Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ìbànújẹ́ Kúrò Lọ́kàn Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ìbànújẹ́ Kúrò Lọ́kàn Mi?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ìbànújẹ́ Kúrò Lọ́kàn Mi?

“Tí àwọn ọ̀rẹ́ mi bá ní ìṣòro tó le gan-an, mo máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́, mo sì máa ń jẹ́ kí ara wọn yá gágá. Àmọ́, ohun tí ọ̀pọ̀ ò mọ̀ ni pé, tí n bá pa dà sínú yàrá mi, ńṣe ni màá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.”—Kellie. a

“Tí inú mi kò bá dùn, ṣe ni mo máa ń fẹ́ dá wà. Bí wọ́n bá pè mí pé kí n wá síbì kan, mi kì í fẹ́ lọ. Mi kì í sì í jẹ́ káwọn ará ilé mi mọ̀ pé inú mi kò dùn. Ṣe ni wọ́n máa ń rò pé mi ò ní ìṣòro kankan.”—Rick.

ṢÉ ÌWỌ náà ti ronú bíi tàwọn ọ̀dọ́ tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe yára rò pé nǹkan kan ń ṣe ẹ́. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, gbogbo èèyàn ni ìbànújẹ́ máa ń sorí wọn kodò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kódà, ìgbà míì wà tí ìbànújẹ́ bá àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn.

Láwọn ìgbà míì, o lè mọ ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹ, ìgbà míì sì rèé, o lè má mọ̀ ọ́n. Anna, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé, “Ìgbàkigbà ni ìbànújẹ́ lè dé, kódà ìbànújẹ́ kàn lè ṣàdédé bá èèyàn láìjẹ́ pé onítọ̀hún ní ìṣòrò pàtó kan. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún gan-an ò tiẹ̀ yé èèyàn, àmọ́ ó máa ń ṣẹlẹ̀!”

Ohun yòówù kó fa ìbànújẹ́, tó bá sì jẹ́ pé o kò mọ ohun tó fà á, kí lo lè ṣe bí ìbànújẹ́ bá fẹ́ sorí rẹ kodò?

Ìmọ̀ràn Kìíní: Sọ̀rọ̀ náà fún ẹnì kan. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.

Kellie: “Lẹ́yìn tí mo bá sọ ohun tó ń ṣe mí fún ẹnì kan, ìtura ńlá ló máa ń jẹ́ fún mi pé ẹnì kan mọ ohun tó ń bá mi fínra. Wọ́n á sì lè ràn mí lọ́wọ́ kí n lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀dùn ọkàn. Ńṣe ló máa dà bíi pé wọ́n yọ mí nínú kòtò tí mo há ara mi mọ́!”

Àbá: Kọ orúkọ ‘ọ̀rẹ́ tòótọ́’ kan tó o lè sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún nígbà tí inú rẹ kò bá dùn. Kọ ọ́ sórí ìlà yìí.

․․․․․

Ìmọ̀ràn Kejì: Ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀. Bí ìbànújẹ́ kò bá jẹ́ kó o lè ṣe ìpinnu tó tọ́, o lè gbìyànjú láti kọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ sínú ìwé kan. Nínú àwọn sáàmù tí Ọlọ́run mí sí, ìgbà míì wà tí Dáfídì ṣàkọsílẹ̀ bí inú rẹ̀ ṣe bà jẹ́ tó. (Sáàmù 6:6) Tó o bá ń kọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ sílẹ̀, wàá lè “fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú.”—Òwe 3:21.

Heather: “Bí mo bá ṣàkọsílẹ̀ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára mi nígbà tí inú mi bá bà jẹ́, èyí máa ń jẹ́ kí n lè fòye mọ oríṣiríṣi èrò tó ń wá sí mi lọ́kàn. Tó o bá ti lè kọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ sílẹ̀, tó o sì ti lóye ohun tó fà á, ìbànújẹ́ náà á dín kù.”

