Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìkànnì Àjọlò Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Apá 2

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìkànnì Àjọlò Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Apá 2

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìkànnì Àjọlò Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Apá 2

To àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí bí wọ́n ti ṣe pàtàkì sí ẹ sí.

․․․․․ àṣírí mi

․․․․․ àkókò mi

․․․․․ irú ojú táwọn èèyàn á fi máa wò mí

․․․․․ àwọn tí mo yàn lọ́rẹ̀ẹ́

ÈWO ló ṣe pàtàkì sí ẹ jù lára àwọn ohun tó wà lókè yìí? Ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì lè ṣàkóbá fún èyí tó ṣe pàtàkì jù sí ẹ yẹn àtàwọn mẹ́ta tó kù.

Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ kó o máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Tó bá jẹ́ pé o ṣì ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ, àwọn ló máa pinnu bóyá ó yẹ kó o máa lò ó. a (Òwe 6:20) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé apá èyíkéyìí téèyàn bá lò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló ní àǹfààní àtàwọn ewu tirẹ̀. Torí náà, bí àwọn òbí rẹ bá sọ pé àwọn ò fẹ́ kó o lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ńṣe ni kó o gbà pẹ̀lú wọn.—Éfésù 6:1.

Àmọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn òbí rẹ fọwọ́ sí i pé kó o máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kí lo lè ṣe tí o kò fi ní kó sínú ewu? Àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” tó ṣáájú èyí sọ̀rọ̀ nípa apá méjì tó yẹ kó o ronú lé lórí, ìyẹn àṣírí rẹ àti àkókò rẹ. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa irú ojú táwọn èèyàn á máa fi wò ẹ́ àti àwọn tó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́.

IRÚ OJÚ TÁWỌN ÈÈYÀN Á FI MÁA WÒ Ẹ́

Tó o bá fẹ́ káwọn èèyàn máa fojú tó dáa wò ẹ́, o gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ohun tó máa jẹ́ káwọn èèyàn ní èrò burúkú nípa rẹ. Wo àpẹẹrẹ yìí ná, ká sọ pé o ní mọ́tò tuntun kan; kò síbì kankan tó ha tàbí tó tẹ̀ wọnú lára mọ́tò náà, nigínnigín ló wà. Ǹjẹ́ kò ní wù ẹ́ kí mọ́tò yẹn máa wà bẹ́ẹ̀ títí lọ? Àmọ́, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó bá lọ jẹ́ pé nítorí ìwà àìbìkítà rẹ, ńṣe lo lọ fi ọkọ̀ náà kọlu nǹkan, tó o sì tipa bẹ́ẹ̀ bà á jẹ́?

Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí ojú táwọn èèyàn á fi máa wò ẹ́ lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ọ̀dọ́bìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Cara sọ pé: “Tó o bá gbé fọ́tò tàbí ọ̀rọ̀ kan sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láìkọ́kọ́ ronú jinlẹ̀ dáadáa, èyí lè mú kí àwọn èèyàn máa fojú burúkú wò ẹ́.” Bí àpẹẹrẹ, ronú bí àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí ṣe lè ní ipa lórí ojú táwọn èèyàn á fi máa wò ẹ́:

Fọ́tò rẹ. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” (1 Pétérù 2:12) Àwọn nǹkan wo lo ti kíyè sí nígbà tó o bá wo àwọn fọ́tò táwọn èèyàn gbé sórí ìkànnì àjọlò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

“Nígbà míì, mo lè rí fọ́tò ẹnì kan tí mo ti máa ń fojú pàtàkì wo tẹ́lẹ̀ níbi tó ti fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni tó ti mutí yó.”—Ana, ọmọ ọdún 19.

“Mo mọ àwọn ọmọbìnrin kan tí wọ́n máa ń gbé àwọn fọ́tò tí wọ́n ti dúró lọ́nà tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àmọ́, wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọn kò bá sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”—Cara, ọmọ ọdún 19.

