Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Ya Ọjọ́ Kan Sọ́tọ̀ Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Ọjọ́ Mímọ́?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Ya Ọjọ́ Kan Sọ́tọ̀ Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Ọjọ́ Mímọ́?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Ya Ọjọ́ Kan Sọ́tọ̀ Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Ọjọ́ Mímọ́?

KÁRÍ ayé, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, àwọn ẹlẹ́sìn Júù àtàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì máa ń ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi jọ́sìn lọ́nà àkànṣe. Kí nìdí? Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Ibrahim, tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, máa ń lọ kí ìrun jímọ̀ ní gbogbo ọjọ́ Friday, ó sì tún máa ń gbọ́ wáàsí. Ó sọ pé: “Mo fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run kí n sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn.”

Ǹjẹ́ Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run sọ pé ká máa ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ mímọ́? Ṣé jíjọ́sìn ní ọjọ́ kan pàtó ló máa jẹ́ kí ọkàn èèyàn balẹ̀ kéèyàn sì sún mọ́ Ọlọ́run?

Ètò Kan Tó Wà fún Ìgbà Díẹ̀

Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run lo wòlíì Mósè láti pèsè àwọn òfin àkànṣe kan. Lára ohun tó wà nínú Òfin náà ni ètò fún àwọn ọjọ́ ìsinmi tàbí Sábáàtì, tó jẹ́ ọjọ́ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ìjọsìn. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ọjọ́ tí wọ́n sábà máa ń yà sọ́tọ̀ fún ìsinmi ni ọjọ́ Sábáàtì. Ìgbà tí oòrùn bá wọ̀ lọ́jọ́ Friday ló máa ń bẹ̀rẹ̀, ó sì máa ń parí lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ lọ́jọ́ Saturday.—Ẹ́kísódù 20:8-10.

Ǹjẹ́ gbogbo àwọn èèyàn tó wà láyé nígbà yẹn ni Ọlọ́run sọ fún pé kí wọ́n máa pa ọjọ́ ìsinmi ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ yẹn mọ́? Rárá o. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn aláwọ̀ṣe nìkan ni Òfin Mósè wà fún. Ọlọ́run sọ fún Mósè pé: “Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì máa pa sábáàtì mọ́,  . . . Láàárín èmi àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àmì ni fún àkókò tí ó lọ kánrin.” aẸ́kísódù 31:16, 17.

Bíbélì sọ pé Òfin Mósè jẹ́ “òjìji àwọn nǹkan tí ń bọ̀.” (Kólósè 2:17) Torí náà, Sábáàtì jẹ́ ètò ìjọsìn tó wà fún ìgbà díẹ̀, èyí tó ń ṣàpẹẹrẹ ètò kan tó ṣe pàtàkì jù lọ́jọ́ iwájú. (Hébérù 10:1) Bíbélì fi hàn pé lójú Ọlọ́run, Òfin tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tó fi mọ́ pípa Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mọ́, wá sópin nígbà tí Jésù kú. (Róòmù 10:4) Kí ló wá rọ́pò rẹ̀?

Ọ̀nà Ìjọsìn Tuntun

Lẹ́yìn tí Òfin Mósè ti parí iṣẹ́ rẹ̀, Bíbélì sọ lọ́nà tó ṣe kedere, irú ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbà jọ́sìn òun. Ǹjẹ́ ọ̀nà ìjọsìn tuntun náà kan jíjọ́sìn ní ọjọ́ kan pàtó lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?

Ìwé Mímọ́ fi hàn pé àwọn àṣẹ kan tí Ọlọ́run pa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan àwọn Kristẹni pẹ̀lú. Lára rẹ̀ ni àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé ká má ṣe lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà àti àgbèrè, ká má sì máa jẹ ẹ̀jẹ̀. (Ìṣe 15:28, 29) Ó gbàfiyèsí pé àṣẹ láti máa pa Sábáàtì mọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kò sí lára àwọn àṣẹ tá a retí pé kí àwọn Kristẹni máa pa mọ́.—Róòmù 14:5.

Kí ni nǹkan míì tí Bíbélì tún sọ fún wa nípa ọ̀nà tí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní gbà jọ́sìn Ọlọ́run? Wọ́n máa ń pàdé déédéé láti gbàdúrà, wọ́n máa ń ka ìwé mímọ́, wọ́n máa ń gbọ́ àsọyé, wọ́n sì máa ń kọrin ìyìn sí Ọlọ́run. (Ìṣe 12:12; Kólósè 3:16) Ní àwọn ìpàdé yìí, àwọn Kristẹni máa ń gba ìtọ́sọ́nà, wọ́n máa ń fún ìgbàgbọ́ wọn lókun, wọ́n sì máa ń fún ara wọn ní ìṣírí lẹ́nì kìíní kejì.—Hébérù 10:24, 25.

Kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti sọ pé ọjọ́ Sunday tàbí ọjọ́ pàtó mìíràn lọ́sẹ̀ ni kí àwọn Kristẹni máa ṣe ìpàdé. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí wá nìdí tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi máa ń ya ọjọ́ Sunday sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ mímọ́? Ẹ̀yìn tí wọ́n ti parí kíkọ Bíbélì ni àṣà ṣíṣe ìjọsìn ní ọjọ́ Sunday bẹ̀rẹ̀, nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú onírúurú ìgbàgbọ́ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí kò bá Bíbélì mu wọnú ẹ̀sìn Kristẹni.

Ṣé Ọlọ́run wá tún òfin ṣe pé kí àwọn èèyàn máa pàdé ní ọjọ́ kan pàtó lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kí wọ́n lè jọ jọ́sìn ni? Rárá o. Gbogbo ohun tó yẹ ká máa ṣe láti jọ́sìn Ọlọ́run ni Bíbélì ti ṣàlàyé lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́. Kò sí ọ̀rọ̀ míì tí Ọlọ́run tún fi kún Ìwé Mímọ́ lẹ́yìn náà. Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé: “Àní bí àwa tàbí áńgẹ́lì kan láti ọ̀run bá polongo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere ohun tí ó ré kọjá nǹkan tí a ti polongo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere, kí ó di ẹni ègún.”—Gálátíà 1:8.

Ìjọsìn Tó Ń Tuni Lára Tó sì Ń Mú Inú Ọlọ́run Dùn

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìgbà ayé Jésù máa ń fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ọjọ́ mímọ́ nínú ọ̀sẹ̀, Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wọn, torí pé ohun tó wà ní ọkàn wọn kò dára. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó, wọ́n sì máa ń fi àbùkù kan àwọn gbáàtúù àti àwọn ẹni rírẹlẹ̀. Wọ́n máa ń fẹ́ ipò ọlá, oníwà ìbàjẹ́ ni wọ́n, wọ́n sì ki gbogbo ara bọ ọ̀ràn ìṣèlú nígbà ayé wọn. (Mátíù 23:6, 7, 29-33; Lúùkù 16:14; Jòhánù 11:46-48) Wọ́n sọ pé aṣojú Ọlọrun ni àwọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ṣètò Sábáàtì láti mú ara tu àwọn èèyàn, ńṣe ni wọ́n fi ọjọ́ Sábáàtì yìí ni àwọn èèyàn lára nípasẹ̀ àwọn òfin àtọwọ́dá wọn.—Mátíù 12:9-14.

Ó ṣe kedere pé, yíya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ mímọ́ kọ́ ló máa jẹ́ kí èèyàn jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà. Kí ló yẹ ká ṣe gan-an? Jésù fún àwọn èèyàn ní ìkésíni kan tó fani mọ́ra, ó ní: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.” (Mátíù 11:28) Ìjọsìn tá a gbé ka àwọn ẹ̀kọ́ Jésù máa ń tuni lára ní tòótọ́. Nínú irú ìjọsìn yìí, kò sí àgàbàgebè, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àwọn ààtò ẹ̀sìn tó ń ni èèyàn lára.

Kárí ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fara balẹ̀ tẹ̀ lé ọ̀nà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbà sin Ọlọ́run. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbádùn àwọn ìtọ́ni láti inú Bíbélì lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Bí ipò nǹkan bá ṣe rí ní àdúgbò ló máa ń pinnu ọjọ́ tí wọ́n máa ń ṣe àwọn ìpàdé wọn, kì í ṣe àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí kò bá Bíbélì mu ló ń darí wọn. A rọ̀ ẹ́ pé kó o lọ sí ọkàn lára àwọn ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń ṣe ìpàdé ní àdúgbò rẹ, kó o lè fojú ara rẹ rí bí wọ́n ṣe ń ṣe ìjọsìn tó ń túni lára.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí Bíbélì bá sọ pé “àkókò tí ó lọ kánrin”, gbogbo ìgbà kọ́ ló máa ń túmọ̀ sí títí láé. Ó tún lè túmọ̀ sí àkókò gígùn tàbí àkókò tí a kò mọ ìgbà tó máa dópin.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ṣé o gbọ́dọ̀ ya ọjọ́ kan pàtó sọ́tọ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ láti máa jọ́sìn Ọlọ́run?—Róòmù 10:4; 14:5.

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa pàdé láti jọ́sìn Ọlọ́run?—Hébérù 10:24, 25.

● Kí la lè ṣe kí ìjọsìn wa bàa lè tù wá lára lóòótọ́?—Mátíù 11:28.

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30, 31]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

TUESDAY

WEDNESDAY

1 THURSDAY

2 FRIDAY

3 SATURDAY

4 SUNDAY