Kò Sí Ìgbà Téèyàn Dàgbà Jù Láti Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run
Kò Sí Ìgbà Téèyàn Dàgbà Jù Láti Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run
Gẹ́gẹ́ bí Olavi J. Mattila ṣe sọ ọ́
“Ǹjẹ́ o tiẹ̀ rò pé o lè mọ ẹni tí Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ gan-an?” Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló bi mí ní ìbéèrè yẹn, èyí sì mú kí n ronú gan-an. Mo ti tó ọgọ́rin [80] ọdún nígbà yẹn, mo sì ti mọ ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn, títí kan àwọn aṣáájú olóṣèlú. Àmọ́, níbi tí mo bá ìrìn-àjò ayé mi dé yìí, ṣé mo lè mọ Ọlọ́run kí n sì dí ọ̀rẹ́ rẹ̀ lóòótọ́?
OṢÙ October 1918 ni wọ́n bí mi ní ìlú Hyvinkää, ní orílẹ̀-èdè Finland. Láti kékeré ni mo ti máa ń ṣe onírúurú iṣẹ́ lóko. Àwọn òbí mi máa ń sin màlúù, ẹṣin, adìyẹ àti pẹ́pẹ́yẹ. Mo kọ́ béèyàn ṣe máa ń ṣiṣẹ́ kára téèyàn á sì máa fi iṣẹ́ rẹ̀ yangàn.
Bí mo ṣe ń dàgbà, àwọn òbí mi gbà mí níyànjú pé kí ń lọ kàwé sí i. Torí náà, nígbà tí mo parí ilé ìwé girama, mo kúrò nílé kí n lè lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga. Mo tún máa ń ṣeré ìdárayá, mo sì wá di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú alága Àjọ Àwọn Eléré Ìdárayá ti ilẹ̀ Finland, ìyẹn, Urho Kekkonen. Mi ò mọ̀ pé Ọ̀gbẹ́ni Kekkonen ṣì máa wá di olórí ìjọba orílẹ̀-èdè Finland, lẹ́yìn náà ló sì wá di ààrẹ orílẹ̀-èdè Finland, àpapọ̀ iye ọdún tó sì fi wà nípò méjèèjì yìí jẹ́ ọgbọ̀n ọdún. Ohun míì tún ni pé, mi ò tiẹ̀ rò ó rí pé ọkùnrin yìí máa ní ipa lórí ìgbésí ayé mi.
Mo Di Gbajúmọ̀ Mo sì Wà Ní Ipò Àṣẹ
Ní ọdún 1939, ìjà ńlá bẹ́ sílẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè Finland àti orílẹ̀-èdè Soviet Union. Ní oṣù November ọdún náà, wọ́n mú mi wọṣẹ́ ológun. Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n ní kí n máa ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọmọ ogun tó wà ní ìpamọ́, ìyẹn army reserve, nígbà tó sì yá, wọ́n fi mi ṣe aṣáájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun tó ń lo ẹ̀rọ arọ̀jò ọta, ìyẹn machine-gun. Ìlú Karelia tó wà ní ààlà orílẹ̀-èdè Finland àti Soviet Union ni àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì ti dojú ìjà kọ ara wọn. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1941, bá a ṣe ń jagun lọ nítòsí ìlú Vyborg, àfọ́kù bọ́ǹbù ṣe mí léṣe gan-an tó fi jẹ́ pé ṣe ni wọ́n gbé mi lọ sí ilé ìwòsàn àwọn ológun. Ọgbẹ́ tí mo ní yìí ni kò jẹ́ kí n lè pa dà sójú ogun mọ́.
Ní oṣù September ọdún 1944, wọ́n ní kí n fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀, mo sì pa dà sí ilé ẹ̀kọ́ gíga. Bákan náà ni mo sì tún pa da sẹ́nu eré ìdárayá tí mò ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo gbégbá orókè ní orílẹ̀-èdè wa, ẹ̀ẹ̀mejì lẹ́nu eré àságbà àti ẹ̀ẹ̀kan lẹ́nu eré-sáré-fo-igi. Mo tún gboyè jáde ní Yunifásítì lẹ́nu iṣẹ́ ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti ìṣúnná owó.
Ní gbogbo àkókò tí mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí, Urho Kekkonen ti di àràbà lágbo àwọn olóṣèlú. Lọ́dún 1952, lásìkò tó jẹ́ olórí ìjọba, ó ké sí mi pé kí n lọ máa ṣojú fún orílẹ̀-èdè wa lórílẹ̀-èdè Ṣáínà. Nígbà tí mo wà níbẹ̀, mo bá onírúurú aṣojú ìjọba pàdé, títí kan Mao Tse-tung, tó jẹ́ aṣáájú orílẹ̀-èdè Ṣáínà. Ṣùgbọ́n, ẹni tó ṣe pàtàkì jù tí mo pàdé ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà ni ọ̀dọ́bìnrin arẹwà kan tó ń jẹ́ Annikki, tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ilẹ̀ Òkèèrè fún orílẹ̀-èdè Finland. Mo gbé e níyàwó ní November ọdún 1956.
