Ǹjẹ́ Ìdí Kankan Wà Tí Ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ Fi Tọ̀nà?
Ojú Ìwòye Bíbélì
Ǹjẹ́ Ìdí Kankan Wà Tí Ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ Fi Tọ̀nà?
NÍ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn ò ka àṣà bíbá ẹ̀yà kan náà lòpọ̀ sí ohun tó burú. Àwùjọ kan tó wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé ó yẹ kí wọ́n fi ohun tí wọ́n pè ní “ọgbọ́n ti òde ìwòyí” túmọ̀ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Pásítọ̀ kan ní orílẹ̀-èdè Brazil, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ ọkùnrin kan bíi tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rọ àwọn èèyàn pé kí wọn “tún ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yẹ̀ wò,” kí ó lè dọ́gba pẹ̀lú ojú tí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ fi ń wò ọ̀rọ̀ ìbẹ́yà kan náà lò pọ̀.
Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ńṣe ni àwọn kan máa ń sọ pé ìkórìíra àti ẹ̀tanú ló mú kí àwọn kan má ṣe fara mọ́ èrò àwọn tó ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. Kí lohun tí Bíbélì sọ gan-an nípa ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀?
Kí Ni Bíbélì Sọ?
Bíbélì kò sọ pé ká ní ẹ̀tanú sí ẹnikẹ́ni. Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ nípa bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ ṣe kedere.
“Iwọ kò gbọdọ bá ọkọnrin dápọ bi obirin: irira ni.”—Léfítíkù 18:22, Bibeli Mimọ.
Ohun tí Bíbélì kà léèwọ̀ yìí jẹ́ ọ̀kan lára onírúurú òfin tó ṣàlàyé ìwà tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́, bó ṣe wà nínú Òfin Mósè èyí tí Ọlọ́run dìídì fún àwọn Ísírẹ́lì. Síbẹ̀ náà, òfin náà sọ ojú tí Ọlọ́run fi wo bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, yálà abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ náà jẹ́ Júù tàbí kì í ṣe Júù, nígbà tó sọ pé: “Irira ni.” Àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká má ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan, panṣágà, àtàwọn ìwà míì tí Òfin Mósè kà léèwọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ka àwọn orílẹ̀-èdè náà sí aláìmọ́. (Léfítíkù 18:24, 25) Ǹjẹ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí ti yí padà nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni dé? Gbé ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ yẹ̀ wò:
“Ọlọ́run . . . jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́ fún ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo tí ń dójú tini, nítorí àwọn obìnrin wọn yí ìlò ara wọn lọ́nà ti ẹ̀dá padà sí èyí tí ó lòdì sí ìwà ẹ̀dá; bákan náà, àní àwọn ọkùnrin fi ìlò obìnrin lọ́nà ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọ́n sì di ẹni tí a mú ara wọn gbiná lọ́nà lílenípá nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, àwọn ọkùnrin pẹ̀lú ọkùnrin, ń ṣe ohun ìbàjẹ́.”—Róòmù 1:26, 27.
Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ lòdì sí ìwà ẹ̀dá àti pé ó jẹ́ ohun ìbàjẹ́? Ìdí ni pé kì í ṣe bí Ẹlẹ́dàá ṣe fẹ́ kí àwọn èèyàn máa bá ara wọn lò pọ̀ ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ gbà ń bá ara wọn lò pọ̀. Ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ kò lè mú ọmọ jáde. Bíbélì fi bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ wé ìṣekúṣe tí àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀, tí à ń pè ní àwọn ẹ̀mí Èṣù, wá ṣe pẹ̀lú àwọn obìnrin ṣáájú Ìkún-omi nígbà ayé Nóà. (Jẹ́nẹ́sísì 6:4; 19:4, 5; Júúdà 6, 7) Ohun tó lòdì sí ìwà ẹ̀dà ni Ọlọ́run ka ìwà méjèèjì sí.
Ǹjẹ́ Ìdí Wà Tá A Fi Lè Sọ Pé Ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ Dára?
Àwọn kan lè máa rò pé, ‘Ṣé a lè sọ pé ẹnì kan tó ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ ṣe ohun tó burú tó bá jẹ́ pé ó ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ ẹni náà, bóyá nítorí ibi tí wọ́n bí i sí tàbí torí àwọn ìrírí tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni tó ti ní, irú bíi kí wọ́n ti bá ẹni náà ṣèṣekúṣe nígbà tó wà lọ́mọdé?’ Àwọn nǹkan yìí kì í ṣe ìdí téèyàn fi gbọ́dọ̀ máa bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀. Wo àpẹẹrẹ yìí ná: Ẹnì kan lè jẹ́ ọ̀mùtí látàrí ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kà sí àjogúnbá, tó ti wà nínú ẹ̀jẹ̀, tàbí nítorí pé ìdílé tí wọ́n ti ń mu ọtí ní ìmukúmu ní wọ́n ti tọ́ ẹni náà dàgbà. Kò sí àní-àní, ọ̀pọ̀ èèyàn ni yóò káàánú ẹni tó bá wà ní irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀. Bó ti wù kó rí, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ńṣe ni àwọn èèyàn á máa gba ẹni náà níyànjú pé kí ó máa bá ìmukúmu rẹ̀ lọ tàbí kó má wulẹ̀ janpata àtidá ìmukúmu rẹ̀ dúró kìkì nítorí pé ọtí mímu ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ ìdílé
wọn tàbí torí pé ìdílé tí wọ́n ti ń mutí ni wọ́n bí i sí.Lọ́nà kan náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kò kórìíra àwọn tí ọkàn wọn máa ń fà sí bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, kò sì ìgbà kan tó fojú tó dára wo àwọn tó ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, yálà wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé àṣà náà jẹ́ ohun tí wọ́n bí mọ́ wọn tàbí nǹkan míì ló fà á tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. (Róòmù 7:21-25; 1 Kọ́ríńtì 9:27) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ràn tó ṣeé múlò àti ìṣírí ni Bíbélì fun irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, èyí táá jẹ́ kí wọ́n lè borí àṣà bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀.
Kí Ni Ọlọ́run Fẹ́ Kí Àwọn Tí Ọkàn Wọn Máa Ń Fà sí Ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ Ṣe?
Bíbélì fi dá wa lójú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì dẹ́bi fún bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, kò sọ pé ká kórìíra àwọn tó ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀.
A kò lè fojú yẹpẹrẹ wo ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere nínú 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10 pé, “àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀” wà lára àwọn “tí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.” Àmọ́ ní ẹsẹ kọkànlá a rí ọ̀rọ̀ ìtùnú yìí kà pé: “Síbẹ̀, ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.”
Ó ṣe kedere pé àwọn tó fẹ́ láti sin Ọlọ́run tọkàntọkàn bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ni a gbà tọwọ́tẹsẹ̀ sínú ìjọ Kristẹni ìgbàanì. Lóde òní pẹ̀lú, tọwọ́tẹsẹ̀ ni a máa ń gba àwọn tó mọyì òtítọ́, tí wọ́n ń wá ojú rere Ọlọ́run, tí wọn kò wá bí wọ́n ṣe máa túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ́nà òdì, àmọ́ tí wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn níbàámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú Bíbélì.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Kí ni Bíbélì sọ nípa bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀?—Róòmù 1:26, 27.
● Ǹjẹ́ Bíbélì sọ pé kí á kórìíra àwọn tó ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀? —1 Tímótì 2:4.
● Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kéèyàn jáwọ́ nínú bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀?—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ṣé ó yẹ kí àwọn èèyàn túmọ̀ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ lọ́nà tí wọ́n fẹ́?