Kí ló máa jẹ́ èrò rẹ nípa irú èèyàn tí ẹnì kan jẹ́, tó o bá rí fọ́tọ̀ onítọ̀hún lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì níbi tó ti (1) múra lọ́nà tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe, tàbí (2) tó jọ pé ó ti mutí yó?

1 ․․․․․

2 ․․․․․

Àwọn ọ̀rọ̀ tó o máa ń kọ. Éfésù 4:29 sọ pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde.” Àwọn kan ti kíyè sí pé àwọn èèyàn máa ń sọ̀rọ̀ àlùfààṣá, wọ́n máa ń ṣe òfófó, tàbí kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ pálapàla lórí àwọn ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

“Ojú kì í ti àwọn èèyàn láti sọ ìsọkúsọ nígbà tí wọ́n bá wà lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kì í fi bẹ́ẹ̀ burú lójú wọn tí wọ́n bá kọ ọ́ sílẹ̀, bí ìgbà tí wọ́n bá sọ ọ́ jáde lẹ́nu. Ó lè jẹ́ pé ìwọ kì í ṣépè o, àmọ́ o lè máa kọ àwọn ọ̀rọ̀ pálapàla, o lè gbójúgbóyà kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí o kò ní lè sọ lójúkojú tàbí àwọn ọ̀rọ̀ rírùn pàápàá.”Danielle, ọmọ ọdún 19.

Ní èrò tìẹ, kí nìdí tó fi jẹ́ pé ojú kì í ti àwọn èèyàn láti sọ ìsọkúsọ nígbà tí wọ́n bá ń kọ ọ̀rọ̀ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

․․․․․

Ǹjẹ́ irú fọ́tò tó o gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti ọ̀rọ̀ tó o kọ síbẹ̀ tiẹ̀ ṣe pàtàkì? Bẹ́ẹ̀ ni o! Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Jane sọ pé: “Níléèwé wa, kókó pàtàkì tí ọ̀rọ̀ wa máa ń dá lé nìyẹn. A ti sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn agbanisíṣẹ́ ṣe lè wo ìsọfúnni nípa ẹni kan tó ń wáṣẹ́ lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tí wọ́n sì lè tipa bẹ́ẹ̀ pinnu irú èèyàn tí onítọ̀hún jẹ́.”

Nínú ìwé kan tó ń jẹ́ Facebook for Parents, tó sọ̀rọ̀ nípa Ìkànnì àjọlò Dókítà B. J. Fogg sọ pé, nǹkan tí òun máa ń ṣe nìyẹn nígbà tí òun bá fẹ́ gba ẹnì kan síṣẹ́. Ó ní: “Mo ka èyí sí ara ọgbọ́n tó yẹ kí n máa lò nígbà tí mo bá fẹ́ gba ẹnì kan síṣẹ́. Tí mo bá wo ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì àjọlò nípa ẹni tí mo fẹ́ gbà síṣẹ́, tí mo sí rí àwọn nǹkan tí kò bójú mu níbẹ̀, mi ò ní fẹ́ gba irú èèyàn bẹ́ẹ̀. Kí nìdí tí mo fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn tó bá máa bá mi ṣiṣẹ́ gbọ́dọ̀ mọ̀wà hù dáadáa.”

Tó bá jẹ́ pé Kristẹni ni ẹ́, nǹkan míì tiẹ̀ tún wà tó ṣe pàtàkì gan-an tó yẹ kó o ronú nípa rẹ̀, ìyẹn ni bí àwọn fọ́tò tàbí ọ̀rọ̀ tó o bá fi sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe lè ní ipa lórí àwọn ẹlòmíì, ì báà jẹ́ pé Kristẹni bíi tìẹ ni wọ́n tàbí wọn kì í ṣe Kristẹni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò sí ọ̀nà kankan tí àwa gbà jẹ́ okùnfà èyíkéyìí fún ìkọ̀sẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 6:3; 1 Pétérù 3:16.