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, wọ́n gbé mi lọ sí ọ́fíìsì tó ń ṣojú orílẹ̀-èdè wa tó wà ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà. Orílẹ̀-èdè yìí la wà tá a fi bí àwọn ọmọkùnrin wa
méjì àkọ́kọ́. Ní January ọdún 1960, a pa dà sí Finland. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà la bí ọmọ wa kẹta, tó jẹ́ obìnrin.Mo Ṣiṣẹ́ Láwọn Ipò Gíga-gíga Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìjọba
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò sí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kankan, nígbà tó di November 1963, Ààrẹ Kekkonen pè mí pé kí n wá di mínísítà tó ń bójú tó ọ̀ràn ìṣòwò pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ òkèèrè. Láàárín ọdún méjìlá tó tẹ̀ lé e, mo ṣiṣẹ́ pẹ̀lú mẹ́fà nínú àwọn ìgbìmọ̀ tó ń bá ààrẹ ṣiṣẹ́, ẹ̀ẹ̀mejì ni mo ṣiṣẹ́ bíi mínísítà ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè. Ní gbogbo ìgbà yẹn, ó dá mi lójú hán-ún hán-ún pé bí àwa èèyàn bá lo ọpọlọ wa, a lè yanjú àwọn ìṣòro tó ń bẹ láyé. Àmọ́, kò pẹ́ rárá tí mo wá mọ̀ pé kò sí ohun tí àwọn èèyàn ò lè ṣe kí agbára lè tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́. Mo fojú ara mi rí àwọn ohun búburú tó máa ń ṣẹlẹ̀ bí àwọn èèyàn kò ṣe fọkàn tán ara wọn tí wọ́n sì ń ṣe ìlara ara wọn.—Oníwàásù 8:9.
Síbẹ̀ náà, mo tún wá mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé tọkàntọkàn ló fi ń wù wọ́n pé kí wọ́n mú nǹkan dẹrùn fáwọn aráàlú. Àmọ́, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn àwọn aṣáájú tó ń wù gan-an pé kí nǹkan dẹrùn fún aráàlú kì í lè ṣe ohun tó wà lọ́kàn wọn.
Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1975, àwọn olórí orílẹ̀-èdè márùndínlógójì [35] wá sí Helsinki fún ìpàdé àpérò ti Àjọ Ààbò àti Àjọṣe Ilẹ̀ Yúróòpù, tí wọ́n pè ní Conference on Security and Cooperation in Europe. Lásìkò yẹn, èmi ni mínísítà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè mo sì tún jẹ́ agbaninímọ̀ràn pàtàkì fún Ààrẹ Kekkonen. Èmi ni wọ́n ní kí n ṣètò bí àpérò náà ṣe máa lọ, èyí sì mú kí n mọ gbogbo àwọn olórí orílẹ̀-èdè tó wá sí àpérò náà.
Láàárín àwọn ọjọ́ mélòó kan yìí, ojú mi rí nǹkan, torí pé gbogbo ọgbọ́n ti mo ní nípa béèyàn ṣe ń ṣètò nǹkan ni mo lò. Láti mú kí àwọn èèyàn tó wá sí àpérò náà gbà láti jókòó níbi tá a ṣètò fún olúkúlùkù wọn dogun! Síbẹ̀, mo gbà pé àpérò náà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìpàdé míì tá a ṣe lẹ́yìn rẹ̀ mú kí àwọn orílẹ̀-èdè alágbára túbọ̀ rí ìdí láti gba ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn láyè, tí àjọṣe àárín wọn sì túbọ̀ sunwọ̀n sí i.
Mo Fẹ́ Láti Sún Mọ́ Ọlọ́run
Lọ́dún 1983, mo fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ mo sì lọ sí orílẹ̀-èdè Faransé níbi tí ọmọ mi obìnrin ń gbé. Àmọ́ láìpẹ́ sígbà yẹn, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó bà mí nínú jẹ́ gan-an. Ní November ọdún 1994, àwọn dókítà rí i pé Anniki ní àrùn jẹjẹrẹ ọmú. Ọdún kan náà yìí ni mo dòwò pọ̀ pẹ̀lú àwọn kan láìmọ̀ pé gbájú ẹ̀ ni wọ́n. Gbogbo ọjọ́ ayé mi ni mo fi ṣiṣẹ́ takuntakun kí n lè ní orúkọ rere. Àmọ́ àṣìṣe kan ṣoṣo tí mo ṣe yìí bà mí lórúkọ jẹ́.
