Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Yẹ Kí Àwọn Obìnrin Jẹ́ Òjíṣẹ́?

Ṣó Yẹ Kí Àwọn Obìnrin Jẹ́ Òjíṣẹ́?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ṣó Yẹ Kí Àwọn Obìnrin Jẹ́ Òjíṣẹ́?

OBÌNRIN kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì sọ nínu ìwé ìròyìn USA Today, pé: “Ó máa ń yà mí lẹ́nu gan-an, ó sì máa ń bí mi nínú, bí mo ṣe ń rí i pé títí di báyìí wọn ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn obìnrin joyè ẹ̀sìn.” Ọ̀pọ̀ ló ní irú èrò tí obìnrin yìí ní. Ó ṣe tán, nínú àwọn ẹ̀sìn míì, àwọn obìnrin máa ń joyè òjíṣẹ́, àlùfáà, bíṣọ́ọ̀bù àti rábì.

Àwọn ẹ̀sìn tó sọ pé àwọn obìnrin kò lè jẹ́ òjíṣẹ́ àti àwọn tó ń fàyè gba àwọn obìnrin láti máa wàásù láti orí pèpéle gbà pé Ìwé Mímọ́ ni àwọn ń tẹ̀ lé. Àmọ́, èrò méjèèjì yìí kò bá ohun tí Bíbélì sọ mu. Báwo ló ṣe lè jẹ́ bẹ́ẹ̀? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà “òjíṣẹ́.”

Àwọn Òjíṣẹ́ ní Ọ̀rúndún Kìíní

Kí lo rò pé ọ̀rọ̀ náà “òjíṣẹ́” túmọ̀ sí? Ohun tí ọ̀rọ̀ yìí máa ń gbé wá sí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn ní gbàrà tí wọ́n bá gbọ́ ọ ni, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin tí wọ́n máa ń darí ìsìn. Àmọ́ ọ̀nà tí Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ yìí gbòòrò ju èyí lọ. Gbé àpẹẹrẹ Fébè yẹ̀ wò, ìyẹn obìnrin Kristẹni kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ó jẹ́ ‘arábìnrin wa, ẹni tí ó jẹ́ òjíṣẹ́ ìjọ tí ó wà ní Kẹnkíríà.’—Róòmù 16:1.

Ṣé o rò pé Fébè máa ń dúró síwájú ìjọ tó wà ní Kẹnkíríà, tó sì máa ń darí ẹ̀sìn? Kí ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Fébè ṣe gan-an? Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Fílípì, Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn obìnrin kan pé, wọ́n “bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ninu iṣẹ́ ìtànkalẹ̀ ìhìn rere.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa; Fílípì 4:2, 3, Ìròyìn Ayọ̀.

Ọ̀nà pàtàkì táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbà tan ìhìn rere kálẹ̀ jẹ́ “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 20:20) Òjíṣẹ́ ni gbogbo àwọn tó kópa nínú iṣẹ́ yẹn. Àwọn obìnrin sì wà lára wọn, irú bíi Pírísílà. Òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, “làdí ọ̀nà Ọlọ́run . . . lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí” fún ọkùnrin kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì tíì ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. (Ìṣe 18:25, 26) Bíi ti Fébè, ẹ̀rí fi hàn pé Pírísílà jẹ́ òjíṣẹ́ tó ṣiṣẹ́ rẹ̀ dójú àmì bí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin míì ti ṣe.

Wọ́n Ń Kópa Tó Buyì Kúnni

Ṣé a lè ka iṣẹ́ ìwàásù sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ yẹpẹrẹ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tí a kàn lè fi sílẹ̀ fún àwọn obìnrin, kí àwọn ọkùnrin lè máa ṣiṣẹ́ tó ṣe pàtàkì, ìyẹn bíbójú tó ìjọ? Ìdí méjì tó tẹ̀ lé e yìí fi hàn pé kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀ rárá. Àkọ́kọ́ ni pé, Bíbélì mú un ṣe kedere pé gbogbo Kristẹni ló gbọ́dọ̀ máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, èyí sì kan àwọn ọkùnrin tí wọ́n ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó rinlẹ̀ nínú ìjọ. (Lúùkù 9:1, 2) Ìdí kejì ni pé, láti ìgbà yẹn títí di òní olónìí, iṣẹ́ ìwàásù ni ọ̀nà pàtàkì tí àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin gbà ń ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé: ‘Ẹ máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa kọ́ wọn.’—Mátíù 28:19, 20.

