Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Lo Mọ̀ Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Kí Lo Mọ̀ Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Kí Lo Mọ̀ Nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Obìnrin kan tó ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ akọ̀ròyìn lórílẹ̀-èdè Denmark sọ pé: “Mo ti ka ọ̀pọ̀ nǹkan nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, mo gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àhesọ kan, mo sì ti gbọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fi ẹ̀tanú hàn. Nítorí èyí, ojú tí kò dáa ni mo fi ń wo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

NÍGBÀ tó yá, obìnrin yìí fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Ó sọ pé: “Ní gbàrà tí mo wọ ilé wọn, ńṣe ni èrò tí mo ní nípa wọn yí pa dà! Bóyá àwọn èèyàn ò mọ̀ wọ́n dáadáa tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni gbogbo wa kàn ń sọ ohun tí ojú wa kò tó. Èmi náà mọ̀ pé mo jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí. Mo wá rí i pé èrò tí mo ní nípa wọn kò tọ̀nà.”—Ìròyìn látọwọ́ Cecilie Feyling fún ìwé ìròyìn Jydske Vestkysten.

Nígbà tí olùdarí àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ta ṣéènì ní ilẹ̀ Yúróòpù dòwò pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó rí i pé wọ́n máa ń ṣòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́. Èyí mú kó fẹ́ láti gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà síṣẹ́.

Òótọ́ ni pé, iṣẹ́ ìwàásù la fi ń dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ jù lọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń rí i pé àwọn kan ò fẹ́ kí wọ́n bá àwọn jíròrò Bíbélì, nígbà tó jẹ́ pé àwọn míì nífẹ̀ẹ́ sí ìjíròrò Bíbélì. Kódà, ó ju mílíọ̀nù méje àwọn èèyàn lọ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, ṣàṣà sì ni orílẹ̀-èdè tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò sí. Àwọn kan lára àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà sì ti dẹni tó ń kọ́ àwọn mìíràn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àjọ National Council of Churches sọ pé lára àwọn ẹ̀sìn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí iye wọn pọ̀ jù lọ, mẹ́rin péré ni iye wọn ń pọ̀ sí i. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì wà lára àwọn ẹ̀sìn mẹ́rin yìí.

Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Báwo ni wọ́n ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ǹjẹ́ wọ́n máa ń retí pé káwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ká tiẹ̀ sọ pé kò wù ẹ́ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ ìdáhùn tó jẹ́ òótọ́ sí àwọn ìbéèrè yìí. Torí náà, má ṣe fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ àhesọ táwọn ẹlẹ́tanú ń sọ, ńṣe ni kó o wádìí kó o lè mọ òtítọ́. Òwe 14:15 sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”

Àdúrà wa ni pé kí ìwé ìròyìn Jí! yìí ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Kódà, ti pé ò ń ka ìwé ìròyìn yìí fi hàn pé o ní ọkàn tó dáa. Ohun kan tó o tún lè ṣe nìyí: Bó o ṣe ń ka àpilẹ̀kọ mẹ́rin tó tẹ̀ lé èyí àtàwọn àpótí tó wà níbẹ̀, gbé Bíbélì rẹ, kó o sì máa ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà. a Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí fi hàn pé o jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti pé o ní “ọkàn-rere” gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ.—Ìṣe 17:11.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí o kò bá ní Bíbélì, o lè gba ọ̀kan lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó o bá sì mọ bí wọ́n ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè ka Bíbélì lórí ìkànnì wa ní oríṣiríṣi èdè, ìyẹn, www.watchtower.org. (Ní báyìí, kò tíì sí Bíbélì èdè Yorùbá níbẹ̀). Bákan náà, àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà lórí Ìkànnì wa, ní èdè tó lé ní irinwó dín ogún [380].