Jíjẹ́ Olóòótọ́ Ló Máa Ń Mú Kí Èèyàn Ṣe Àṣeyọrí Tó Tọ́jọ́
Jíjẹ́ Olóòótọ́ Ló Máa Ń Mú Kí Èèyàn Ṣe Àṣeyọrí Tó Tọ́jọ́
“Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.”—Lúùkù 12:15.
PÀTÀKÌ ni owó jẹ́ ní ìgbésí ayé àwa èèyàn. Ọlọ́run sọ pé ojúṣe wa ló jẹ́ láti pèsè fún ara wa àti àwọn ìdílé wa.—1 Tímótì 5:8.
Àmọ́, kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí ìdí tí èèyàn fi ń wá owó bá ti kọjá àtijẹ àtimu, ibi tí èèyàn á máa gbé àti aṣọ tí èèyàn á máa wọ̀? Tó bá lọ jẹ́ pé eré àtilówó ni èèyàn ń fi ojoojúmọ́ ayé sá ńkọ́? Àtilọ́wọ́ nínú ìwà àìṣòótọ́ kì í pẹ́ rárá fún àwọn tó jẹ́ pé gbogbo ohun tí wọ́n ń rò kò ju bí wọ́n ṣe máa di olówó lọ. Wọ́n lè má tètè fura pé ìwà àìṣòótọ́ tí àwọn ń hù ni kò jẹ́ kí àwọn ṣe àṣeyọrí tó máa tọ́jọ́. Bákan náà, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, ìfẹ́ owó máa ń fa ọ̀pọ̀ ìrora.—1 Tímótì 6:9, 10.
Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ àwọn mẹ́rin kan tó jẹ́ pé kì í ṣe níní owó rẹpẹtẹ àti ohun ìní púpọ̀ ni wọ́n kà sí àṣeyọrí.
Iyì Ara Ẹni
“Ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, oníbàárà kan fẹ́ gbé iṣẹ́ kan fún mi tí iye owó ọjà náà sì jẹ́ mílíọ̀nù kan owó dọ́là (owó yìí lé ní àádọ́jọ [150] mílíọ̀nù náírà.) Iye tó máa jẹ́ èrè tèmi níbẹ̀ á sì tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún owó dọ́là. Àmọ́, ó sọ pé bí òun bá máa gbé iṣẹ́ náà fún mi, òun máa gba ìdajì nínú iye tó jẹ́ èrè tèmi. Òun tó fẹ́ kí n ṣe yẹn kò bófin mu rárá, ìwà àìṣòótọ́ ni, mo sì jẹ́ kó mọ̀ bẹ́ẹ̀.
“Kí ó lè ronú jinlẹ̀ nípa bí ohun tó fẹ́ ṣe yìí ti burú tó, mo bi í bóyá ó máa fẹ́ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tó jẹ́ oníjìbìtì, àti pé ṣé á sì fún onítọ̀hún ní àwọn ìsọfúnni nípa ara rẹ̀ àti nípa ìṣúnná owó rẹ̀. Mo tún wá jẹ́ kó mọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i pé mi ò lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, mo sì sọ fún un pé tó bá ṣì fẹ́ kí èmi àti òun jọ dòwò pọ̀ kí ó ké sí mi. Ṣùgbọ́n mi ò tún gbúròó rẹ̀ mọ́ látìgbà yẹn.
“Ká sọ pé mo gbà pẹ̀lú rẹ̀ ni, mo di aláìṣòótọ́ nìyẹn, ẹnu mi ò sí ní gbà á láti máa sọ fún àwọn èèyàn pé Kristẹni ni mí. Ńṣe ni màá sì wá di ẹrú ẹni tó tì mí sí ìwà jìbìtì náà.”—Don, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Ìbàlẹ̀ Ọkàn
Bá a ṣe sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, wọ́n fún Danny ní owó ribiribi gẹ́gẹ́ bí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí ó lè pa irọ́ fún ilé iṣẹ́ tirẹ̀ pé ilé iṣẹ́ tí wọ́n rán òun lọ máa lè ṣe àwọn nǹkan tí àwọn fẹ́, nígbà tó sì jẹ́ pé wọn ò lè ṣe nǹkan náà. Kí ni Danny ṣe?
“Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà fún bó ṣe fi oúnjẹ ṣe mí lálejò, mo sì dá àpò ìwé tí owó wà nínú rẹ̀ pà dà fún un. Ó tún rọ̀ mí pé bí mo bá lè jẹ́ kí àwọn rí iṣẹ́ náà gbà, àwọn tún máa fún mi lówó sí i. Ṣùgbọ́n mi ò gbà.
“Ká sọ pé mo gba owó náà ni, gbogbo ìgbà ni ẹ̀rù á máa bà mí pé, àṣírí máa tú lọ́jọ́ kan. Nígbà tó yá, ọ̀gá mi wá gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ náà. Inú mi dùn, ọkàn mi sì balẹ̀ pé mi ò ṣe ohun má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ kankan. Òwe 15:27 ló sọ sí mi lọ́kàn, ó ní: ‘Ẹni tí ń jẹ èrè aláìbá ìdájọ́ òdodo mu ń mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá bá ilé ara rẹ̀, ṣùgbọ́n olùkórìíra àwọn ẹ̀bùn [tàbí àbẹ̀tẹ́lẹ̀] ni yóò máa wà láàyè nìṣó.’”—Danny, orílẹ̀-èdè Hong Kong.
