Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọ̀rẹ́ Lásán La Jẹ́ Àbí Ọ̀rọ̀ Ìfẹ́ Ti Ń Wọ̀ ọ́? APÁ 1

Ṣé Ọ̀rẹ́ Lásán La Jẹ́ Àbí Ọ̀rọ̀ Ìfẹ́ Ti Ń Wọ̀ ọ́? APÁ 1

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Ṣé Ọ̀rẹ́ Lásán La Jẹ́ Àbí Ọ̀rọ̀ Ìfẹ́ Ti Ń Wọ̀ ọ́? APÁ 1

ǸJẸ́ ỌKÀN RẸ LỌ SỌ́DỌ̀ ẸNÌ KAN NÍGBÀ TÓ O KA ÀKÒRÍ TÓ WÀ LÓKÈ YÌÍ?

BẸ́Ẹ̀ NI BẸ́Ẹ̀ KỌ́

TÈTÈ KA ÀPILẸ̀KỌ YÌÍ. ṢÁÀ WÁ ÀYÈ LÁTI KA

Ó LÈ ṢE Ẹ́ LÁǸFÀÀNÍ ÀPILẸ̀KỌ YÌÍ. WÀÁ LÈ YẸRA FÚN

JU BÓ O ṢE RÒ LỌ. OHUN TÓ LÈ MÚ ÌFURA DÁNÍ

LÁÀÁRÍN ÌWỌ ÀTI Ẹ̀YÀ ÒDÌKEJÌ,

O Ò SÌ NÍ KÓ SÍNÚ ÌṢÒRO.

Fi àmì sí bẹ́ẹ̀ ni tàbí rárá nínú àwọn gbólóhùn tó wà nísàlẹ̀ yìí:

Kò yẹ kí n ní ẹ̀yà òdìkejì lọ́rẹ̀ẹ́ títí dìgbà tí mo bá ṣe tán láti ṣègbéyàwó.

․․․․․ BẸ́Ẹ̀ NI ․․․․․ RÁRÁ

Àpẹẹrẹ kan rèé: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ní àwọn ọ̀rẹ́ obìnrin, kò ní in lọ́kàn láti fẹ́ èyíkéyìí lára wọn níyàwó. (Mátíù 12:46-50; Lúùkù 8:1-3) Ó ṣe kedere pé bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú Tímótì tó jẹ́ àpọ́n, torí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé kí ó hùwà sí “àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.”—1 Tímótì 5:1, 2.

Pọ́ọ̀lù ti ní láti ronú pé bí Tímótì ṣe ń sìn láti ìjọ kan sí òmíràn, yóò máa bá àwọn ọ̀dọ́bìnrin pàdé lóríṣiríṣi. (Máàkù 10:29, 30) Ṣé ó burú tí Tímótì bá ń bá wọn ṣọ̀rẹ́ ni? Rárá. Àmọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kì í ṣe pé Tímótì ń wá ẹni tó máa fẹ́ lákòókò yẹn, ó ní láti ṣọ́ra kó má lọ di pé ọkàn rẹ̀ á bẹ̀rẹ̀ sí fà sí àwọn ọ̀dọ́bìnrin náà, ó sì dájú pé kò ní máa bá wọn tage tàbí kí ó kàn máa fa ojú wọn mọ́ra lásán.—Lúùkù 6:31.

Ìwọ ńkọ́? Ṣé o ti ṣe tán láti ṣègbéyàwó?

Tó bá jẹ́ BẸ́Ẹ̀ NI ⇨ Bó o ṣe ń ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà òdìkejì, o lè tipa bẹ́ẹ̀ rí ẹni tí wàá fẹ́.—Òwe 18:22; 31:10.

Tó bá jẹ́ BẸ́Ẹ̀ KỌ́ ⇨ Wọléwọ̀de rẹ pẹ̀lú wọn gbọ́dọ̀ mọ níwọ̀n. (Jeremáyà 17:9) Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ yìí dùn sọ, àmọ́ kò rọrùn! Ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìdínlógún [18] tó ń jẹ́ Nia sọ pé: “Kò rọrùn rárá kéèyàn fi mọ sí ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ lásán. a Kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti mọ ibi tó yẹ kí irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ mọ.”

Kí nìdí tó tiẹ̀ fi yẹ kí wọléwọ̀de náà mọ níwọ̀n? Ìdí ni pé tí o kò bá ṣọ́ra, wàá ṣèpalára fún ara ẹ tàbí kó o pa ẹlòmíì lára. Wo ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀.

