Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ìgbéyàwó Ṣe Lè Wà Pẹ́ Títí

Bí Ìgbéyàwó Ṣe Lè Wà Pẹ́ Títí

Ojú Ìwòye Bíbélì

Bí Ìgbéyàwó Ṣe Lè Wà Pẹ́ Títí

Mátíù 19:4-6, Jésù Kristi sọ pé: “Ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan‘ . . . Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”

NÍNÚ ayé yìí, ìlànà táwọn èèyàn ń tẹ̀ lé máa ń yí pa dà, wọ́n kò sì fojú pàtàkì wo ìgbéyàwó mọ́. Ọ̀pọ̀ tọkọtaya máa ń gbé pa pọ̀ títí dìgbà tí wọ́n á fi ṣá lójú ara wọn tàbí tí ìṣòro bá jẹyọ, nígbà míì ó sì lè jẹ́ ohun tí kò tó nǹkan, nígbà tó bá yá, wọ́n á pínyà tàbí kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀. Ó bani nínú jẹ́ pé ńṣe ni èyí máa ń kó wàhálà bá àwọn ọmọ.

Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí kì í ṣe ìyàlẹ́nu fún àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìyẹn àkókò tí a wà yìí, pé àwọn èèyàn kò ní ṣe ohun tó máa ń jẹ́ kí ìdílé wà pa pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọn kò ní jẹ́ adúróṣinṣin, wọ́n kò ní ní ìfẹ́ àtọkànwá àti ìfẹ́ àdánidá. (2 Tímótì 3:1-5) Ǹjẹ́ bí ìlànà rere ṣe ń di àwátì tó sì ń ṣàkóbá fún ìdílé tiẹ̀ kàn ẹ́? Ǹjẹ́ ò ń fi ojú pàtàkì wo ìgbéyàwó?

Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ìmọ̀ràn Bíbélì máa tù ẹ́ nínú, torí pé ọ̀pọ̀ ìdílé ti lo ìmọ̀ràn Bíbélì ó sì ti ṣe wọ́n láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká wo márùn-ún péré lára àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ṣe ìdílé láǹfààní. a

Ohun Márùn-Ún Tó Lè Mú Kí Ìgbéyàwó Wà Pẹ́ Títí

(1) Gbà pé Ọlọ́run ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀. Bí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà lápá òsì àpilẹ̀kọ yìí ṣe fi hàn, ohun mímọ́ ni ìgbéyàwó jẹ́ lójú Jésù, ohun mímọ́ náà ló sì jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Ọlọ́run bá àwọn ọkùnrin kan wí lọ́nà tó lágbára torí pé wọ́n kọ ìyàwó wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ fẹ́ àwọn obìnrin tó ṣì kéré lọ́jọ́ orí, èyí jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìgbéyàwó. Ọlọ́run sọ pé: “O ti da májẹ̀mú tí o dá pẹ̀lú ìyàwó tí o fẹ́ nígbà tí o wà ní ọ̀dọ́. Òun ni ẹnì kejì rẹ, o sì ti da májẹ̀mú tí o dá pẹ̀lú rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣèlérí níwájú Ọlọ́run pé o máa jẹ́ olóòótọ́ sí i.” Lẹ́yìn náà, Jèhófà wá sọ ọ̀rọ̀ tó lágbára yìí, ó ní: “Mo kórìíra rẹ̀ bí ẹnì kan lára yín bá ṣe nǹkan burúkú yìí sí ìyàwó rẹ̀.” (Málákì 2:14-16, Bíbélì Today’s English Version) Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run kò fojú yẹpẹrẹ wo ìgbéyàwó; ó ń kíyè sí ìwà tí ọkọ àti ìyàwó ń hù sí ara wọn.

(2) Jẹ́ ọkọ tó mọ ojúṣe rẹ̀. Bí ìpinnu pàtàkì kan bá wà láti ṣe nínú ìdílé, ẹnì kan ní láti wà tó máa fàṣẹ sí i. Ọkọ ni Bíbélì gbé ojúṣe yìí lé lọ́wọ́. Éfésù 5:23 sọ pé: “Ọkọ ni orí aya rẹ̀.” Àmọ́ jíjẹ́ olórí ìdílé kò wá sọ ọkọ di òǹrorò. Ọkọ gbọ́dọ̀ máa rántí pé “ara kan” ni òun àti ìyàwó òun jẹ́, torí náà ó gbọ́dọ̀ máa bọlá fún un, kó sì máa bá a jíròrò kó tó ṣe ìpinnu tó kan ìdílé. (1 Pétérù 3:7) Ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Bíbélì sọ ni pé “kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn.”—Éfésù 5:28.

