Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó Ti Yẹ Kí N Kúrò Lọ́dọ̀ Àwọn Òbí Mi?

Ṣé Ó Ti Yẹ Kí N Kúrò Lọ́dọ̀ Àwọn Òbí Mi?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Ṣé Ó Ti Yẹ Kí N Kúrò Lọ́dọ̀ Àwọn Òbí Mi?

“Ó máa ń ṣe mí bíi pé àwọn èèyàn ò ní fojú gidi wò mí torí pé èmi tí mo ti pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], ṣì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí mi. Mi ò rò pé màá dẹni tí ó tójú bọ́ bí mi ò bá kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí mi.” —Katie. a

“Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún [20] ọdún, àmọ́ inú mi kì í dùn bó ṣe jẹ́ pé àwọn òbí mi ló ń darí ìgbésí ayé mi. Ohun tó mú kí n ronú láti máa lọ dá gbé ni pé, mi ò fẹ́ bí àwọn òbí mi kò ṣe jẹ́ kí n máa ṣe ohun tó wù mí, wọ́n máa ń sọ pé àwọn mọ̀ jù mí lọ.”—Fiona.

Ó LÈ ti pẹ́ tó ti ń wù ẹ́ pé kó o máa dá gbé kó tó di pé o dàgbà tó láti ṣe bẹ́ẹ̀. Kò sóhun tó burú nínú ìyẹn. Ó ṣe tán, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn látilẹ̀wá fún àwọn ọ̀dọ́ ni pé kí wọ́n dàgbà, nígbà tó bá sì yá, kí wọ́n kúrò lọ́dọ̀ bàbá àti ìyá wọn láti lọ dá ìdílé tiwọn sílẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:23, 24; Máàkù 10:7, 8) Àmọ́, ṣé bó ṣe ń wù ẹ́ pé kó o wà láyè ara rẹ túmọ̀ sí pé àkókò ti tó fún ẹ nìyẹn láti kó kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ? Ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀. Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá ó ti tó àkókò lóòótọ́ láti lọ máa dá gbé? Wo ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta tó o ní láti wá ìdáhùn sí. Àkọ́kọ́ ni . . .

Kí Nìdí Tí Mo Fi Fẹ́ Lọ Máa Dá Gbé?

Kó bàa lè rọrùn fún ẹ láti mọ ìdí tó o fi fẹ́ lọ máa dá gbé, wo àwọn ohun tá a fẹ́ mẹ́nu bà yìí. Kọ nọ́ńbà sẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn bẹ̀rẹ̀ látorí ìdí tó ṣe pàtàkì jù lọ tó fi ń wù ẹ́ pé kó o kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ.

․․․ Mo fẹ́ sá fún wàhálà tí wọ́n ń fún mi nílé

․․․ Mo fẹ́ lómìnira sí i

․․․ Mo fẹ́ túbọ̀ níyì lójú àwọn ọ̀rẹ́ mi

․․․ Mo fẹ́ lọ máa gbé pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi tó fẹ́ kí ẹnì kan máa bá òun gbé

․․․ Kí n lè yọ̀ǹda ara mi láti lọ ṣiṣẹ́ níbòmíì

․․․ Kí n lè kọ́ bí mo ṣe lè máa dá gbọ́ bùkátà ara mi

․․․ Mo fẹ́ dín ìnáwó àwọn òbí lórí mi kù

․․․ Nǹkan míì ․․․․․

Àwọn ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu bà tán yìí kò burú nínú ara wọn. Àmọ́, ohun tó mú kó o kúrò nílé lè nípa lórí bó o ṣe máa láyọ̀ tó lẹ́yìn tó o bá ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé torí kó o lè sá fún àwọn wàhálà tí ò ń kojú nílé tàbí kó o lè lómìnira púpọ̀ sí i lo ṣe ń fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ, èyí lè yọrí sí ìjákulẹ̀.

Danielle kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ fúngbà díẹ̀ nígbà tó pé ọmọ ogún [20] ọdún, ó kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ látinú ohun tí ojú rẹ̀ rí. Ó sọ pé: “Kò sí béèyàn ṣe lè wà tí kò ní sí nǹkan kan tó máa ká a lọ́wọ́ kò. Tó o bá ti ń dá gbé, àìlówó lọ́wọ́ tàbí iṣẹ́ tó ò ń ṣe kò ní jẹ́ kó o lè ṣe gbogbo ohun tó bá wù ẹ́.” Carmen, tó lọ gbé ilẹ̀ òkèèrè fún oṣù mẹ́fà sọ pé: “Mo gbádùn ibẹ̀ gan-an, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà iṣẹ́ mi kì í jẹ́ kí n ráyè ara mi rárá. Ó di dandan fún mi kí n ṣe àwọn iṣẹ́ ilé, irú bí ìmọ́tótó ilé, títún àwọn ohun tó bà jẹ́ ṣe, ríro oko àyíká ilé, fífọ aṣọ, fífọ ilẹ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”