Ohun Tó O Lè Ṣe

Bí àwọn òbí rẹ bá gbà ẹ́ láyè láti máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wo àwọn fọ́tò tó o gbé síbẹ̀, kó o wá bi ara rẹ pé: ‘Irú èèyàn wo ni fọ́tò yìí fi hàn pé mo jẹ́? Ṣé irú ẹni tí mo fẹ́ káwọn èèyàn gbà pé mo jẹ́ nìyí? Ǹjẹ́ ojú máa tì mí tí àwọn òbí mi, alàgbà kan tàbí tí ẹni tó fẹ́ gbà mí síṣẹ́ bá rí àwọn fọ́tò yìí?’ Tó bá jẹ́ pé ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè tó gbẹ̀yìn yìí jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ńṣe ló yẹ kó o ṣàtúnṣe. Ohun tí Kate, ọmọbìnrin ọdún mọ́kànlélógún [21] ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Alàgbà kan bá mi sọ̀rọ̀ nípa fọ́tò tí mo gbé sórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì mi, mo sì mọrírì rẹ̀ gan-an ni. Mo mọ̀ pé ńṣe ni arákùnrin yẹn kò fẹ́ kí n ṣe ohun tó máa mú káwọn èèyàn máa fi ojú burúkú wò mí.”

Bákan náà, fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tó o kọ sórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì rẹ àti èyí tí àwọn ẹlòmíì kọ síbẹ̀. Má ṣe fàyè gba “ọ̀rọ̀ òmùgọ̀” tàbí “ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn.” (Éfésù 5:3, 4) Jane, Ọmọbìnrin ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan sọ pé: “Nígbà míì, àwọn kan máa ń fi àwọn ọ̀rọ̀ tí kò dáa ránṣẹ́ tàbí kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n dọ́gbọ́n lo àwọn ọ̀rọ̀ kan láti sọ ìsọkúsọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kọ́ lo kọ ọ̀rọ̀ yẹn síbẹ̀, ńṣe ni irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ń fi ẹrẹ̀ yí ẹ lára, torí pé orí ìkànnì rẹ ni wọ́n kọ ọ́ sí.”

Tó o bá fẹ́ fi fọ́tò tàbí ọ̀rọ̀ sórí ìkànnì àjọlò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kí lo lè ṣe tí àwọn èèyàn kò fi ní máa fojú burúkú wò ẹ́?

․․․․․

ÀWỌN TÓ O YÀN LỌ́RẸ̀Ẹ́

Tó o bá ní mọ́tò tuntun, ṣé ẹnikẹ́ni tó o bá ṣáà ti rí ni wàá máa fi mọ́tò náà gbé? Bákan náà, tó bá jẹ́ pé àwọn òbí rẹ gbà kó o máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó yẹ kó o pinnu irú àwọn èèyàn tó o máa pè tàbí tó o máa gba ìkésíni wọn pé kẹ́ ẹ di ọ̀rẹ́. Báwo lo ṣe máa ṣe ìpinnu yìí lọ́nà tó dára?

“Ohun tó jẹ àwọn kan lógún ni bí wọ́n ṣe máa kó ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ jọ lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Wọ́n tiẹ̀ lè gbà kí ẹni tí wọn kò mọ̀ rí di ọ̀rẹ́ wọn.”—Nayisha, ọmọ ọdún 16.

“Tó o bá lọ sórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè tún di ọ̀rẹ́ pa dà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtijọ́. Àmọ́ nígbà míì, àwọn kan wà lára wọn tó jẹ́ pé ì bá dáa kó o má ṣe ní àjọṣe pẹ̀lú irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ mọ́.”—Ellen, ọmọ ọdún 25.