Kò sí ibi tí mo lọ tí mi kì í bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pà dé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọrírì ìbẹ̀wò wọn tí mo sì máa ń gba àwọn ìwé ìròyìn wọn, ọwọ́ mi dí débi pé mi ò ráyè fún àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Ọlọ́run. Àmọ́ nígbà tó fi máa di ọdún 2000, mo kúkú wá dúró nílé kí n lè máa tọ́jú ìyàwó mi tí àrùn jẹjẹrẹ ṣì ń yọ lẹ́nu. Lọ́jọ́
kan nínú oṣù September ọdún 2002, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ mi. Ó bi mí ní ìbéèrè tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Mo wá ronú pé, ‘Ǹjẹ́ èèyàn lè mọ Ọlọ́run lóòótọ́? Ṣé èèyàn sì lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?’ Mo lọ wá Bíbélì mi jáde, ó ti bu tátá, mo sì gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa wá ká lè jọ máa jíròrò déédéé látinú Ìwé Mímọ́.Ní oṣù June ọdún 2004, ìyàwó mi ọ̀wọ́n ṣaláìsí, mo wá dẹni tí kò lẹ́nì kejì. Àmọ́ ṣá, àwọn ọmọ mi tù mí nínú gan-an ni. Síbẹ̀, ó ṣì wù mí láti mọ ipò tí àwọn òkú wà. Mo bi àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Luther méjì nípa rẹ̀, ohun tí wọ́n sọ kò ju pé, “Wò ó, àdììtú lọ̀rọ̀ tó o béèrè yìí.” Ohun tí wọ́n sọ yìí kò tẹ́ mi lọ́rùn. Èyí wá mú kí n rí i pé ó yẹ kí n túbọ̀ ṣèwádìí gan-an nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Bí mo ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tó ti ń wù mí láti mọ̀ túbọ̀ ń yé mi sí i. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì ṣàlàyé pé ikú jẹ́ ipò téèyàn kò ti mọ nǹkan kan, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń sùn, àti pé àwọn tó kú ṣì máa jí dìde tí wọ́n á sì máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 11:25) Àlàyé yìí mú kí n nírètí, ó sì tù mí nínú gan-an.
Kò pẹ́ rárá tí mo fi ka Bíbélì láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó wú mi lórí gan-an ni Míkà 6:8 tó sọ pé, “Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?” Bí àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣe mọ́gbọ́n dání tó sì rọrùn láti lóye fà mí lọ́kàn mọ́ra. Ó tún jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti onídàájọ́ òdodo.
Mo Nírètí Nípa Ọjọ́ Ọ̀la
Bí mo ti ń mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ tí mo ní àti ìgbẹ́kẹ̀lé mi túbọ̀ ń lágbára sí i. Èyí mú kí n túbọ̀ máa sún mọ́ Ẹlẹ́dàá mi! Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 55:11 wú mi lórí gan-an, èyí tó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.” Láìsí àní-àní, Ọlọ́run ti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó sì tún máa mú wọn ṣẹ lọ́jọ́ iwájú. Ó máa ṣe àwọn nǹkan tí àwọn ìjọba èèyàn àti ọ̀pọ̀ àpérò àwọn olóṣèlú ti kùnà láti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 46:9 sọ pé: “Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”
Àǹfààní tí mo ti rí látìgbà tí mo ti ń lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lóǹkà. Ibẹ̀ ni mo ti fojú ara mi rí ojúlówó ìfẹ́ Kristẹni tó jẹ́ àmì téèyàn fi ń dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ mọ̀. (Jòhánù 13:35) Ìfẹ́ yìí lágbára ju ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lọ, kò sì sí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn olóṣèlú tàbí àwọn oníṣòwò ńláńlá.
Àǹfààní Tó Ga Jù Lọ Tí Mo Ní
Mo ti lé ní àádọ́rùn-ún [90] ọdún báyìí, mo sì gbà pé àǹfààní tó ga jù tí mo tíì ní láyé mi ni pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Òtítọ́ nípa Ọlọ́run tí mo ti fẹ́ mọ̀ látọjọ́ yìí ni mo wá mọ̀ wẹ́rẹ́ yìí. Mo ti wá mọ ìdí tá a fi wà láyé àti òtítọ́ nípa Ọlọ́run.
Inú mi tún máa ń dùn pé láìka ti ọjọ́ orí mi sí, mo ṣì ń kópa déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mó ti bá ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn pàdé tí mo sì ti wà láwọn ipò gíga-gíga, kò sí ohunkóhun tó dà bí àǹfààní tí mo ní láti mọ Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, tí mo sì wá di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ gan-an, ó sì wù mí kí n máa yìn ín fún àǹfààní tí mo ní báyìí láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 3:9) Kò sí ìgbà téèyàn dàgbà jù láti di ọ̀rẹ́ Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi àti Ààrẹ Kekkonen àti Ààrẹ Ford ti Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nígbà àpérò Helsinki lọ́dún 1975
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi àti Ààrẹ Kekkonen àti Brezhnev tó jẹ́ olórí orílẹ̀-èdè Soviet Union
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Mo máa ń kópa kíkún nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]
Lápá òsì nísàlẹ̀: Ensio Ilmonen/Lehtikuva; lápá ọ̀tún nísàlẹ̀: Esa Pyysalo/Lehtikuva