Òótọ́ ni pé, tó o bá lọ ń dá gbé, ìyẹn lè jẹ́ kó o túbọ̀ lómìnira, ó sì lè jẹ́ kó o túbọ̀ níyì lójú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Àmọ́, ìwọ fúnra rẹ ni wàá máa san owó àwọn nǹkan tó o bá lò, wàá máa dá se oúnjẹ, wàá máa tún ilé ṣe, wàá sì máa dá ara rẹ nínú dùn bí tẹbí-tọ̀rẹ́ kò bá sí nítòsí. Torí náà, má ṣe jẹ́ káwọn ẹlòmíì tì ẹ́ ṣe ìpinnu láìronú jinlẹ̀. (Òwe 29:20) Bó o bá tiẹ̀ nídìí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó o fi fẹ́ kúrò nílé, ohun míì wà tó tún ṣe pàtàkì gan-an. O gbọ́dọ̀ mọ bó o ṣe lè máa bójú tó ara rẹ. Ìyẹn ló máa gbé wa dé orí ìbéèrè kejì . . .

Ṣé Mo Ti Múra Tán?

Tó o bá fẹ́ lọ máa dá gbé, ṣe ló dà bíi pé o fẹ́ rìnrìn àjò lọ sínú aginjù. Ṣé wàá fẹ́ rin irú ìrìn yìí láìmọ bí wọ́n ṣe ń pàgọ́, bí wọ́n ṣe ń dáná, bí wọ́n ṣe ń se oúnjẹ àti bí wọ́n ṣe ń wo àwòrán ilẹ̀? Ó dájú pé o ò ní fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀! Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ń kó kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn láìfi bẹ́ẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe lè bójú tó ilé.

Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sọ pé, “afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Kó o lè mọ̀ bóyá o ti múra tán láti lọ máa dá gbé, ronú lórí àwọn kókó tá a fẹ́ mẹ́nu bà yìí. Fi àmì sí ẹ̀gbẹ́ èyí tó o lè ṣe, kó o sì fi àmì X sí ẹ̀gbẹ́ èyí tí o kò tíì mọ̀ ọ́n ṣe nínú àwọn ohun tá a kọ sísàlẹ̀ yìí.

◯ Ìṣúnná Owó Serena, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé: “Mi ò tíì fi owó ara mi ra ohunkóhun rí. Ẹ̀rù ń bà mí láti lọ máa dá gbé, mi ò sì mọ bí mo ṣe lè ṣètò bí màá ṣe máa náwó.” Báwo lo ṣe lè mọ bí wàá ṣe máa ṣọ́wó ná?

Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i, ẹni òye sì ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá.” (Òwe 1:5) O ò ṣe béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ, iye tó máa ná ẹnì kan lóṣù, láti san owó ilé, láti ra oúnjẹ, láti bójú tó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tàbí láti san owó ọkọ̀? Kó o wá ní káwọn òbí rẹ kọ́ ẹ bó o ṣe lè máa ṣètò owó tó o fẹ́ ná, kó o sì máa san owó àwọn nǹkan tó o bá lò. Kí nìdí tó fi yẹ kó o kọ́ bó o ṣe lè máa ṣètò owó tó o fẹ́ ná? Kevin, ọmọ ogun [20] ọdún sọ pé: “Tó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í dá gbé, àìmọye ìnáwó tó ò rò tẹ́lẹ̀ ló máa yọjú. Tó ò bá sì ṣọ́ra, ṣe ni wàá máa ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó torí àtisan gbèsè.”

Tó o bá ti ń ṣiṣẹ́, tó o sì fẹ́ mọ bọ́rọ̀ ìnáwó ṣe máa rí lẹ́yìn tó o bá kó kúrò nílé, fún ìgbà díẹ̀ o ò ṣe máa fún àwọn òbí rẹ ní àròpọ̀ iye tí wọ́n ń ná lórí rẹ lóṣooṣù fún oúnjẹ, ilé àtàwọn ìnáwó míì. Tí o kò bá lè san owó yìí tàbí tí kò wù ẹ́ láti san án nígbà tó o ṣì ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ, a jẹ́ pé kò tíì tó àkókò fún ẹ láti máa dá gbé nìyẹn.—2 Tẹsalóníkà 3:10, 12.