Ohun Tó O Lè Ṣe

Àbá: Ṣàyẹ̀wò kó o sì ṣàtúnṣe. Ṣàyẹ̀wò àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kó o sì ṣe àtúnṣe tó bá yẹ. Bó o ṣe ń ṣàyẹ̀wò orúkọ kọ̀ọ̀kan, bi ara rẹ pé:

1. ‘Ǹjẹ́ mo mọ irú èèyàn tí ẹni yìí jẹ́?’

2. ‘Irú fọ́tò àti ọ̀rọ̀ wo ló máa ń gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?’

3. ‘Ǹjẹ́ ẹni tí mo pè ní ọ̀rẹ́ mi yìí ti ní ipa tó dára nínú ìgbésí ayé mi?’

Ní oṣooṣù, mo sábà máa ń ṣàyẹ̀wò orúkọ àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bí mo bá rí ẹnì kan níbẹ̀ tí àwọn nǹkan tí mo rí nípa rẹ̀ kò tẹ́ mi lọ́rùn, tàbí tí mi ò mọ̀ dáadáa, ńṣe ni mo máa ń yọ orúkọ onítọ̀hún kúrò.”—Ivana, ọmọ ọdún 17.

Àbá: Ní ìlànà tí wàá máa tẹ̀ lé tó o bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́. Bó o ṣe máa ń ṣe tó o bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́ lójúkojú, bákan náà, ó yẹ kó o ní ìlànà tí wàá máa tẹ̀ lé tó o bá fẹ́ pe ẹnì kan láti wá di ọ̀rẹ́ rẹ, àti àwọn tí wàá máa gbà pé kí wọ́n dí ọ̀rẹ́ rẹ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. (1 Kọ́ríńtì 15:33) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Leanne sọ pé: “Ìlànà tí èmi máa ń tẹ̀ lé ni pé: Tí mi ò bá ti mọ ẹ́, mi ò ní gbà kó o di ọ̀rẹ́ mi. Bí mo bá rí ohun kan lórí ìkànnì rẹ tí kò tẹ́ mi lọ́rùn, ńṣe ni màá yọ ẹ́ kúrò lára orúkọ àwọn ọ̀rẹ́ mi, mi ò sì tún ní gbà láti fi orúkọ rẹ sí i mọ́.” Àwọn míì náà wà tó jẹ́ pé irú ìlànà yìí ni wọ́n ń tẹ̀ lé.

“Kì í ṣe gbogbo èèyàn ni mo máa ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́ lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, nítorí pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ léwu gan-an.”—Erin, ọmọ ọdún 21.

“Àwọn kan tá a jọ lọ síléèwé ti fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí mi pé ká di ọ̀rẹ́ lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí wà lára àwọn tí mi ò kì í fẹ́ bá da ohunkóhun pọ̀ rárá nígbà tá a ṣì wà níléèwé; kí wá nìdí tí máa fi wá dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ wọn báyìí”?—Alex, ọmọ ọdún 21.

Kọ ìlànà tí ìwọ á máa tẹ̀ lé tó o bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́ sórí ìlà yìí.

․․․․․

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé ìròyìn Jí! kò sọ pé ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kan ló dára tàbí pé ọkàn kò dára. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ rí i pé, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì kò ta ko àwọn ìlànà Bíbélì.—1 Tímótì 1:5, 19.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 26]

Òwe inú Bíbélì kan sọ pé: “Orúkọ ni ó yẹ ní yíyàn dípò ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀; ojú rere sàn ju fàdákà àti wúrà pàápàá.”—Òwe 22:1

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]

O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?

