Ohun tí wọ́n sábà máa ń lò ni “àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù.” (1 Tímótì 4:1) Àwọn ẹ̀kọ́ èké yìí, tó sábà máa ń jẹ́ ẹ̀kọ́ ìsìn, kò jẹ́ kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan.

Wọ́n ń kọ́ni pé àwọn òkú ṣì wà láàyè. Àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń lo àwọn ìran abàmì, ohùn àjèjì àti àwọn ọ̀nà àyínìke míì láti tan àwọn èèyàn jẹ, kí wọ́n lè gbà gbọ́ pé àwọn alààyè lè bá òkú sọ̀rọ̀. Síbẹ̀, ìtànjẹ yìí ń mú kí àwọn èèyàn gba irọ́ náà gbọ́ pé ẹ̀mí èèyàn ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn tí ẹni náà bá ti kú. Àmọ́, Bíbélì sọ lọ́nà tó ṣe kedere pé: ‘Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.’ (Oníwàásù 9:5, 6) Níwọ̀n bí àwọn òkú ti “sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ìdákẹ́jẹ́ẹ́,” wọn kò lè yin Ọlọ́run.—Sáàmù 115:17. a

Wọ́n gba ìwàkiwà láyè. Ìwé 1 Jòhánù 5:19 sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń lo agbára wọn nípasẹ̀ àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde àti àwọn ọ̀nà míì láti tan èrò burúkú kálẹ̀ pé ó yẹ kéèyàn gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara láyè. (Éfésù 2:1-3) Abájọ nígbà náà tí onírúurú ìwà pálapàla, tó fi mọ́ ìbálòpọ̀ tí wọ́n gbé gbòdì fi wọ́pọ̀ lónìí. Ọ̀pọ̀ tiẹ̀ máa ń wò ó pé kò sí nǹkan tó burú nínú irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀, wọ́n sì rò pé àwọn ìlànà Bíbélì kò bá ìgbà mu mọ́ tàbí pé àwọn ìlànà wọ̀nyẹn kì í jẹ́ kéèyàn lè ṣe tinú ẹni.

Wọ́n ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàdé ìránṣẹ́bìnrin kan tí ó ní “ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́,” tó jẹ́ kó máa “mú èrè púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀ nípa fífi ìsọtẹ́lẹ̀ ṣiṣẹ́ ṣe.” (Ìṣe 16:16) Pọ́ọ̀lù kò fetí sí ohun tí ọmọbìnrin yìí ń sọ torí ó mọ̀ pé àwọn ẹ̀mí èṣù ló fún un lágbára yẹn. Bákan náà, Pọ́ọ̀lù kò fẹ́ mú Ọlọ́run bínú torí ó mọ̀ pé ohun ìríra ni Ọlọ́run ka gbogbo onírúurú ìbẹ́mìílò sí, tó fi mọ́ ìwòràwọ̀ àti títọrọ nǹkan lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òkùnkùn.—Diutarónómì 18:10-12.

Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù

Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí burúkú? Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nígbà tó sọ pé: “Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Jákọ́bù 4:7) Ọ̀nà tá a lè gbà ṣègbọràn sí àṣẹ yìí ni pé ká máa fi àwọn ohun tá à ń kọ́ látinú Bíbélì ṣèwà hù, òun ni Ìwé Mímọ́ kan ṣoṣo tó tú àṣírí Sátánì, àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ àti àwọn ètekéte wọn. (Éfésù 6:11, 2 Kọ́ríńtì 2:11) Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹ̀mí burúkú àti gbogbo àwọn tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, kò ní máa wà lọ títí. (Róòmù 16:20) Òwe 2:21 sọ pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó o bá fẹ́ mọ òtítọ́ nípa ipò tí àwọn òkú wà àti ìrètí àjíǹde tí Bíbélì sọ, jọ̀wọ́ wo orí 6 àti 7 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ṣé Ọlọ́run ló dá àwọn ẹ̀mí èṣù?​—2 Pétérù 2:4.

● Ǹjẹ́ o lè bá òkú sọ̀rọ̀?​—Oníwàásù 9:5, 6.

● Báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù?—Jákọ́bù 4:7.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni àwọn ẹ̀mí èṣù ń gbà darí àwọn èèyàn