Ayọ̀ Nínú Ìdílé
“Mo dá ilé iṣẹ́ kọ́lékọ́lé kan sílẹ̀. Kì í ṣe ohun tó ṣòro fún mi rárá láti máa yan àwọn oníbàárà mi jẹ tàbí kí n má ṣe máa san owó orí. Ṣùgbọ́n, mo ti pinnu pé mi ò ní lọ́wọ́ sí ìwà àìṣòótọ́ kankan, èyí sì ti ṣe èmi àti ìdílé mi láǹfààní gan-an.
“Kì í ṣe nínú iṣẹ́ tàbí ìṣòwò nìkan ni èèyàn ti lè fi hàn pé òun jẹ́ olóòótọ́, ó tún kan irú ẹni tí èèyàn jẹ́ látòkèdélẹ̀. Bí èèyàn bá mọ̀ pé ọkọ tàbí aya òun máa rọ̀ mọ́ ìlànà Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ jíjẹ́ olóòótọ́, ó máa ń mú kí àwọn tó wà nínú ìdílé túbọ̀ máa fọkàn tán ara wọn. Ó máa ń fi tọkọtaya lọ́kàn balẹ̀ tí wọ́n bá mọ̀ pé ìgbà gbogbo ni ẹnì kejì àwọn máa ń hùwà tó tọ́.
“Ẹnì kan lè ní ilé iṣẹ́ tó jẹ́ pé òun ló tóbi jù lọ lágbàáyé, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìfọ̀kànbalẹ̀ àti àlàáfíà nínú ìdílé kò ṣeé fowó rà. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, mo sì ti rí i pé tí èèyàn bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ìgbésí ayé onítọ̀hún á wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Èmi àti ìdílé mi máa ń gbádùn ara wa dáadáa, mi ò kọjú síbi tí ayé kọjú sí, nítorí pé owó àti ẹ̀mí ìwọra ló ń darí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn.”—Durwin, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.
Àjọṣe Tó Dára Pẹ̀lú Ọlọ́run
“Ní ibiṣẹ́ mi, ara iṣẹ́ tí mò ń ṣe ni ríra àwọn nǹkan tá a máa ń lò. Nígbà míì, àwọn tí mo máa ń rajà lọ́wọ́ wọn máa ń sọ fún mi pé dípò tó fi máa jẹ́ pé ilé iṣẹ́ wa ló máa gba ẹ̀dínwó orí ọjà tí wọ́n bá tà fún wa, àwọn á máa kó ẹ̀dínwó orí ọjà náà fún mi. Àmọ́, bí ìgbà ti mo ja ilé iṣẹ́ wa lólè nìyẹn.
“Owó oṣù tí mò ń gbà kò tó nǹkan, mo sì lè ná owó tí wọ́n fi lọ̀ mí yẹn sórí nǹkan míì. Ṣùgbọ́n kò sí ohun tá a lè fi wé kí èèyàn ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ àti àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Nítorí náà, nígbàkigbà tí mo bá lọ rajà, ìlànà Bíbélì tó wà ní Hébérù 13:18 ni mo máa ń tẹ̀ lé, ó ní: ‘A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.’”—Raquel, orílẹ̀-èdè Philippines.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Ìlànà Tó Yẹ Kí Olóòótọ́ Èèyàn Máa Tẹ̀ Lé Lẹ́nu Iṣẹ́ Ajé
Ìlànà tí àwọn èèyàn ń tẹ̀ lé lórí irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù lẹ́nu iṣẹ́ ajé yàtọ̀ láti ibì kan sí ibòmíràn. Àmọ́, àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì ló yẹ kéèyàn máa tẹ̀ lé láti pinnu irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù. Bó o bá fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ajé rẹ, àwọn ìlànà mẹ́fà tó yẹ kó o máa tẹ̀ lé rèé:
Máa sọ òtítọ́
Ìlànà: “Ẹ má ṣe máa purọ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—Kólósè 3:9.
Má ṣe máa jáni kulẹ̀
Ìlànà: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.”—Mátíù 5:37.
Jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán
Ìlànà: “Aṣiri elomiran ni iwọ kò gbodo fihàn.”—Òwe 25:9, Bíbélì Mímọ́.
Jẹ́ olóòótọ́
Ìlànà: “Kí o má gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ ojú àwọn tí ó ríran kedere.”—Ẹ́kísódù 23:8.
Máa fi ọ̀rọ̀ ro ara rẹ wò
Ìlànà: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12.
Máa tẹ̀ lé òfin
Ìlànà: “Ẹ fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, ẹ fún un ní owó orí.”—Róòmù 13:7.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Olóòótọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ajé Rẹ
● Mọ Ohun Tó O Kà sí Pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, èwo lo kà sí pàtàkì jù nínú nǹkan méjì yìí: kí o ní owó rẹpẹtẹ tàbí kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run má ṣe bà jẹ́?
● Pinnu Ohun Tó O Máa Ṣe. Ronú nípa àwọn ipò tó lè mú kó o hùwà àìṣòótọ́, kó o sì pinnu ohun tí wàá ṣe nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀.
● Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Mọ Ìlànà Tí Ò Ń Tẹ̀ Lé. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni kó o ti jẹ́ kí àwọn tí ẹ jọ fẹ́ da òwò pọ̀ mọ àwọn ìlànà tí ò ń tẹ̀ lé.
● Fi Ọ̀rọ̀ Lọ Àwọn Ẹlòmíì. Tó o bá dojú kọ ìdẹwò tàbí tí o kò mọ ohun tí ó tọ́ láti ṣe, fi ọ̀rọ̀ lọ àwọn tó ń tẹ̀ lé irú ìlànà tí ìwọ náà ń tẹ̀ lé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Tó o bá jẹ́ olóòótọ́, wàá ní ìbàlẹ̀ ọkàn