◯ Àwọn iṣẹ́ ilé Brian tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] sọ pé, ohun tó ń ba òun lẹ́rù jù lọ ni bí òun á ṣe máa fọ àwọn aṣọ òun lẹ́yìn tóun bá kó kúrò nílé. Báwo lo ṣe máa mọ̀ bóyá o ti lè máa bójú tó ara rẹ? Aron, tó jẹ́ ọmọ ogún [20] ọdún dá àbá pé: “Gbìyànjú láti lo odindi ọ̀sẹ̀ kan jálẹ̀ bíi pé o ti ń dá gbé. Fi owó ara rẹ ra oúnjẹ, kó o sì sè é fúnra rẹ. Máa wọ àwọn aṣọ tó o fọ, tó o sì lọ̀ fúnra rẹ. Máa tún ilé ṣe fúnra rẹ. Kó o sì máa sanwó ọkọ̀ ara rẹ lọ sáwọn ibi tó o bá fẹ́ lọ.” Tó o bá tẹ̀ lé àwọn àbá yìí, àǹfààní méjì ló wà ńbẹ̀, (1) wàá lè mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan (2) wàá sì tún mọyì iṣẹ́ táwọn obí rẹ ń ṣe.

◯ Àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì Ṣé ọ̀rọ̀ ìwọ àtàwọn òbí rẹ pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò rẹ wọ̀ dáadáa? Bó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ yín kì í sábà yé ara yín, o lè máa rò pé nǹkan á túbọ̀ rọ̀ ẹ́ lọ́rùn tí ìwọ àti ọ̀rẹ́ rẹ kan bá jọ ń gbé. Ó sì lè rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Àmọ́, kíyè sí ohun tí Eve, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sọ, ó ní: “Ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi méjì kan wọ̀ dáadáa tẹ́lẹ̀, àmọ́ bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í gbé pa pọ̀ báyìí, wọ́n wá rí i pé àjọgbé àwọn kò wọ̀ rárá. Ọ̀kan jẹ́ afínjú, èkejì sì ya ọ̀bùn. Ọ̀kan fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run, nígbà tí èkejì kò fi bẹ́ẹ̀ ka ìjọsìn Ọlọ́run sí. Lọ́rọ̀ kan ṣá, wọ́n wá rí i pé àwọn ò lè jọ gbé!”

Ó wu ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Erin láti fi ilé sílẹ̀, àmọ́ ó sọ pé: “O lè kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ nípa bó o ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì nígbà tó o bá ṣì wà nílé. Wàá kọ́ bó o ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro àti bó o ṣe lè fara mọ́ àwọn nǹkan kan tí o kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí. Mo ti kíyè sí pé àwọn tó máa ń kúrò nílé nítorí awuyewuye tó ń wáyé láàárín àwọn àtàwọn òbí wọn kì í mọ bí wọ́n ṣe lè yanjú àìgbọ́ra-ẹni-yé, ńṣe ni wọ́n máa ń sá fún un.”

◯ Àwọn nǹkan tẹ̀mí tó yẹ kó o máa ṣe Ìdí táwọn ọ̀dọ́ kan fi ń lọ dá gbé ni pé, wọ́n fẹ́ sá fún àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìjọsìn táwọn òbí wọn ń ṣe. Ohun tó wà lọ́kàn àwọn míì ni pé àwọn á máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn á sì máa jọ́sìn Ọlọ́run nígbà tí àwọn bá fi ilé sílẹ̀, àmọ́ díẹ̀díẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í hu ìwàkiwà. Kí lo lè ṣe tí ‘ọkọ̀ ìgbàgbọ́ rẹ kò fi ní rì’?—1 Tímótì 1:19.

Má kàn máa tẹ̀ lé ohun táwọn òbí rẹ gbà gbọ́ láìronú jinlẹ̀. Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ohun tá a gbà gbọ́ dá wa lójú. (Róòmù 12:1, 2) Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ẹ lọ́wọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run, ṣètò bí wàá ṣe máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, kó o sì máa tẹ̀ lé ètò tó o bá ṣe. O ò ṣe kọ ètò tó o ṣe nípa àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn sórí kàlẹ́ńdà, kó o sì gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé e fún oṣù kan láìjẹ́ pé àwọn òbí rẹ ń rán ẹ létí?

Ìbéèrè kan tó kù tó yẹ kó o bi ara rẹ ni pé . . .

Ibo Ni Mò Ń Lọ?