Àbá: Àwọn ẹlòmíì máa ń ní ìwé tí wọ́n máa ń ṣàkọsílẹ̀ ohun tó bá ń ṣe wọ́n sí. Tí ìwọ náà bá ní irú ìwé bẹ́ẹ̀, kí lo lè kọ síbẹ̀? Tí inú rẹ kò bá dùn, ṣàpèjúwe bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ àti ohun tó o rò pé ó fa ìbànújẹ́ náà. Lẹ́yìn oṣù kan, ka ohun tó o bá kọ. Ṣé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ ti yí pa dà? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kọ ohun tó ràn ẹ́ lọ́wọ́ sílẹ̀.

Ìmọ̀ràn Kẹta: Gbàdúrà nípa rẹ̀. Bíbélì sọ pé, tó o bá sọ ohun tó ń dùn ẹ́ lọ́kàn fún Ọlọ́run nínú àdúrà, ‘àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò máa ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ àti agbára èrò orí rẹ.’—Fílípì 4:7.

Esther: “Mo gbìyànjú láti mọ ohun tó ń bà mí nínú jẹ́, àmọ́ kò yé mi. Mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́ kí n lè láyọ̀. Nǹkan tojú sú mi torí mi ò mọ ìdí tí ìbànújẹ́ fi ń bá mi. Àmọ́, mo bọ́ lọ́wọ́ ìbànújẹ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Má ṣe fojú kéré agbára tí àdúrà ní!”

Àbá: Bó o bá fẹ́ gbàdúrà sí Jèhófà, o lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó wà nínú Sáàmù 139:23, 24. Sọ gbogbo ohun tó bá wà lọ́kàn rẹ fún Ọlọ́run, kó o sì ní kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o lè mọ ohun tó ń bà ẹ́ nínú jẹ́.

Láfikún sí àwọn àbá tá a dá lókè yìí, àwọn ìmọ̀ràn tó ṣeyebíye wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 119:105) Tó o bá ń fi àwọn èrò rere tó wà nínú Bíbélì kún inú ọkàn rẹ, ìyẹn á nípa rere lórí bó o ṣe ń ronú, bọ́rọ̀ ṣe ń rí lára rẹ àti bó o ṣe ń hùwà. (Sáàmù 1:1-3) Àwọn ìtàn amóríyá, tó sì ń gbéni ró wà nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì nínú Bíbélì. Wàá rí àwọn àbá síwájú sí i tó máa jẹ́ kó o gbádùn Bíbélì kíkà nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ojú ìwé mẹ́sàn-án tá a ti jíròrò àwọn “Àwòkọ́ṣe” nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé náà. Lára àwọn ìtàn Bíbélì tá a jíròrò nínú ìwé náà ni ìtàn Jósẹ́fù, Hesekáyà, Lìdíà àti Dáfídì. Tó o bá wo ojú ìwé 227 nínú ìwé náà, wàá rí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe kó lè bọ́ lọ́wọ́ èrò tí kò tọ́ tó ń wá sí i lọ́kàn nítorí pé ó jẹ́ aláìpé.

Àmọ́ tí ìbànújẹ́ yìí bá kọ̀ tí kò lọ, lẹ́yìn tó o ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe sí i ńkọ́?

Bí Ìbànújẹ́ Bá Kọ̀ Tí Kò Lọ

Ryan sọ pé, “Nígbà míì, mi kì í fẹ́ dìde lórí bẹ́ẹ̀dì tí mo bá jí láàárọ̀, torí pé mi ò tún fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tí kò nítumọ̀.” Àárẹ̀ ọkàn ló ń da Ryan láàmú, kì í sì í ṣe òun nìkan ló níṣòro yìí. Ìwádìí fi hàn pé tá a bá kó ọ̀dọ́ mẹ́rin jọ, ó ṣeé ṣe kí ọ̀kan nínú wọn ní oríṣi àwọn àárẹ̀ ọkàn kan kí wọ́n tó dàgbà.

