Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?

Kí Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?

Kí Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́?

Ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ àṣírí, torí pé èèyàn lè rí àwọn ìwé wọn ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Díẹ̀ lára àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ rèé.

1. Bíbélì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Jason BeDuhn, tó jẹ́ igbá kejì ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn sọ pé: “[Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé] ìgbàgbọ́ àti ìṣe wọn ka orí ohun tí Bíbélì sọ láì bomi là á, wọ́n sì fara mọ́ ohun yòówù kí wọ́n bá níbẹ̀.” Ohun tí wọ́n gbà gbọ́ bá Bíbélì mu, wọn kì í sì í yí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ po láti ti èrò wọn lẹ́yìn. Bákan náà, wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ohun tó wà nínú Bíbélì ni èèyàn lè túmọ̀ ní olówuuru. Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ méje tí Ọlọ́run fi ṣẹ̀dá àwọn nǹkan kì í ṣe ọjọ́ oní wákàtí mẹ́rìnlélógún, àmọ́ àkókò tó gùn ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọjọ́ náà túmọ̀ sí.—Jẹ́nẹ́sísì 1:31; 2:4.

2. Ẹlẹ́dàá Ọlọ́run fún ara rẹ̀ ní orúkọ àdáni kan, tó jẹ́ kó yàtọ̀ sí àwọn ọlọ́run èké, orúkọ náà ni Jèhófà (tàbí Yáwè, gẹ́gẹ́ bí ìtúmọ̀ Bíbélì ti Jerusalem Bible ti àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ṣe ń pè é, orúkọ yìí sì ni àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan lóde òní fara mọ́). a (Sáàmù 83:18) Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn lédè Hébérù nínú Ìwé Mímọ́ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Jésù jẹ́ ká mọ bí orúkọ yẹn ti ṣe pàtàkì tó, nígbà tó sọ nínú àdúrà àwòkọ́ṣe pé: “Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ.” (Matteu 6:9, Bibeli Mimọ) Ọlọ́run fẹ́ ká máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo, bó sì ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn. Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lo ère nínú ìjọsìn.—1 Jòhánù 5:21.

3. Jésù Kristi Òun ni Olùgbàlà, “Ọmọ Ọlọ́run,” àti “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá.” (Jòhánù 1:34; Kólósè 1:15; Ìṣe 5:31) Ẹni ọ̀tọ̀ kan ni Jésù jẹ́, kì í ṣe ara Mẹ́talọ́kan. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28) Ọ̀run ni Jésù ń gbé kó tó wá sí ayé, lẹ́yìn tó kú ikú ìrúbọ, ó jíǹde, ó sì pa dà sí ọ̀run. “Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ [rẹ̀].”—Jòhánù 14:6.

4. Ìjọba Ọlọ́run Ìjọba gidi kan tó máa ṣàkóso látọ̀run ni Ìjọba Ọlọ́run. Jésù Kristi ni ọba Ìjọba náà, òun pẹ̀lú àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] ni wọ́n jọ máa ṣàkóso, ìyẹn àwọn tá a “rà lára aráyé.” (Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1, 3, 4; Dáníẹ́lì 2:44; 7:13, 14) Wọ́n máa jọba lé ayé lórí, kò ní sí ìwà burúkú mọ́ ní ayé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó bẹ̀rù Ọlọrun ni yóò máa gbé ayé.—Òwe 2:21, 22.

5. Ayé Oníwàásù 1:4 sọ pé: “Aiye duro titi lai.” (Bibeli Mimọ) Lẹ́yìn tí àwọn èèyàn burúkú bá ti pa run, ayé máa di Párádísè, àwọn olódodo ni yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé. (Sáàmù 37:10, 11, 29) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú àdúrà àwòṣe yẹn á wá rí bẹ́ẹ̀ gan-an, ìyẹn, “ifẹ tirẹ ni ki a ṣe . . . li aiye.”—Mátíù 6:10, Bibeli Mimọ.

6. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì “Ọlọ́run . . . kò lè purọ́.” (Títù 1:2) Torí náà, gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run ló máa ń ní ìmúṣẹ, títí kan àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa òpin ayé yìí. (Aísáyà 55:11; Mátíù 24:3-14) Àwọn wo ló máa la ìparun tó ń bọ̀ já? Ìwé 1 Jòhánù 2:17 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”

7. Àwọn aláṣẹ ìlú Jésù sọ pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Máàkù 12:17) Fún ìdí yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pa òfin orílẹ̀-èdè mọ́, bí àwọn òfin náà kò bá lòdì sí òfin Ọlọ́run.—Ìṣe 5:29; Róòmù 13:1-3.

8. Iṣẹ́ Ìwàásù Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí” ní gbogbo ayé, kí òpin ayé yìí tó dé. (Mátíù 24:14) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé iṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là yìí jẹ́ iṣẹ́ tó ń buyì kúnni. Ohun kan ni pé, kálukú ló máa pinnu bóyá kí òun tẹ́tí sí ìwàásù wọn tàbí kí òun má ṣe tẹ́tí sí i. Bíbélì sọ pé: “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìṣípayá 22:17.

9. Ìrìbọmi Àwọn tó bá ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, tí wọ́n sì fẹ́ sin Ọlọ́run nípa jíjẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣèrìbọmi fún. (Hébérù 12:1) Èyí fi hàn pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n sì fi èyí hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi.—Mátíù 3:13, 16; 28:19.

10. Fífi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn àlùfáà àti ọmọ ìjọ Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Arákùnrin ni gbogbo yín jẹ́.” (Mátíù 23:8) Àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, títí kan àwọn tó kọ Bíbélì kò ní ẹgbẹ́ àlùfáà. Àpẹẹrẹ yìí, tó wà nínú Bíbélì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló hùmọ̀ orúkọ náà “Jèhófà.” Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, ni wọ́n ti ń pe orúkọ Ọlọ́run ní “Jèhófà” láwọn èdè míì yàtọ̀ sí èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì, títí kan èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Jámánì. Ó dunni pé, àwọn olùtumọ̀ Bíbélì òde òní kan ti fi àwọn orúkọ oyè bí “Ọlọ́run” àti “Olúwa” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run, èyí sì fi hàn pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún Ẹni tó ni Bíbélì rárá.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

“Baba tóbi jù mí lọ.”​—Jòhánù 14:28

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

“A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14