ÒÓTỌ́ Ọ̀RỌ̀: Tó bá di pé ọkàn ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹnì kan tó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí onítọ̀hún, láìjẹ́ pé o ti ṣe tán láti fẹ́ ẹ, ó lè yọrí sí ẹ̀dùn ọkàn fún ọ̀kan nínú yín. Ọmọbìnrin ọlọ́dún mọ́kàndínlógún [19], tó ń jẹ Kelli sọ pé: “Ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí mi. Nígbà àkọ́kọ́, ńṣe ni ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ọmọkùnrin kan, àti nígbà kejì, ọmọkùnrin kan ni ọkàn rẹ̀ ń fà sí mi. Nígbà méjèèjì, ọ̀rọ̀ náà yọrí sí ẹ̀dùn ọkàn fún ọ̀kan nínú wa, ó sì dá ọgbẹ́ sí mi lọ́kàn títí dòní olónìí.”

Ohun tó yẹ kó o ronú lé:

Àwọn ipò wo ló ti lè bọ́gbọ́n mu pé kó o máa ṣọ̀rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀yà òdìkejì? Àwọn ipò wo ló yẹ kó o yẹra fún?

Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé kí ìwọ àti ẹnì kan náà tó jẹ́ ẹ̀yà òdìkejì máa wà pa pọ̀ ṣáá? Kí ni ẹnì kejì lè máa rò? Kí ni ìwọ alára lè máa rò?

“Nígbà míì, mo máa ń tan ara mi jẹ pé, ‘Kò sí nǹkan kan, ọ̀rẹ́ lásán ni wá. Ńṣe ni mo mú un bí ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin.’ Àmọ́ nígbà tí mo bá rí i tó ń bá ọmọbìnrin míì ṣeré, ó máa ń dùn mí gan-an, ó máa ń ṣe mí bíi pé èmi nìkan lo yẹ kó máa bá ṣeré.”—Denise.

Bíbélì sọ pé: “Ọlọgbọn eniyan ti ri ibi tẹlẹ̀, ó si pa ara rẹ̀ mọ: ṣugbọn awọn òpè tẹ̀ siwaju, a si jẹ wọn níyà.”—Òwe 22:3, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

ÒÓTỌ́ Ọ̀RỌ̀: Tó bá di pé ọkàn ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹnì kan tó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí onítọ̀hún, láìjẹ́ pé o ti ṣe tán láti fẹ́ ẹ, okùn ọ̀rẹ́ yín kò ní pẹ́ já. Ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́rìndínlógún [16] tó ń jẹ́ Kati sọ pé: “Nígbà kan, èmi àti ọmọkùnrin kan máa ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra wa lórí fóònù, àmọ́ kò pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ sí í fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí mi, tó fi jẹ́ pé bóyá ni ọjọ́ kan lè lọ ká má fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ara wa lórí fóònù. Lọ́jọ́ kan, ó wá sọ fún mi pé òun fẹ́ràn mi gan-an, àti pé ó wu òun pé ká jọ máa fẹ́ra wa. Ìṣòro náà ni pé, kì í ṣe ẹni tí mo lè fẹ́ rárá. Lẹ́yìn tí mo sọ fún un, kò bá mi sọ̀rọ̀ mọ́, ibẹ̀ sì ni ọ̀rẹ́ wa parí sí.”

Ohun tó yẹ kó o ronú lé:

Nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kati yìí, ta ni ọ̀rọ̀ náà ṣèpalára fún, kí sì nìdí? Ǹjẹ́ ohun kan wà tí Kati tàbí ọmọkùnrin náà ì bá ti ṣe tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò fi ní ṣẹlẹ̀? Tó bá wà, kí ni wọn ì bá ti ṣe?

Téèyàn bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù, àwọn ọ̀rọ̀ wo lèèyàn lè máa kọ tó fi jẹ́ pé láìmọ̀ọ́mọ̀, ọ̀rọ̀ náà á ti fẹ́ máa kọjá ti ọ̀rẹ́ lásán?

“Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo ní láti ṣọ́ra gan-an, bí mo bá kíyè sí pé mo ti ń kọjá àyè lọ́dọ̀ àwọn ọmọkùnrin. Mo máa ń gbádùn àwọn ọ̀rẹ́ ọkùnrin gan-an, àmọ́ mi ò fẹ́ kí àṣejù wọ ọ̀rọ̀ wa kí ọ̀rẹ́ wa má bàa bà jẹ́.”—Laura.

Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.