Kí ìwọ àtàwọn òbí rẹ jọ ṣàyẹ̀wò Apá 1 àpilẹ̀kọ yìí, tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! yìí. Kí ẹ jọ jíròrò bí lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe ń ní ipa lórí rẹ láwọn ọ̀nà mẹ́rin yìí: (1) àṣírí rẹ, (2) àkókò rẹ, (3) irú ojú táwọn èèyàn fi ń wò ẹ́, àti (4) àwọn tó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]

Ọ̀rọ̀ Rèé O, Ẹ̀yin Òbí

Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ rẹ lè mọ bí wọ́n ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì jù ẹ́ lọ. Àmọ́, wọn kò gbọ́n tó ẹ. (Òwe 1:4; 2:1-6) Ọ̀gbẹ́ni Parry Aftab, tó jẹ́ ọ̀mọ̀ràn nípa ààbò lórí lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì sọ pé: “Àwọn ọmọdé mọ púpọ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ṣùgbọ́n àwọn òbí mọ púpọ̀ nípa ìgbésí ayé.”

Lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí ibi tí wọn kì í ti í lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ǹjẹ́ o lè gbà kí ọmọ rẹ tó ti bàlágà máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Ìwọ lo máa pinnu ìyẹn. Ńṣe ni ọ̀rọ̀ yìí dà bíi wíwa mọ́tò, fífi owó pa mọ́ sí báńkì, ríra ọjà ní àwìn, kò sí èyí tó burú nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àmọ́ gbogbo wọn ló ní àwọn ewu tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú lílo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí tiẹ̀ ni díẹ̀ lára àwọn ewu yìí?

ÀṢÍRÍ. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ kò mọ ewu tó wà nínú kí wọ́n máa fi ìsọfúnni tó pọ̀ jù sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Tí wọ́n bá fi ibi tí wọ́n ń gbé, ilé ìwé tí wọ́n ń lọ, tàbí àwọn àkókò tí wọ́n máa ń wà nílé àti àwọn àkókò tí wọn kì í sí nílé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, irú àwọn ìsọfúnni yìí lè fi gbogbo ìdílé yín sínú ewu.

Ohun tó o lè ṣe. Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ṣì kéré, o kọ́ wọn pé kí wọ́n máa wo ọ̀tún àti òsì dáadáa kí wọ́n tó sọdá títì. Ní báyìí tí wọ́n ti wá dàgbà, ó yẹ kó o kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè yẹra fún ewu lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ka ìsọfúnni tó sọ̀rọ̀ nípa àṣírí nínú àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí. Lẹ́yìn náà, kó o wá jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ tó ti bàlágà. Sapá láti jẹ́ kí wọ́n ní “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú,” kí wọ́n lè yẹra fún ewu tó wà nínú lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì.—Òwe 3:21.

ÀKÓKÒ. Èèyàn lè sọ ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì di bárakú. Ọ̀dọ́kùnrin ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún kan tó ń jẹ́ Rick sọ pé: “Lẹ́yìn ọjọ́ bíi mélòó kan tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, agbára káká ni mo fi máa ń kúrò nídìí rẹ̀.” Mo máa fi ọ̀pọ̀ wákàtí wo àwọn fọ́tò àti àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀.”

Ohun tó o lè ṣe. Kí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ jọ jíròrò àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé,” tí àkọlé rẹ̀ sọ pé, “Ṣé Mo Ti Sọ Àwọn Ohun Tó Ń Gbé Ìsọfúnni Jáde Di Bárakú?” tó wà nínú ìtẹ̀jáde Jí! April–June 2011. Ẹ fiyè sí àpótí tí àkọlé rẹ̀ sọ pé, “Ìkànnì Táwọn Èèyàn Ti Ń Fọ̀rọ̀ Jomi Toro Ọ̀rọ̀ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì Di Bárakú fún Mi,” tó wà ní ojú ìwé 26. Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí ó lè jẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà,” kí ó sì lè máa díwọ̀n iye àkókò tí yóò máa lò nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì. (1 Timothy 3:2) Rán ọmọ rẹ létí pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó gbádùn mọ́ni ni èèyàn ṣì lè ṣe nígbà tó bá wà pẹ̀lú àwọn èèyàn lójúkojú!