Ìdí tí àwọn ọ̀dọ́ kan fi fẹ́ máa lọ dá gbé ni pé, wọ́n fẹ́ sá fún ìṣòro tàbí pé wọn ò fẹ́ káwọn òbí máa darí àwọn. Ohun tí wọ́n ń fẹ́ sá fún nìkan ni wọ́n ń rò, wọn ò ronú nípa ibi tí wọ́n ń lọ. Ńṣe lọ̀rọ̀ yìí dà bíi ti ẹni tó ń wa mọ́tò, àmọ́ tó jẹ́ pé dígí tí awakọ̀ fi ń wo ẹ̀yìn ló tẹjú mọ́. Tó bá jẹ́ pé ohun tí awakọ̀ ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn ló ń wò, kò ní lè rí ohun tó wà ní iwájú rẹ̀. Ẹ̀kọ́ wo ni èyí kọ́ wa? Tó o bá fẹ́ ṣàṣeyọrí, má kàn máa ronú nípa bó o ṣe fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ, ṣe ni kó o fi nǹkan kan ṣe àfojúsùn rẹ.

Àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn kí wọ́n lè lọ wàásù ní àwọn àdádó kan lórílẹ̀-èdè wọn tàbí lórílẹ̀-èdè míì. Àwọn míì ti lọ ṣèrànwọ́ láti kọ́ àwọn ibi ìjọsìn tàbí kí wọ́n lọ ṣiṣẹ́ ní ọ̀kan lára ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn míì ronú pé ó máa dáa káwọn dá gbé fúngbà díẹ̀ káwọn tó ṣègbéyàwó. b

Kọ àfojúsùn tó o fẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ tó o bá kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ sórí ìlà yìí. ․․․․․

Ó ṣeé ṣe kó o ti pẹ́ gan-an lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ, síbẹ̀ kó o máà ní ìwà àgbà, kó o má sì mọ bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn nǹkan kan tó máa jẹ́ kó o lè dá dúró láyè ara rẹ. Bọ́rọ̀ bá tiẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, má fi ìkánjú pinnu. Rò ó dáadáa. Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Fetí sí ìmọ̀ràn àwọn òbí rẹ. (Òwe 23:22) Gbàdúrà lórí ọ̀rọ̀ náà. Bó o bá ti fẹ́ pinnu ohun tó o máa ṣe, kó o fi àwọn ìlànà Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò tán yìí sọ́kàn.

Kì í ṣe ìbéèrè tó yẹ kó o béèrè ni pé, Ṣé ó ti yẹ kí n kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí mi? Àmọ́, ńṣe ló yẹ kó o bi ara rẹ pé, Ǹjẹ́ mo ti ṣe tán láti máa dá gbọ́ bùkátà ara mi? Tó bá jẹ́ pé o ti lè dá gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, èyí jẹ́ àmì pé o lè kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

b Ní àwọn ìlú kan, àṣà wọn ni pé kí ọmọ wọn, pàápàá jù lọ ọmọbìnrin, máa gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí títí dìgbà tó máa ṣègbéyàwó. Bíbélì kò fún wa ní ìtọ́ni pàtó lórí ọ̀rọ̀ yìí.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

● Bí nǹkan kò bá tiẹ̀ fara rọ nínú ìdílé yín, àǹfààní wo ló wà nínú kó o ṣì máa bá àwọn òbí rẹ gbé fún ìgbà díẹ̀?

● Nígbà tó o bá ṣì wà nílé, kí lo lè máa ṣe tó máa ṣe ìdílé yín láǹfààní tó sì máa jẹ́ kó o lè gbọ́ bùkátà ara rẹ lọ́jọ́ iwájú?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Táwọn òbí ẹ bá yan àwọn iṣẹ́ tí wàá máa ṣe nílé fún ẹ, ìyẹn iṣẹ́ tó di dandan kó o máa ṣe nígbà tó o bá ti ń dá gbé, á jẹ́ pé wọ́n ti ń kọ́ ẹ bó o ṣe lè máa bójú tó ara rẹ nígbà tó o bá kúrò lọ́dọ̀ wọn nìyẹn.”

“Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé torí kó o lè sá fún àwọn òfin táwọn òbí ẹ ń fún ẹ lo ṣe fẹ́ kúrò nílé, a jẹ́ pé kò tíì yẹ kó o kúrò nílé nìyẹn.”