Kókó pàtàkì: Kì í ṣe ohun tó burú tó o bá ní àwọn ẹ̀yà òdìkejì lọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́ tó o bá ti mọ̀ pé o ò ṣe tán láti yan ẹni tó o máa fẹ́, yáa jẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín yín mọ níwọ̀n.

NÍNÚ “ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ . . . ” TÓ TẸ̀ LÉ E

O lè ba ara ẹ lórúkọ jẹ́ tó bá di pé ọkàn ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹnì kan tó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí onítọ̀hún, láìjẹ́ pé o ti ṣe tán láti fẹ́ ẹ. Báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

KÍ NI ÌWỌ MÁA ṢE?

OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ ẸNÌ KAN: “Mo kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù sí ọ̀rẹ́ mi ọkùnrin kan tó ń gbé ní ohun tó ju ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] kìlómítà sílé wa. A máa ń kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ara wa bóyá lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Mi ò ní in lọ́kàn pé a máa fẹ́ra wa, mi ò sì rò pé òun náà ní nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́kàn. Ó wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan pé ó kọ ọ̀rọ̀ kan ránṣẹ́ sí mi, ọ̀rọ̀ náà kà pé: ‘Olólùfẹ́ mi, báwo ni? Ọkàn mi ń fà sí ẹ gan-an. Kí ló ń ṣẹlẹ̀, ṣó o wà pa?’ Ẹnu yà mí gan-an! Mo wá sọ fún un pé ọ̀rẹ́ lásán ni èmi gbà pé a jẹ́ àti pé mi ò rò ó rárá pé ọ̀rọ̀ ìfẹ́ máa wọnú ẹ̀. Ó wá kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ pa dà pé, ‘ìwọ lo mọ̀.’ Látìgbà yẹn, kò tún kọ ọ̀rọ̀ sí mi mọ́.”—Janette.

● Tó bá jẹ́ pé ìwọ alára náà mọ̀ pé kò yẹ kó o fẹ́ ẹnì kan, tàbí pé kò tiẹ̀ tíì sí lọ́kàn ẹ rárá láti bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan, kí lo máa kọ pa dà ká sọ pé ìwọ ni Janette tí ẹni kan kọ irú ọ̀rọ̀ yìí sí?

● Tó bá jẹ pé ọkùnrin ni ẹ́, ǹjẹ́ o rò pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ ránṣẹ́ sí Janette yìí bójú mu? Tó bá bójú mu, kí nìdí? Tí kò bá bójú mu, kí nìdí?

● Lójú tiẹ̀, nínú fífi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù àti bíbá ẹnì kan sọ̀rọ̀ lójúkojú, èwo lo rò pé ó máa mú kí ọkàn ẹnì kan máa fà sí ẹ̀yà òdìkejì jù? Sọ èrò rẹ àti ìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?

Béèrè àwọn ìbéèrè tó ní àmì róbótó dúdú níwájú, tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ, kí wọ́n sì sọ èrò wọn fún ẹ. Ṣé ohun tí wọ́n sọ yàtọ̀ sí èrò tìẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni ìyàtọ̀? Àǹfààní wo lo rí nínú ohun tí wọ́n sọ?—Òwe 11:14.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

Joshua—Bó o bá ń  lo àkókò pẹ̀lú ẹnì kan náà ṣáá, ńṣe ni ọkàn rẹ á túbọ̀ máa fà sí ẹni náà.

Natasha—Tó bá jẹ́ pé ohun tó o fẹ́ kó wà láàárín ìwọ àti ẹ̀yà òdìkejì kò ju ọ̀rẹ́ lásán lọ, àmọ́ tó jẹ́ pé ẹ̀yin méjèèjì lẹ jọ máa ń wà pa pọ̀ ṣáá nígbà gbogbo, bópẹ́ bóyá ọkàn ẹnì kan nínú yín á bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí èkejì tàbí kí ọkàn ẹ̀yín méjèèjì máa fà sí ara yín.

Kelsey—Ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rẹ́ lásán lẹ jẹ́ látìbẹ̀rẹ̀, ó rọrùn gan-an pé kí ọkàn yín bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ara yín tẹ́ ẹ bá ń wà pa pọ̀ ṣáá. Ọkùnrin àti obìnrin lè jẹ́ ọ̀rẹ́ lásán, àmọ́ ó gba pé kí wọ́n ní ìwà àgbà, kí wọ́n sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

O lè kó ara rẹ sí wàhálà tó bá di pé ọkàn ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹnì kan tó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sí onítọ̀hún, láìjẹ́ pé o ti ṣe tán láti fẹ́ ẹ