IRÚ OJÚ TÁWỌN ÈÈYÀN Á FI MÁA WO ÌDÍLÉ YÍN. Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán. (Òwe 20:11) Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí tó bá kan lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì! Síwájú sí i, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló lè rí ohun tí ẹnì kan ń ṣe lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ohunkóhun tí àwọn ọmọ rẹ bá gbé sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì lè mú kí àwọn èèyàn máa fi ojú burúkú wo ìdílé yín.

Ohun tó o lè ṣe. Àwọn ọ̀dọ́ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ńṣe ni ohun tí àwọn bá kọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ hàn. Ó tún yẹ kí wọ́n mọ̀ pé ohunkóhun tí èèyàn bá ti kọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kì í ṣeé pa rẹ́. Nínú ìwé kan tó n jẹ́ CyberSafe, tí Dọ́kítà Gwenn Schurgin O’Keeffe kọ, ó sọ pé: “Ó lè ṣòro fún àwọn ọmọdé láti gbà pé ohun tí wọ́n bá kọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kì í ṣeé pa rẹ́, àmọ́ ó ṣe pàtàkì pé kí ọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ sí í yé wọn báyìí.” Ọ̀nà kan tí èèyàn lè gbà ṣàlàyé fún wọn ni pé, kéèyàn máa rán wọn létí pé ohun tí wọn kò bá ti lè sọ fún ẹnikẹ́ni lójúkojú, wọn kò gbọ́dọ̀ kọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”

ÀWỌN Ọ̀RẸ́. Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún kan tó ń jẹ́ Tanya sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn sí ẹni tó gbajúmọ̀. Torí náà, wọ́n máa ń gbà kí àwọn èèyàn tí wọn kò mọ̀ rí tàbí àwọn oníwàkiwà di ọ̀rẹ́ wọn.”

Ohun tó o lè ṣe. Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí ó lè ní ìlànà tí yóò máa tẹ̀ lé tó bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́ lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọdún méjìlélógún [22] kan tó ń jẹ́ Alicia kì í sábà gbà láti di ọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ tirẹ̀. Ó sọ pé: “Tí mi ò bá mọ ẹnì kan tàbí tí a kò bá tíì ríra lójúkojú, mi ò ní torí pé onítọ̀hún jẹ́ ọ̀rẹ́ fún ọ̀rẹ́ mi kan kí n wá fi orúkọ rẹ̀ sára àwọn ọ̀rẹ́ mi.”

Tọkọtaya kan tí orúkọ wọn ń jẹ́ Tim àti Julia ṣètò ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ń lò lọ́nà tó jẹ́ kí wọ́n lè máa rí àwọn ọ̀rẹ́ tí ọmọbìnrin wọn ní lórí Ìkànnì àjọlò, tí wọ́n á sì lè máa rí àwọn ọ̀rọ̀ àti fọ́tò tí òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń gbé síbẹ̀. Julia, ìyá ọmọ náà sọ pé: “A sọ fún ọmọ wa pé kí ó fi orúkọ wa sára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Ojú tá a fi ń wò ó ni pé ńṣe ni àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì wà nínú ilé wa. A fẹ́ mọ irú èèyàn tí wọ́n jẹ́.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Bó ṣe jẹ́ pé bí èèyàn bá wa ọkọ̀ níwàkuwà, ọkọ̀ náà lè forí sọ nǹkan kí ó sì bà jẹ́, àwọn èèyàn lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi ojú tí kò dáa wò ẹ́ tó o bá lọ gbé fọ́tò burúkú àti ọ̀rọ̀ tí kò dáa sórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Tó o bá ní mọ́tò, ṣé gbogbo èèyàn tó o bá ṣáà ti rí ni wàá máa gbé? Kí ló wá dé tí wàá fi gbà kí ìwọ àti ẹni tí o kò mọ̀ rí di ọ̀rẹ́ lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?