Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ó Lè Jẹ́ Orin Ló Máa Ṣèrànwọ́”

“Ó Lè Jẹ́ Orin Ló Máa Ṣèrànwọ́”

“Ó Lè Jẹ́ Orin Ló Máa Ṣèrànwọ́”

Orílẹ̀-èdè Philippines ni Juliana, obìnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ Kristẹni ń gbé. Ó ní àìsàn ọpọlọ tó máa ń mú kí àwọn arúgbó gbàgbé ọ̀pọ̀ nǹkan, ìyẹn àìsàn tí wọ́n ń pè ní Alzheimer. Àìsàn yìí ti wọ̀ ọ́ lára débi pé tó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀, kì í dá wọn mọ̀. Síbẹ̀, kò sígbà tí mo bá wà ládùúgbò yẹn tí mi ò ní dé ọ̀dọ̀ Juliana.

Orí ìdùbúlẹ̀ ni Juliana máa ń wà tọ̀sán-tòru, ńṣe ló kàn máa ń yọjú lójú fèrèsé ṣáá. Kì í rọrùn fún mi rárá nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀, torí kò dá mi mọ̀ mọ́. Ṣe ló máa ń wò mí roro, síbẹ̀ ó máa ń hàn lójú rẹ̀ pé kò dá mi mọ̀. Mo bi í pé, “Ṣé o ṣì máa ń ronú nípa Jèhófà?” Mo wá sọ ìrírí kan fún un, lẹ́yìn náà mo bí i ní àwọn ìbéèrè míì, síbẹ̀, kò jọ pé ó lóye ohun tí mò ń sọ rárá. Ni mo bá torin bẹnu. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà múnú mi dùn gan-an ni!

Juliana bojú wò mí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orin náà pẹ̀lú mi! Kò pẹ́ tí mo fi dákẹ́ torí mi ò mọ gbogbo ọ̀rọ̀ orin náà lórí, ní èdè ìbílẹ̀ Tagalog. Àmọ́ Juliana kò dákẹ́, ṣe ló ń kọrin náà lọ ní tiẹ̀. Ó rántí ìlà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí orin náà ní. Mo yáa ní kí ẹni tá a jọ wà níbẹ̀ bá mi yá ìwé orin lọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń gbé nítòsí. Kíá ló sì lọ gbà á wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ nọ́ńbà orin náà, mo kàn ṣàdédé rí i pé ibẹ̀ gan-an ni mo ṣí. Bó ṣe di pé àwa méjèèjì jọ kọ gbogbo orin náà nìyẹn! Nígbà tí mo bi Juliana bóyá ó rántí àwọn orin míì, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orin àtijọ́ kan, ìyẹn orin ìfẹ́ ní èdè Filipino.

Mo wá sọ fún un pé, “Rárá o, kì í ṣe orin tí wọ́n máa ń kọ lórí rédíò ni mò ń sọ, àmọ́ orin tí wọ́n ń kọ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.” a Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ orín míì látinú ìwé orin wa, òun náà sì bá mi kọ ọ́. Mo rí i pé inú rẹ̀ dùn gan-an ni. Ó rẹ́rìn-ín dénú, kò sì wò mí bí ẹni tí kò mọ̀ mí mọ́.

Àwọn aládùúgbò tó ń gbọ́ orin náà sáré bọ́ síta, wọ́n fẹ́ mọ ibi tí orin náà ti ń wá. Wọ́n dúró sójú fèrèsé, wọ́n ń wò wá, wọ́n sì ń fetí sí orin tí à ń kọ. Ó wú mi lórí gan-an láti rí bí orin náà ṣe wọ Juliana lọ́kàn! Ó ti jẹ́ kó rántí àwọn ọ̀rọ̀ orin náà.

Ìrírí yìí kọ́ mi pé, a kò mọ ohun tó máa ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ní ìṣòro láti lóye nǹkan tàbí tí wọ́n ò tiẹ̀ lè sọ̀rọ̀ rárá. Ó lè jẹ́ orin ló máa ṣèrànwọ́.

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni Juliana kú. Ìgbà tí mò ń gbọ́ àwọn orin amóríyá tuntun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lọ́dún 2009, ni mo rántí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Bó o bá fẹ́ àwọn orin aládùn yìí, o lè bi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ìpàdé.