Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Mo Fi Sọ Irú Ọ̀rọ̀ Yìí?

Kí Nìdí Tí Mo Fi Sọ Irú Ọ̀rọ̀ Yìí?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Kí Nìdí Tí Mo Fi Sọ Irú Ọ̀rọ̀ Yìí?

Àpilẹ̀kọ yìí á jẹ́ kó o rí

ÌDÍ tó o fi máa ń ṣi ọ̀rọ̀ sọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan

OHUN tó o lè ṣe tó o bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ

BÍ O ṢE LÈ máa ṣọ́ ẹnu rẹ

“Mo sábà máa ń ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí mo bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ, ó máa ń tì mí lójú gan-an!”​—Chase

“Ìgbà míì wà tí mo máa ń sọ ohun tó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn máa rò lọ́kàn, àmọ́ tí kò yẹ kí èèyàn sọ jáde lẹ́nu . . . Àṣìṣe ńlá gbáà lèyí jẹ́!”​—Allie

ÌDÍ TÓ FI ṢẸLẸ̀

Ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ: “Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé.” (Jákọ́bù 3:2) Kí ni ìtumọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí? Ohun tó tú mọ̀ sí ni pé kò sí ẹni tí kì í ṣi ọ̀rọ̀ sọ. Ọ̀pọ̀ ló máa gbà pẹ̀lú Annette, a tó sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, mo ti máa ń sọ̀rọ̀ tán kí n to wá rí i pé kò yẹ kí n sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.”

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan: “Ọ̀rẹ́ mi kan sọ pé kí n fún òun ni aṣọ kan tí mo fẹ́ kó dà nù. Láìtiẹ̀ ronú rárá, ńṣe ni mo kàn sọ pé, mi ò rò pé àwọn aṣọ yìí máa bá ẹ́ mu. Ó wá sọ pé ‘Kò lè bá mi mu kẹ̀? Ṣé ohun tó o wá ń sọ ni pé mo ti sanra jù?’”—Corrine.

Tó o bá fẹ́ mọ ohun tó ṣeé ṣe kó fà á tó fi jẹ́ pé o máa ń sọ ohun tí kò yẹ kó o sọ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè ṣe ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí.

● Mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro rẹ.

․․․․․ Mo sábà máa ń fi ìbínú sọ̀rọ̀

․․․․․ Mo sábà máa ń sọ̀rọ̀ láìronú

․․․․․ Mo sábà máa ń sọ̀rọ̀ láì fetí sílẹ̀ nígbà táwọn ẹlòmíì bá ń sọ̀rọ̀

․․․․․ Nǹkan míì ․․․․․

Àpẹẹrẹ: “Ìṣòro tèmi ni pé àwàdà mi ti pọ̀ jù, àwọn èèyàn sì máa ń ṣì mí lóye nígbà míì.”—Alexis.

Mọ àwọn tó jẹ́ pé ìgbà tó o bá wà pẹ̀lú wọn lo sábà máa ń sọ ohun tí kò yẹ kó o sọ.

․․․․․ Òbí mi

․․․․․ Ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi

․․․․․ Ọ̀rẹ́ mi

․․․․․ Àwọn míì ․․․․․

Àpẹẹrẹ: “Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ogún ọdún kan tó ń jẹ́ Christine sọ pé: Ó máa ń dùn mí pé àwọn èèyàn tí mo fẹ́ràn jù ni mo sábà máa ń ṣẹ̀ jù. Mo rò pé ohun tó fà á ni pé mo gbà pé ọ̀dọ̀ àwọn tèmi ni mo wà, torí náà mo lè sọ̀rọ̀ bó bá ṣe wù mí.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE NÍGBÀ TÓ O BÁ ṢI Ọ̀RỌ̀ SỌ

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó yẹ kó o fi sọ́kàn: “Máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà.” (Róòmù 14:19) Ọ̀nà kan tó o lè gbà fi ìmọ̀ràn yìí sílò ni pé kó o tọrọ àforíjì.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan: “Ọmọ oṣù mẹ́wàá ni mo wà nígbà tí mọ́mì mi kú, ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n mọ́mì mi àti ọkọ wọn ni mo sì gbé dàgbà, mi ò sì mọ dádì mi rárá. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá sí mọ́kànlá, lọ́jọ́ kan ẹ̀dùn ọkàn bá mi gidigidi, inú sì ń bí mi pé mi ò ní ìyá, èyí sì mú kí n máa kanra gan-an. Torí náà, nígbà tí ẹ̀gbọ́n mọ́mì mi sọ pé kí n bá àwọn ṣe nǹkan kan, ńṣe ni mo jágbe mọ́ wọn; ti mo sì sọ fún wọn pé, ‘ẹ fi mi sílẹ̀, ẹ máà dá sí ọ̀rọ̀ mi mọ́,’ ẹ̀yin kọ́ ni mọ́mì mi’. Ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an pé irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè jáde lẹ́nu mi. Wọ́n lọ sínú yàrá wọn, wọ́n pa ìlẹ̀kùn dé, mo sì gbọ́ tí wọ́n ń sunkún. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí bà mí nínú jẹ́ gan-an. Ẹni tó ti ń tọ́jú mi láti kékeré, tó ń ṣe gbogbo ohun tí mo fẹ́ fún mi, tí mo sì wá wọ́ ọ nílẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ọkọ wọn bá mi sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ náà, wọ́n sì fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan hàn mí tó sọ pé kéèyàn máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀. Lẹ́yìn náà, mo bẹ ẹ̀gbọ́n mọ́mì mi gan-an pé kí wọ́n forí jì mí. Mo gbà pé àṣìṣe ńlá ni mo ṣe.”Karen.

Lórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí, kọ ìdí kan tó lè mú kó ṣòro fún ẹ láti tọrọ àforíjì.

․․․․․

Kí nìdí tí ara fi lè tù ẹ́ tó o bá tọrọ àforíjì?

․․․․․

Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Wo àwọn ìlànà tó wà ní Òwe 11:2 àti Mátíù 5:23, 24.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ì bá ti dára jù tó o bá yẹra fún ohun tó lè mú kó o ṣi ọ̀rọ̀ sọ, kó má bàa di pé wàá ní láti tọrọ àforíjì. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

BÍ O ṢE LÈ MÁA ṢỌ́ ẸNU RẸ

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó yẹ kó o fi sọ́kàn: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Àwọn àbá kan rèé tó máa jẹ́ kó o lè fi ìmọ̀ràn náà sílò.

Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, kó o wá kọ èyí tó bá ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí mu síwájú rẹ̀.

Òwe 12:16

Òwe 17:14

Òwe 26:20

Oníwàásù 7:9

Fílípì 2:3

1 “Má ṣe jẹ́ kí nǹkan máa ká ẹ lára ju bó ṣe yẹ lọ; nípa bẹ́ẹ̀ o kò ní tètè máa bínú.”—Danette.

2 “Ṣe ni mo máa ń wá ibì kan lọ, kí n lè dá nìkan wà fún ìgbà díẹ̀, èyí á sì mú kí inú tó ń bí mi lọ sílẹ̀.”—Brielle.

3 “Nígbà tí mò ṣì kéré, mó máa ń rò pé ìjà ni èèyàn fi máa ń yanjú gbogbo ọ̀ràn tó bá yọjú, mo sì máa ń sọ ọ̀ràn tí kò tó nǹkan di ńlá. Àmọ́, mo ti wá mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ ló yẹ kéèyàn máa fà.”—Celia.

4 “Tí ẹnì kan bá ń bínú tó sì ń pariwo, àmọ́ tí o kò dá a lóhùn, tó bá yá ó máa sú ẹni náà, á sì dákẹ́ torí pé o kò dá a lóhùn. Ìwọ ṣáà mú sùúrù, má ṣe dá kún ìṣòro náà.”—Kerrin.

5 “Àwọn ìgbà kan wà tó jẹ́ pé tí inú bá ti bí mi sí ẹnì kan, oríṣiríṣi nǹkan ni mo máa ń rò nípa bí màá ṣe sọ̀rọ̀ sí onítọ̀hún. Àmọ́ bí mo bá ṣe sùúrù díẹ̀, mo máa ń rí i pé kò yẹ kí n sọ ohunkóhun. Mo ti wá kẹ́kọ̀ọ́ pé kò yẹ kéèyàn tètè máa bínú.”—Charles.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Allie—Kí n tó sọ ohun kan, mo máa ń bi ara mi láwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé ohun tí mo fẹ́ sọ yìí máa jẹ́ kí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yanjú? Báwo ni ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ sọ ṣe máa rí lára ẹni tí mò ń bá sọ̀rọ̀?’ Tó o bá ti ń ṣiyè méjì nípa bóyá ó yẹ kó o sọ ohun kan tàbí kò yẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé kò yẹ kó o sọ nǹkan ọ̀hún nìyẹn.

Chase—Bí mó bá fẹ́ sọ ohun kan, mo máa ń gbìyànjú láti ronú nípa bó ṣe máa rí lára àwọn tá a jọ ń sọ̀rọ̀. Mo rí i pé bí mo ṣe ń dàgbà sí i ni mò ń mọ bí mo ṣe lè máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Èèyàn máa ń kọ́gbọ́n láti inú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí i.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

O Ò ṢE BI ÀWỌN ÒBÍ RẸ?

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa, gẹ́gẹ́ bí Jákọ́bù ṣe sọ pé, “a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà,” ní kí àwọn òbí ẹ sọ fún ẹ bí wọ́n ṣe ti gbìyànjú tó láti má ṣe sọ̀rọ̀ tí kò yẹ.—Jákọ́bù 3:2.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

“Tó o bá tẹ ọṣẹ ìfọyín jáde, kò ṣeé kó pa dà síbẹ̀ mọ́. Bí ọ̀rọ̀ tí à ń sọ náà ṣe rí nìyẹn. Tá a bá ti sọ̀rọ̀ tó ń gúnni lára sí ẹnì kan, a ò lè kó ọ̀rọ̀ náà pa dà sẹ́nu wa mọ́.”—James.