(3) Jẹ́ alátìlẹyìn ọkọ rẹ. Bíbélì sọ pé “àṣekún” tàbí alátìlẹyìn ni aya jẹ́ fún ọkọ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Èyí tó fi hàn pé aya gbọ́dọ̀ máa fi ìwà rere rẹ̀ mú kí ìdílé ṣe àṣeyọrí. Níwọ̀n bí aya sì ti jẹ́ alátìlẹyìn ọkọ, kò gbọ́dọ̀ máa bá ọkọ rẹ̀ díje, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni yóò máa tì í lẹ́yìn tìfẹ́tìfẹ́, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí aláàfíà jọba nínú ìdílé. Éfésù 5:22 sọ pé: “Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn.” Tí kò bá wá fara mọ́ èrò ọkọ rẹ̀ lórí ọ̀ràn kan ńkọ́? Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kó sọ èrò rẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, gẹ́gẹ́ bí òun náà ṣe máa fẹ́ kí ọkọ rẹ̀ bá a sọ̀rọ̀.

(4) Má ṣe tan ara rẹ jẹ, mọ̀ pé ìṣòro máa wà. Bí èèyàn kò bá ronú jinlẹ̀ kó tó sọ̀rọ̀ tàbí tí kò bá sọ ọ̀rọ̀ tó fi inúure hàn, ó lè fa ìṣòro nínú ìdílé. Nǹkan míì tó tún máa ń fa ìṣòro ni ìṣúnná owó, àìsàn líle koko tàbí wàhálà ọmọ títọ́. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé, àwọn tó ṣe ìgbéyàwó “yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” (1 Kọ́ríńtì 7:28) Àmọ́ kò yẹ kí ìpọ́njú tàbí àdánwò sọ ìgbéyàwó di ahẹrẹpẹ. Ká sòótọ́, bí àwọn tọkọtaya bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì ní ọgbọ́n Ọlọ́run, wọ́n ti ní ohun tí wọ́n lè máa fi yanjú ọ̀rọ̀ tó lè dá ìyapa sílẹ̀ nìyẹn. Tí ìṣòro bá jẹ yọ nínú ìdílé rẹ, ǹjẹ́ o ní ọgbọ́n tó o lè fi yanjú rẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni.”—Jákọ́bù 1:5.

(5) Ẹ jẹ́ olóòótọ́ sí ara yín. Ohun tó wọ́pọ̀ jù lọ tó máa ń tú ìgbéyàwó ká ni àgbèrè, ìyẹn níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni, èyí tó jẹ́ ìdí kan ṣoṣo tí Ọlọ́run fọwọ́ sí pé èèyàn lè torí rẹ̀ kọ ọkọ tàbí aya rẹ̀ sílẹ̀. (Mátíù 19:9) Bíbélì sọ pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Hébérù 13:4) Kí ni àwọn tọkọtaya lè ṣe kó máa bàa di pé yóò máa wù wọ́n láti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn? Bíbélì sọ pé: “Kí ọkọ máa fi ohun ẹ̀tọ́ aya rẹ̀ fún un; ṣùgbọ́n kí aya pẹ̀lú máa ṣe bákan náà fún ọkọ rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 7:3, 4.

Àwọn kan lè máa ronú pé àwọn nǹkan márùn-ún tá a jíròrò yìí kọjá ohun tí èèyàn lè ṣe, tàbí pé kó bóde mu mọ́. Àmọ́ ẹ̀rí fi hàn pé àwọn tó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí máa ń gbádùn ìgbéyàwó wọn dáadáa. Kódà, ńṣe ni ọ̀rọ̀ wọn dà bíi ti ẹni tó bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run nínú gbogbo apá ìgbésí ayé rẹ̀. Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni pé: “Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” (Sáàmù 1:2, 3) Àṣeyọrí nínú ìgbéyàwó wà lára “gbogbo nǹkan” tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ìgbéyàwó, wo Ilé Ìṣọ́ February 1, 2011, ìyẹn ìwé ìròyìn tó ṣìkejì ìwé ìròyìn Jí!

KÍ LÈRÒ RẸ?

● Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ìkọ̀sílẹ̀?—Málákì 2:14-16.

● Báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ máa hùwà sí ìyàwó rẹ̀?—Éfésù 5:23, 28.

● Ọgbọ́n ta ló máa ń jẹ́ kí ìgbéyàwó wà pẹ́ títí?—Sáàmù 1:2, 3.