Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Lo Ṣe Lè Wà Ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn?

Báwo Lo Ṣe Lè Wà Ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Báwo Lo Ṣe Lè Wà Ní Àlàáfíà Pẹ̀lú Àwọn Èèyàn?

BÍBÉLÌ sọ nípa àwa èèyàn pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Nítorí bó ṣe jẹ́ pé aláìpé ní gbogbo èèyàn tó ń bẹ láyé, kò sóhun tá a lè ṣe tí gbúngbùngbún ò fi ní máa wáyé. Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá wáyé, kí la lè ṣe láti wá àlàáfíà?

Bíbélì fún wa ní ìmọ̀ràn tó ṣeé múlò. Ó pe Ẹlẹ́dàá wa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà ní “Ọlọ́run àlàáfíà.” (Hébérù 13:20; Sáàmù 83:18) Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ara wọn. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa nípa bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí tọkọtaya àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ba àjọṣe rere tí wọ́n ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Ọlọ́run ti ṣe ohun tó máa jẹ́ kí àárín òun àti àwa èèyàn padà gún régé. (2 Kọ́ríńtì 5:19) Jẹ́ ká jíròrò àwọn nǹkan mẹ́ta tó o lè ṣe láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn.

Máa Dárí Jini Fàlàlà

Kí ni Bíbélì sọ? “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.”—Kólósè 3:13.

Kí ló lè mú kí ó ṣòro láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò? Ó ṣeé ṣe kó o ní “ìdí fún ẹjọ́” lòdì sí ẹni tó ṣẹ̀ ọ́, kó o sì rí i pé ohun tó tọ́ ni pé kó o yẹra fún un. O sì lè ronú pé ó dìgbà tí ẹni náà bá kọ́kọ́ wá tọrọ àforíjì. Àmọ́, tó bá lọ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀ pé òun ṣẹ̀ ọ́ tàbí tó sọ pé ìwọ lo jẹ̀bi, ṣe ni ọ̀rọ̀ náà á túbọ̀ ta kókó.

Kí lo lè ṣe? Ṣe ni kó o fi ìmọ̀ràn tí Bíbélì fúnni sílò, kó o dárí ji ẹni náà fàlàlà, pàápàá tí ọ̀ràn náà kò bá to nǹkan. Fi sọ́kàn pé, ká ní Ọlọ́run kì í gbójú fo àwọn àṣìṣe wa ni, kò sí ẹni tí yóò lè dúró níwájú rẹ̀. (Sáàmù 130:3) Bíbélì sọ pé “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, Ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, Ó rántí pé ekuru ni wá.”—Sáàmù 103:8, 14.

Tún kíyè sí òwe inú Bíbélì tó sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” (Òwe 19:11) Ìjìnlẹ̀ òye máa ń jẹ́ kí á wo ọ̀ràn kan tinú tẹ̀yìn, ó máa ń jẹ́ ká rí ìdí tí àwọn èèyàn fi sọ̀rọ̀ tàbí ìdí tí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n ṣe. Nítorí náà, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé kì í ṣe pé ẹni tó sẹ̀ mí yìí ti ṣiṣẹ́ tó sì ti rẹ̀ ẹ́, ṣé kì í ṣe pé ara rẹ̀ kò yá tàbí ìṣòro kan ló ń bá a fínra lákòókò yẹn?’ Tó o bá finú wòye ohun tó fà á gan-an tí ẹnì kan fi ṣẹ̀ ọ́, tó o mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀ àti ìṣòro tó ń bá a fínra, èyí kò ní jẹ́ kó o bínú kọjá àyè, àti pé ó máa jẹ́ kó rọrùn fún ọ láti gbójú fo àṣìṣe onítọ̀hún.

Ẹ Sọ̀rọ̀ Náà Kí Ó Yanjú

Kí Ni Bíbélì Sọ? “Bí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, lọ fi àléébù rẹ̀ hàn án láàárín ìwọ àti òun nìkan. Bí ó bá fetí sí ọ, ìwọ ti jèrè arákùnrin rẹ.”—Mátíù 18:15.

