Ìtàn Ọkùnrin Kan Tó Béèrè Ọ̀rọ̀
Ìtàn Ọkùnrin Kan Tó Béèrè Ọ̀rọ̀
● Kí lo fẹ́ kí àwọn èèyàn máa fi rántí rẹ? Kí ló máa wá sọ́kàn àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá rántí rẹ? Nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ ṣe orúkọ fún ara wọn, wọ́n máa ń forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n lè di olókìkí nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, ìṣèlú, eré ìdárayá, àti iṣẹ́ ọnà. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ìbéèrè tó o béèrè ni àwọn èèyàn fi rántí rẹ ńkọ́?
Ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún sẹ́yìn, ọkùnrin kan tó ń gbé ní Amẹ́ríkà Àárín béèrè àwọn ìbéèrè kan tó ń múni ronú jinlẹ̀. Nicarao ni orúkọ ọ̀gbẹ́ni yìí, ó sì jẹ́ olóyè kan ní àdúgbò rẹ̀. Ó ṣe kedere pé látinú orúkọ rẹ̀ ni orúkọ orílẹ̀-èdè náà, Nicaragua, ti jáde. Orúkọ rẹ̀ yìí ni wọ́n wá fi mọ ẹ̀yà tí àwọn èèyàn rẹ̀ ti wá, orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé àti adágún ńlá tó wà ní orílẹ̀-èdè náà.
Orí ilẹ̀ tóóró kan tó wà láàárín Òkun Pàsífíìkì àti Adágún Odò ńlá Nicaragua ni àwọn ẹ̀yà Nicarao ń gbé. Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn tí Columbus ti ṣàwárí Ìwọ̀ Oòrùn Ìlàjì ayé, tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Sípéènì fi lọ ṣàyẹ̀wò àgbègbè yìí. Ọ̀gákọ̀ Gil González Dávila ló kó àwọn èèyàn rẹ̀ gba àríwá láti ibi tá a wá mọ̀ ní báyìí sí Costa Rica, wọ́n sì wọ ilẹ̀ Nicarao ni ọdún 1523 Sànmánì Kristẹni.
Ẹ wo bí ẹ̀rù á ti máa ba àwọn arìnrìn-àjò yìí bí wọ́n ti ń lọ sí àgbègbè tí wọn kò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ńṣe ni ọkàn wọn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ nígbà tí wọ́n rí olóyè náà Nicarao! Gẹ́gẹ́ bí ìwà ọ̀làwọ́ ṣe jẹ́ àṣà àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Nicaragua títí di òní yìí, tọwọ́ tẹsẹ̀ ni wọ́n gba àwọn ọmọ ilẹ̀ Sípéènì náà lálejò, wọ́n fún wọn ní ẹ̀bùn, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ góòlù.
Nicarao fẹ́ kí wọ́n dáhùn àwọn ìbéèrè tó ti ń wá ìdáhùn sí látọjọ́ pípẹ́. Ìbẹ̀wò tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Sípéènì ṣe yìí ló tún mú kí ó béèrè àwọn ìbéèrè míì. Àwọn asọ̀tàn ròyìn pé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí ló béèrè lọ́wọ́ Ọ̀gákọ̀ González:
Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ pé àkúnya omi kàn pa àwọn èèyàn àti ẹranko run? Ǹjẹ́ Ọlọ́run tún máa fi àkúnya omi pa ayé run? Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn lẹ́yìn ikú? Báwo ni oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ṣe máa ń rìn kiri? Kí ló gbé wọn dúró sí ojú sánmà? Báwo ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe jìnnà tó sí ayé? Ìgbà wo ni oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ kò ní tan ìmọ́lẹ̀ mọ́? Ibo ni ẹ̀fúùfù ti ń wá? Kí ló máa ń fa ooru àti òtútù, ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn? Kí nìdí tí gígùn ọjọ́ fi máa ń yàtọ̀ síra jálẹ̀ ọdún?
Ó ṣe kedere pé ó wu Nicarao gan-an láti mọ̀ nípa ayé yìí àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀. Àwọn ìbéèrè rẹ̀ jẹ́ ká mọ ohun tó gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn rẹ̀. Wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí àti àwọn ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn jọ ti àwọn èèyàn òde òní. Ti pé Nicarao àti àwọn èèyàn rẹ̀ mọ̀ nípa àkúnya omi ńlá kan rán wa létí ìtàn kan náà tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 7:17-19.
Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé àṣà ìbẹ́mìílò àti fífi èèyàn rúbọ gbilẹ̀ ní ìlú Nicarao, ìwà àti ìṣe àwọn èèyàn rẹ̀ jẹ ẹ́ lógún gan-an ni. Àwọn ìbéèrè rẹ̀ fi hàn pé àwa èèyàn ní ẹ̀rí ọkàn tó máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó dára àti ohun tí kò dára. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí àti, láàárín ìrònú tiwọn fúnra wọn, a ń fẹ̀sùn kàn wọ́n tàbí a ń gbè wọ́n lẹ́yìn pàápàá.”—Róòmù 2:14, 15.
Ère tí wọ́n fi ń rántí Olóyè Nicarao ṣì wà ní ibi tí wọ́n sọ pé ó ti kọ́kọ́ pàdé àwọn arìnrìn-àjò ọmọ ilẹ̀ Sípéènì náà. Àròjinlẹ̀ tí ọkùnrin yìí ní ló mú kó ronú jinlẹ̀ nípa ìgbésí ayé àti àwọn nǹkan tó wà láyé. Àpẹẹrẹ àtàtà ló yẹ kí èyí jẹ́ fún wa.—Róòmù 1:20.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Nicaragua
AMẸ́RÍKÀ TI GÚÚSÙ
ÒKUN ÀTÌLÁŃTÍÌKÌ