Ojúṣe pàtàkì kan tún wà táwọn obìnrin kan ní nínú ìjọ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí àwọn àgbàlagbà obìnrin jẹ́ . . . olùkọ́ni ní ohun rere; kí wọ́n lè pe orí àwọn ọ̀dọ́bìnrin wálé láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn, láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn.” (Títù 2:3, 4) Èyí fi hàn pé, àwọn obìnrin tó ti dàgbà, tí wọ́n sì mọ irú ìgbé ayé tó yẹ kí Kristẹni máa gbé, ní àǹfààní láti ṣèrànwọ́ fún àwọn obìnrin tó kéré lọ́jọ́ orí, tí wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí, kí òótọ́ bàa lè jinlẹ̀ nínú àwọn náà. Ó dájú pé ojúṣe tó ń buyì kúnni, tó sì ṣe pàtàkì lèyí jẹ́ pẹ̀lú.

Kíkọ́ni Nínú Ìjọ

Àmọ́ ṣá o, kò síbi tí Bíbélì ti sọ pé káwọn obìnrin dúró níwájú ìjọ láti kọ́ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wọn ní ìtọ́ni láti “dákẹ́ nínú àwọn ìjọ.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Òun fúnra rẹ̀ sọ ohun kan tó mú kó sọ bẹ́ẹ̀, ó ní kí nǹkan lè máa ṣẹlẹ̀ “lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́ríńtì 14:34, 40) Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa nínú ìjọ, Ọlọ́run ti gbé ojúṣe kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lé àwọn kan lọ́wọ́. Àmọ́ kíyè sí pé, kì í kàn ṣe torí pé ẹnì kan jẹ́ ọkùnrin ni Ọlọ́run fi ń yàn án sípò àbójútó nínú ìjọ; àwọn ọkùnrin tí wọ́n kúnjú ìwọ̀n dáadáa ló máa ń yàn sípò. a1 Tímótì 3:1-7; Títù 1:5-9.

Ṣé ipò tó ń tàbùkù ẹni ni Ọlọ́run yan àwọn obìnrin sí ni? Rárá o. Rántí pé iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì gan-an ni Ọlọ́run yàn fún wọn, ìyẹn láti máa jẹ́rìí nípa òun níbi gbogbo. (Sáàmù 68:11) Láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí, gbogbo ọkùnrin àti obìnrin wọn ló ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, wọ́n sì ti ran ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn lọ́wọ́ láti ronú pìwà dà kí wọ́n lè ní ìgbàlà. (Ìṣe 2:21; 2 Pétérù 3:9) Àṣeyọrí ńlá mà lèyí o!

Bí Ọlọ́run ṣe ṣètò ipa tí ọkùnrin àti obìnrin ń kó nínú ìjọ ń mú kí àlááfíà wà, èyí sì fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn méjèèjì. Láti ṣàkàwé: Ojú àti etí ló máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ bí ẹnì kan bá fẹ́ sọdá òpópónà tí ọkọ̀ ń gbà lọ gbà bọ̀. Lọ́nà kan náà, bí ọkùnrin àti obìnrin bá ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́, Ọlọ́run máa ń bù kún ìjọ nípa jíjẹ́ kó wà lálàáfíà.—1 Kọ́ríńtì 14:33; Fílípì 4:9. b

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tún kíyè sí pé, ó níbi tí àṣẹ ọkùnrin mọ nínú ìjọ. Ó wà lábẹ́ àṣẹ Kristi, ó sì gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Ó tún ṣe pàtàkì pé kí àwọn tó wà nípò àbójútó nínú ìjọ “wà ní ìtẹríba fún ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì nínú ìbẹ̀rù Kristi,” kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, kí wọ́n sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀.—Éfésù 5:21.

b Bí àwọn obìnrin bá ń bọ̀wọ̀ fún ojúṣe tí Ọlọ́run fún àwọn ọkùnrin nínú ìjọ, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún àwọn áńgẹ́lì.—1 Kọ́ríńtì 11:10.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ọ̀nà wo ni àwọn obìnrin gbà ń kọ́ni nígbà tí ìjọ Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀?—Ìṣe 18:26.

● Àwọn wo ni Ọlọ́run yàn láti jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ?—1 Tímótì 3:1, 2.

● Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwọn obìnrin Kristẹni lóde òní?—Sáàmù 68:11.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]

“Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó sọ àsọjáde náà; àwọn obìnrin tí ń sọ ìhìn rere jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá.”—SÁÀMÙ 68:11