Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run?

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run?

ÀǸFÀÀNÍ tí kò ṣeé díye lé ni àwa èèyàn ní pé a lè sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún Olódùmarè. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ ọnà tó tọ́ láti gbàdúrà, àwọn míì sì ń wá bí wọ́n ṣe máa mú kí àdúrà wọn túbọ̀ nítumọ̀. Ó ṣe kedere pé ó wu àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi pé kí àdúrà wọn túbọ̀ nítumọ̀. Ọ̀kan lára wọn sọ fún Jésù pé, “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà.” (Lúùkù 11:1) Jésù wá kọ́ wọn ní àdúrà àwòṣe, tí àwọn èèyàn sábà máa ń pè ní Àdúrà Olúwa tàbí Baba Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run. Àdúrà yìí dùn-ún gbọ́ létí, ó rọrùn, ó sì ń mú ká mọ bá a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run. Yàtọ̀ sí ìyẹn ó tún jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun pàtàkì tí Bíbélì dá lé.

Àdúrà Àwòṣe tí Jésù Kọ́ Wa

Jésù sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú. Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní; kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa. Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’”Mátíù 6:9-13.

Kíyè sí ohun tí Jésù sọ, ó ní: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí. Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Jésù kò fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa sọ ọ̀rọ̀ kan náà ní àsọtúnsọ. Kódà, kò pẹ́ tó sọ fún wọn pé kí wọ́n má ṣe máa gbàdúrà nírú ọ̀nà bẹ́ẹ̀. (Mátíù 6:7) Ńṣe ni Jésù tipasẹ̀ àdúrà àwòṣe náà kọ́ wa ní ohun tó yẹ kí á kà sí pàtàkì jù, ìyẹn ohun tó ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run, kì í ṣe lójú àwa èèyàn. Kí a bàa lè mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì yìí, ó yẹ kí a lóye àwọn ohun tí Jésù sọ nínú àdúrà náà. Jẹ́ kí á wá gbé àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú àdúrà náà yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

Àlàyé Lórí Àdúrà Àwòṣe

“Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” Ó dára gan-an bí Jésù ṣe pe Ọlọ́run ní “Baba” nítorí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa ó sì máa ń dáàbò bò wá, gẹ́gẹ́ bí bàbá rere kan ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ tó sì máa ń dáàbò bò wọ́n. Ọlọ́run tún ní orúkọ kan, orúkọ náà ni Jèhófà, orúkọ yìí sì yàtọ̀ pátápátá sí àwọn orúkọ oyè tó ní, bí Olódùmarè, Ọlọ́run àti Olúwa. a (Sáàmù 83:18) Nígbà náà, kí nìdí tí orúkọ Ọlọ́run fi di ohun tá a gbọ́dọ̀ yà sí mímọ́ tí èyí sì máa gba pé kí àtúnṣe bá ohun tí àwọn èèyàn ń sọ nípa Ọlọ́run àti èrò tí wọ́n ní nípa rẹ̀? Ìdí ni pé wọ́n ti ba orúkọ Ọlọ́run jẹ́ wọ́n sì ti pẹ̀gàn rẹ̀.

Àwọn kan máa ń dá Ọlọ́run lẹ́bi nígbà tí ìyà bá ń jẹ wọ́n. Ó sì lè jẹ́ pé àfọwọ́fà ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn, tàbí kí ó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ṣe kòńgẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú kan. (Òwe 19:3; Oníwàásù 9:11) Àwọn míì tiẹ̀ máa ń fẹ̀sùn kan Ọlọ́run pé òun ló ń fa àwọn àjálù. Ṣùgbọ́n, ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “A kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ló ń kọ́ni pé Ọlọ́run máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn nípa dídá wọn lóró nínú iná ọ̀run àpáàdì, inú Ọlọ́run ìfẹ́ kò dùn sí ẹ̀kọ́ yìí. (Jeremáyà 19:5; 1 Jòhánù 4:8) Àmọ́, kì í ṣe ìdálóró ayérayé ni Bíbélì pè ní èrè ẹ̀ṣẹ̀, ohun tó sọ ni pé, “ikú li ère ẹ̀ṣẹ.”! bRóòmù 6:23; Bíbélì Mímọ́.

“Kí ìjọba rẹ dé.” Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìṣàkóso gidi kan, Jésù Kristi ló sì máa jẹ́ Ọba ìjọba náà. Láìpẹ́, Jésù yóò bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gbogbo ayé pátá. Dáníẹ́lì 7:14 sọ pé: “A sì fún un ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba.” Ìjọba Ọlọ́run máa “dé” nígbà tó bá dá sí ọ̀rọ̀ aráyé, tí ó fọ́ gbogbo ìjọba ayé pátá, tó sì wá ń ṣàkóso lórí gbogbo ayé pátá.—Dáníẹ́lì 2:44.

“Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” Tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé, ìfẹ́ Ọlọ́run ni gbogbo aráyé á máa ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, ojúlówó àlàáfíà yòó gbilẹ̀, gbogbo èèyàn á sì máa jọ́sìn Ọlọ́run bí Ọlọ́run ṣe fẹ́. Ìṣèlú àti ìsìn èké tó ń fa ìpínyà kò ní sí mọ́. Lọ́nà àpẹẹrẹ, Ìṣípayá 21:3, 4 sọ pé “àgọ́ Ọlọ́run” yóò wà “pẹ̀lú aráyé,” “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”

“Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.” Lẹ́yìn tí Jésù ti sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Ọlọ́run àti Ìjọba Ọlọ́run, ó ṣẹ̀sẹ̀ wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tá a nílò. Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé kò sídìí láti máa ṣe kìràkìtà kọjá ohun tá a nílò “fún ọjọ́ òní.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn tó wà nínú Òwe 30:8 ló yẹ ká fi sílò, ó sọ pé: “Má ṣe fún mi ní ipò òṣì tàbí ti ọrọ̀. Jẹ́ kí n jẹ ìwọ̀n oúnjẹ tí ó jẹ́ ìpín tèmi.”

“Dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.” Ọ̀rọ̀ náà “àwọn gbèsè,” tí Jésù lò níbí yìí túmọ̀ sí “àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” c Ó yẹ kí gbogbo wa máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Torí náà, nígbà tá a bá ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, tàbí tá a dẹ́ṣẹ̀ sí i, ńṣe ni ó dà bíi pé a di ajigbèsè. Àmọ́, Jèhófà ṣe tán láti dárí gbèsè wa jì wá nígbà tí àwa náà bá dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá tìfẹ́tìfẹ́.—Mátíù 18:21-35.

“Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” “Ẹni burúkú náà” ni Sátánì Èṣù, tá a tún ń pè ní “Adẹniwò náà.” (Mátíù 4:3) Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, a nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run ká lè dojú ìjà kọ Èṣù àti àwọn èèyàn tó ń ṣojú fún un.—Máàkù 14:38.

Ǹjẹ́ kí àdúrà Jésù ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè túbọ̀ mú kí àdúrà rẹ nítumọ̀, bóyá kí o tiẹ̀ ṣàtúnṣe àwọn nǹkan tó o kà sí pàtàkì jù. Àmọ́, báwo ni àdúrà àwòṣe tí Jésù kọ́ wa, ṣe mú kí á túbọ̀ lóye ohun pàtàkì tí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì dá lé? Ọ̀rọ̀ Jésù fi hàn pé, ohun pàtàkì tí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì dá lé ni pé Ọlọ́run máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, yóò mú gbogbo ìwà ibi kúrò láyé, àti pé Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso ayé lọ́nà tí àlàáfíà fi máa gbilẹ̀. Wo bí àdúrà àwòṣe tí Jésù kọ́ wa ṣe mú kí á túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i!

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ìyẹn èdè Hébérù àti Gíríìkì, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà ni orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n, ó ṣeni láàánú pé, orúkọ oyè tí Ọlọ́run ní ni ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì tó wà lóde òní lò dípò orúkọ mímọ́ rẹ̀.

b Kì í ṣe pé àwọn òkú máa ń gbé ara míì wọ̀ tí wọ́n á sì lọ máa gbé ní ibòmíì, ṣùgbọ́n ńṣe ni wọ́n ń ‘sùn,’ tàbí pé “wọn kò mọ nǹkan kan rárá,” títí dìgbà tí wọ́n máa jíǹde lọ́jọ́ iwájú.—Jòhánù 5:28, 29; 11:11-13; Oníwàásù 9:5.

c Wo Lúùkù 11:4, níbi tí Bíbélì ti lo ọ̀rọ̀ méjèèjì náà pa pọ̀.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí”?​—Mátíù 6:9.

● Kí ni ohun tó yẹ kó gba iwájú nínú àdúrà wa?—Mátíù 6:9, 10.

● “Àwọn gbèsè” wo la jẹ, kí sì nìdí tó fi yẹ ká dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá?​—Mátíù 6:12.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àdúrà àwòṣe Jésù lè mú kó o mọ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run, kì í ṣe ohun tí ìwọ kà sí pàtàkì jù