Kí ló lè mú kí ó ṣòro láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò? Ìbẹ̀rù, ìbínú, àti ìtìjú lè mú kí ó ṣòro fún ọ láti tọ ẹni náà lọ kẹ́ ẹ sì jọ yanjú ọ̀rọ̀ náà. Ó sì lè ṣe ọ́ bíi pé kí o wá àwọn agbọ̀ràndùn tí wàá sọ ìṣòro náà fún, èyí tó lè mú kí ọ̀ràn náà tàn kálẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.

Kí lo lè ṣe? Bí ìṣòro náà bá tóbi débi pé o kò ní lè gbójú fò ó, rí i pé o lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni náà kẹ́ ẹ sì jọ yanjú ọ̀rọ̀ náà. Ẹ gbìyànjú àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí láti yanjú ọ̀rọ̀ náà:

(1) Má ṣe jẹ́ kó pẹ́: Má ṣe fòní-dónìí fọ̀la-dọ́la. Bí o kò bá tètè gbé ìgbésẹ̀, kò ní pẹ́ tí ọ̀ràn náà á fi gbalẹ̀ bí iná ọyẹ́. Gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn Jésù sílò, ó sọ pé: “Bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.”—Mátíù 5:23, 24.

(2) Má se tan ọ̀rọ̀ náà ká: Má ṣe jẹ́ kí ẹran ara sún ọ láti wá máa sọ ọ̀ràn náà fún àwọn míì. “Ro ẹjọ́ tìrẹ pẹ̀lú ọmọnìkejì rẹ, má sì ṣí ọ̀rọ̀ àṣírí ẹlòmíràn payá.”—Òwe 25:9.

(3) Ẹ sọ ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí-ìnùbí: Ẹ má ṣe máa gba ọ̀rọ̀ náà bí ẹni gba igbá ọtí, kẹ́ ẹ máa wá ẹni tó jẹ̀bi àti ẹni tó jàre. Àlàáfíà lò ń wá, kì í ṣe pé o fẹ́ borí nínú ìjà. Gbìyànjú kó o máa lo ọ̀rọ̀ náà, “èmi” dípò tí wàá fi sọ pé “ìwọ.” Ó máa dára tó o bá lè sọ fún ẹni náà pé “Ohun tó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà dùn mí ni pé . . . ” dípò tí wàá fi sọ pé: “O múnú bí mi!” Ohun tí Bíbélì sọ ni pé: “Ẹ jẹ́ kí á máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.”—Róòmù 14:19.

Ní Ìpamọ́ra

Kí ni Bíbélì sọ? “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Ṣùgbọ́n, “bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní ohun kan láti mu.’”—Róòmù 12:17, 20.

Kí ló lè mú kí ó ṣòro láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò? Tó bá dà bíi pé ẹni náà kò gbà kẹ́ ẹ yanjú ọ̀ràn náà lákọ̀ọ́kọ́, ó lè ṣe ẹ́ bíi pé kó o pa á tì.

Kí lo lè ṣe? Mú sùúrù. Bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára wa yàtọ̀ síra, a sì máa ń ri ara gba ọ̀rọ̀ sí ju ara wa lọ. Ó máa ń pẹ́ kí ìbínú tó kúrò lára àwọn kan; àwọn míì sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run kọ́ra ni. Máa ṣe inúure sí ẹni náà nìṣó kó o sì máa fìfẹ́ hàn sí i. Bíbélì sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.”—Róòmù 12:21.

Ká tó lè wá ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, a gbọ́dọ̀ sapá láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ọgbọ́n, sùúrù àti ìfẹ́. Àmọ́, irú ìsapá bẹ́ẹ̀ láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ!

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí ló máa ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè máa dárí jini fàlàlà?—Kólósè 3:13.

● Kí ló máa jẹ́ kó o lè lọ sọ́dọ̀ ẹni tẹ́ ẹ jọ ní aáwọ̀ láti yanjú ọ̀ràn náà?​—Mátíù 5:23, 24.

● Kí lo lè ṣe tí ẹni náà kò bá gbà pé kẹ́ ẹ yanjú ọ̀rọ̀ náà?​—Róòmù 12:17-21.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

“Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.”​—ÒWE 19:11