Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kó O Gbẹ̀mí Ara Rẹ

Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kó O Gbẹ̀mí Ara Rẹ

Tó Bá Ń Ṣe Ẹ́ Bíi Pé Kó O Gbẹ̀mí Ara Rẹ

LỌ́DỌỌDÚN, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ló ń gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn. Bíbélì sọ ohun tó fà á tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi sọ ìrètí nù. Ó sọ pé àwọn “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé, èyí sì ń mú kí nǹkan túbọ̀ nira fún àwọn èèyàn. (2 Tímótì 3:1; Oníwàásù 7:7) Bí àníyàn ìgbésí ayé bá sì ti bo èèyàn mọ́lẹ̀, èèyàn lè máa ronú àtigba ẹ̀mí ara rẹ̀, torí pé ó gbà pé ìyẹn á mú kí òun bọ́ lọ́wọ́ ìnira. Kí lo lè ṣe tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kí o gbẹ̀mí ara rẹ?

Gbogbo Èèyàn Ló Ní Ìṣòro!

Tó bá dà bí ẹni pé ọ̀rọ̀ ara rẹ ti sú ẹ, tó sì dà bíi pé kò sí ọ̀nà àbáyọ, rántí pé gbogbo èèyàn ló ní ìṣòro kan tàbí òmíràn tí wọ́n ń bá yí. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀.” (Róòmù 8:22) Ní báyìí, ó lè dà bíi pé kò sí ojútùú rárá sí ìṣòro tó o ní, àmọ́ bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́ àwọn nǹkan sábà máa ń lójú. Ṣùgbọ́n, kí lo lè ṣe ní báyìí ná?

Sọ ìṣòro rẹ fún ọ̀rẹ́ rẹ kan tó ní ìwà àgbà tó o sì fọkàn tán. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” (Òwe 17:17) Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin olódodo náà Jóòbù, pé ó sọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ fún àwọn kan nígbà tó wà nínú wàhálà. Nígbà tí ìṣòro náà pọ̀ débi tó fi sọ pé òun ‘kórìíra ìgbésí ayé òun tẹ̀gbintẹ̀gbin,’ ó ní: “Èmi yóò tú ìdàníyàn nípa ara mi jáde. Èmi yóò sọ̀rọ̀ nínú ìkorò ọkàn mi!” (Jóòbù 10:1) Ẹ̀dùn ọkàn rẹ máa dín kù tó o bá rí ẹnì kan fọ̀ràn lọ̀, ìyẹn sì lè mú kí ìṣòro náà má ṣe dà bí nǹkan ńlá lójú rẹ mọ́.

Sọ ìṣòro rẹ fún Ọlọ́run. Èrò àwọn kan ni pé àdúrà jẹ́ ohun tí èèyàn kàn lè fi rẹ ara rẹ̀ tẹ́ nígbà ìṣòro, ṣùgbọ́n Bíbélì sọ ohun tó yàtọ̀ sí ìyẹn. Sáàmù 65:2 pe Jèhófà Ọlọ́run ní “Olùgbọ́ àdúrà,” 1 Pétérù 5:7 sì sọ pé: “Ó bìkítà fún yín.” Léraléra ni Bíbélì sọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ:

“Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”ÒWE 3:5, 6.

“Ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù [Jèhófà] ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là.”SÁÀMÙ 145:19.

“Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.”1 JÒHÁNÙ 5:14.

“Jèhófà jìnnà réré sí àwọn ẹni burúkú, ṣùgbọ́n àdúrà àwọn olódodo ni ó máa ń gbọ́.”ÒWE 15:29.

Tó o bá sọ ìṣòro rẹ fún Ọlọ́run, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá níyànjú pé: “Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé e ní gbogbo ìgbà. Ẹ tú ọkàn-àyà yín jáde níwájú rẹ̀.”—Sáàmù 62:8.

Ohun Tó O Tún Lè Ṣe

Ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbẹ̀mí ara wọn ló jẹ́ pé wọ́n ti ní ìsoríkọ́ látọjọ́ pípẹ́. a Èyí fi hàn pé ó lè pọn dandan pé kí àwọn tó bá ń ronú àtigbẹ̀mí ara wọn lọ rí dókítà. Dókítà kan lè kọ àwọn oògùn tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ á máa lò tàbí àwọn oúnjẹ tí wọ́n á máa jẹ tàbí èyí tí wọ́n á yẹra fún. Ó sì lè gba pé kí wọ́n máa ṣe àwọn eré ìmárale kan láfikún sí àwọn ohun tí wọ́n ń lò. Ọ̀pọ̀ ló ti rí ìtọ́jú gbà lọ́dọ̀ àwọn dókítà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́. b

Àwọn ìsọfúnni lóríṣiríṣi wà nínú Bíbélì tó lè fún ọ lókun, tó sì máa mú kó o ní ìrètí. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé Ìṣípayá 21:4, Bíbélì sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé: “Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ọlọ́run ló ṣe ìlérí yìí, bó o bá sì ń ronú nípa rẹ̀, ó lè mú kí ara tù ẹ́.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tó wà nínú Bíbélì yìí fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn kárí ayé. Èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ ní ojúlówó ìrètí ní àwọn àkókò tó kún fún ìyọnu yìí. Tó o bá ń fẹ́ àlàyé síwájú sí i, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ, o lè lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn tàbí kó o kọ̀wé sí èyí tó bá yẹ lára àwọn àdírẹ́sì tó wà lójú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí. O tún lè lọ sórí ìkànnì wa, www.watchtower.org.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ àlàyé sí i nípa ìsoríkọ́, wo Jí! November 8, 2000 ojú ìwé 16 sí 18 àti Jí! July 2009 lédè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 3 sí 9.

b Ìwé ìròyìn Jí! kò sọ pé irú ìtọ́jú kan pàtó ló dára jù. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló yẹ kó fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò oríṣiríṣi ìtọ́jú tó wà, kí ó sì ṣe ìpinnu tó wù ú.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]

BÍBÉLÌ LÈ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

● “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:6, 7.

● “Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn, Ó sì dá mi nídè nínú gbogbo jìnnìjìnnì mi.”—Sáàmù 34:4.

● “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18.

● “Ó ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.”—Sáàmù 147:3.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]

TÓ BÁ Ń ṢE Ẹ́ BÍI PÉ KÓ O GBẸ̀MÍ ARA RẸ . . .

Sọ ìṣòro rẹ fún ọ̀rẹ́ rẹ kan tó o fọkàn tán

Sọ ìṣòro rẹ fún Ọlọ́run

Lọ gba ìtọ́jú ìṣègùn

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

ÌMỌ̀RÀN FÚN TẸBÍ TỌ̀RẸ́

Ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ ẹnì kan ló máa tètè mọ̀ pé ẹni náà ń ronú láti gbẹ̀mí ara rẹ̀. Tẹ́ ẹ bá tètè wá nǹkan ṣe sí i, ẹ lè gba ẹ̀mí ẹni náà là! Ẹ fetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀, kí ẹ sì máa fọ̀rọ̀ ro ara yín wò. Ẹ gbà pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ eré ni ìṣòro tí onítọ̀hún ní. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Ẹ gba ẹni tó ní ìsoríkọ́ níyànjú pé kó lọ rí dókítà, kẹ́ ẹ sì rí i pé ó ṣe bẹ́ẹ̀.