[Àwọn àwòrán]

Sarah

Aron

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]

Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O Ẹ̀YIN ÒBÍ

Ẹ̀rù ń ba Serena, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, láti kó kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Kí ló ń bà á lẹ́rù? Ó sọ pé: “Bí mo bá tiẹ̀ fẹ́ ra nǹkan, Dádì mi ò ní jẹ́ kí n fi owó ara mi rà á. Wọ́n máa ń sọ pé, ojúṣe àwọn ni láti ra àwọn ohun tí mo bá nílò. Ìdí nìyẹn tí ẹ̀rù fi máa ń bà mí pé tí mo bá kúrò nílé pẹ́nrẹ́n, èmi ni màá máa san owó àwọn nǹkan tí mo bá lò.” Òótọ́ ni pé, ohun tó dáa ni bàbá Serena ní lọ́kàn, àmọ́ ṣé o rò pé ó ń kọ́ ọmọ rẹ̀ bó ṣe máa lè gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ nígbà tó bá kúrò nílé?—Òwe 31:10, 18, 27.

Ṣé kì í ṣe pé ìwọ náà ń kẹ́ àwọn ọmọ rẹ ní àkẹ́jù débi pé wọn ò mọ bí wọ́n ṣe lè gbọ́ bùkátà ara wọn nígbà tí wọ́n bá lọ ń dá gbé? Báwo lo ṣe lè mọ̀? Jẹ́ ká tún gbé àwọn kókó mẹ́rin tá a ti jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí yẹ̀ wò lọ́nà tí ìwọ òbí máa fi mọ ojúṣe rẹ.

Ìṣúnná owó. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ tó ti tójú bọ́ mọ bí wọ́n ṣe lè kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù owó orí tàbí bí wọ́n ṣe lè tẹ̀ lé òfin ìjọba nípa sísan owó orí? (Róòmù 13:7) Ṣé wọ́n mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná? (Òwe 22:7) Ṣé wọ́n lè ṣètò bí wọ́n ṣe lè máa ná owó tó ń wọlé fún wọn, kí wọ́n má sì ná ju iye tí wọ́n ní lọ? (Lúùkù 14:28-30) Ṣé ẹ ti jẹ́ kí wọ́n ní irú ayọ̀ téèyàn máa ń ní tó bá fowó tó ṣiṣẹ́ fún ra nǹkan? Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ ti ní ìdùnnú tó tún ju ìyẹn lọ, èyí téèyàn máa ń ní tó bá ń lo àkókò àtàwọn ohun tó ní láti fi ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?—Ìṣe 20:35.

Iṣẹ́ ilé. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ, lọ́kùnrin àti lóbìnrin mọ oúnjẹ sè? Ṣé o ti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń fọ aṣọ àti bí wọ́n ṣe ń lọ̀ ọ́? Bí wọ́n bá ti ń wa mọ́tò, ṣé wọ́n lè ṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lára mọ́tò náà, irú bíi pípààrọ̀ fíùsì, ọ́ìlì tàbí táyà tó bá jò?

Àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Bí àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n ti tójú bọ́ bá bára wọn jà, ṣé ìwọ lo máa ń bá wọn parí ìjà? Àbí o ti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè máa fi sùúrù yanjú àwọn ọ̀ràn, kí wọ́n sì wá sọ bí wọ́n ṣe yanjú rẹ̀ fún ọ?—Mátíù 5:23-25.

Àwọn nǹkan tẹ̀mí téèyàn máa ń dá ṣe. Ṣé o kàn máa ń sọ ohun tó yẹ káwọn ọmọ rẹ gbà gbọ́ fún wọn ni, àbí o máa ń sọ ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gba irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọ́ fún wọn? (2 Tímótì 3:14, 15) Dípò kó o kàn máa dáhùn àwọn ìbéèrè tí àwọn ọmọ rẹ bá ń bi ẹ́ nípa ẹ̀sìn àti nípa ìwà híhù, ṣé ò ń kọ́ wọn lọ́nà tí wọ́n á fi ní “agbára láti ronú,” tí wọ́n á sì lè “kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Òwe 1:4; Hébérù 5:14) Ṣó o fẹ́ kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àbí o fẹ́ kí wọ́n túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó sàn ju tìẹ lọ?

Kò sí àní-àní pé tó o bá fẹ́ tọ́ àwọn ọmọ rẹ láwọn ọ̀nà tá a mẹ́nu bà yìí, o gbọ́dọ̀ lo àkókò tó pọ̀, kó o sì sapá gidigidi. Àmọ́, àǹfààní tó o máa rí tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tí ọjọ́ náà bá pé, tí wọ́n máa ní láti dágbére fún ẹ pé àwọn fẹ́ lọ máa dá gbé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Tó o bá fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ, ṣe ló dà bí ìgbà tó o fẹ́ rìnrìn àjò lọ sínú aginjù, o gbọ́dọ̀ mọ bó o ṣe máa bójú tó ara rẹ lọ́hùn-ún kó tó di pé o kúrò nílé