Báwo lo ṣe máa mọ̀ pé àárẹ̀ ọkàn ló ń dà ẹ́ láàmú? Lára àwọn àmì tó o máa rí ni pé ìṣesí àti ìwà rẹ kàn máa ṣàdédé yí pa dà lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, á máa wù ẹ́ pé kó o máa dá wà, ọ̀pọ̀ nǹkan kò ní máa wù ẹ́ ṣe, bó o ṣe ń jẹun àti bó o ṣe ń sùn máa yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀, wàá sì tún máa fi ojú ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan wo ara rẹ tàbí kó o kàn máa dá ara rẹ lẹ́bi ṣáá.

Ká sòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ni ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ohun tá a mẹ́nu bà yìí máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, bí àwọn àmì yìí bá kọ̀ tí wọn kò lọ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, o lè sọ fáwọn òbí rẹ pé kí wọ́n jẹ́ kó o lọ rí dókítà. Ó ṣeé ṣe kí Dókítà lè pinnu bóyá àìsàn kan ló ń fa ìbànújẹ́ náà. b

Tó bá jẹ́ pé àárẹ̀ ọkàn ló ń yọ ẹ́ lẹ́nu, kò sí ìtìjú ńbẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní irú àìsàn yìí ni ara wọn ti bẹ̀rẹ̀ sí í yá gágá báyìí, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ó ti pẹ́ tí ara wọn ti yá gágá bẹ́ẹ̀ gbẹ̀yìn! Nítorí náà, tó bá jẹ́ pé àárẹ̀ ọkàn tàbí nǹkan míì ló ń fa ìbànújẹ́ fún ẹ, máa rántí àwọn ọ̀rọ̀ tó tuni nínú tó wà nínú Sáàmù 34:18 pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

b Bí ìbànújẹ́ bá kọ̀ tí kò lọ kúrò lọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ kan, wọ́n máa ń fẹ́ pa ara wọn. Bí irú èrò yìí bá ti wá sí ẹ lọ́kàn, tètè fọ̀rọ̀ náà lọ àgbàlagbà kan tó o fọkàn tán.—Wo Jí! July–September 2008, ojú ìwé 16 sí 18.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

Àǹfààní wo ló wà nínú ẹkún sísun?

“Mi ò kì í tètè sunkún, àmọ́ ó di dandan pé kí n sunkún nígbà tí ìbànújẹ́ bá sorí mi kodò. Ẹkún sísun máa ń mú ìtura wá, ó sì máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ fúyẹ́ lọ́kàn. Ó máa ń jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, màá sì wá rí i kedere pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.”—Leanne.

Báwo làwọn ẹlòmíì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìbànújẹ́ bá sorí rẹ kodò?

“Bí inú mi kò bá dùn, kò yẹ ki n máa dá wà. Òótọ́ ni pé mo ní láti dá wà nígbà míì ki n lè ronú jinlẹ̀ lórí bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi, kí n sì lè ráyè sunkún dáadáa. Àmọ́ lẹ́yìn ìyẹn, àfi ki n wà láàárín àwọn èèyàn kí n má bàa máa ronú nípa ohun tó ń bà mí nínú jẹ́.”—Christine.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

“Inú mi kì í sábà dùn tí mo bá ń ronú nípa ara mi ṣáá. Àmọ́, nígbàkigbà tí n bá ti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, mi kì í fi bẹ́ẹ̀ ronú nípa ara mi mọ́, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí n láyọ̀.”

“Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe eré ìmárale déédéé, inú mi kì í fi bẹ́ẹ̀ bà jẹ́ mọ́ torí pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò tó dáa nípa ara mi. Eré ìmárale máa ń tán mi lókun débi pe, nígbà tí n bá fi máa ṣe é tán, ṣe ni ìbànújẹ́ máa ń fò lọ kúrò lọ́kàn mi.”

[Àwọn àwòrán]

Drenelle

Rebekah

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Tó o bá sapá, táwọn ẹlòmíì sì ràn ẹ́ lọ́wọ́, o lè bọ́ lọ́wọ́ ìbànújẹ́ bí ìgbà tí ẹnì kan fà ẹ́ jáde kúrò nínú kòtò