Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Báwo Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Báwo Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ni nípa ṣíṣàlàyé kókó kan tẹ̀ lé òmíràn. Lọ́pọ̀ ìgbà ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ni wọ́n máa ń lò. Orí mọ́kàndínlógún [19] ni ìwé yìí ní, lára wọn sì ni:

“Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́?”

“Ta Ni Jésù Kristi?”

“Ibo Làwọn Òkú Wà?”

“Ṣé ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn’ La Wà Yìí?”

“Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?”

“Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀”

Wọ́n máa ń sọ pé kí àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bi wọ́n ní ìbéèrè, kí wọ́n sì fojú ara wọn rí bí Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè wọn. Bí wọ́n ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ, ohun tí wọ́n ti kọ́ látinú Bíbélì ló máa mú kí wọ́n pinnu ẹ̀sìn tí wọ́n máa yàn.

Bó o bá fẹ́ kí ẹnì kan máa wá kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó o sì fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé náà, jọ̀wọ́ kọ̀wé sínú fọ́ọ̀mù tó wà lójú ewé yìí, kó o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tá a kọ síbẹ̀ tàbí sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tá a tò sójú ewé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Mo fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.