Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Oúnjẹ Rẹ Kò Léwu?

Ṣé Oúnjẹ Rẹ Kò Léwu?

Ṣé Oúnjẹ Rẹ Kò Léwu?

“Wọ́n ti ilé ìwé kan pa ní orílẹ̀-èdè Jámánì látàrí bí àwọn ọmọ iléèwé mélòó kan ṣe kó àrùn tí kòkòrò E. Coli máa ń fà.”—REUTERS NEWS SERVICE, Orílẹ̀-èdè JÁMÁNÌ.

“Ìwádìí Fi Hàn Pé Irú Àwọn Ẹ̀wà Kan Ń Fa Kòkòrò Àrùn Tí Wọ́n Ń Pè Ní Samonella Láwọn Ìpínlẹ̀ Márùn-ún.”—Ìwé Ìròyìn USA TODAY.

“Wọ́n Kó Ẹran Màlúù tí Wọ́n Ti Fi Oògùn Olóró Bọ́ Yó Wọ Ìpínlẹ̀ Mẹ́sàn-án.”—Ìwé Ìròyìn THE MAINICHI DAILY NEWS, Orílẹ̀-èdè JAPAN.

LỌ́DÚN tó kọjá, àárín ọ̀sẹ̀ méjì péré ni àwọn ohun tó jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn yìí ṣẹlẹ̀. Ìwádìí fi hàn pé lọ́dọọdún ní àwọn ìlú tó ti gòkè àgbà, àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ló ń kó àìsàn látinú oúnjẹ.

Báwo ni àwọn ìròyìn yìí ṣe rí lára rẹ? Bàbá kan nílẹ̀ Hong Kong, tó ń jẹ́ Hoi, sọ pé “Ẹ̀rù ń bà mí, inú sì ń bí mi pẹ̀lú. Ọmọ méjì ni mo ní, mo máa ń ronú gan-an nípa bí wọ́n ṣe ń se oúnjẹ tí àwọn ọmọ náà ń jẹ àti ibi tí wọ́n ti ń sè é.”

Láwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò ti rí já jẹ, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún látàrí àìsàn tí wọ́n ń kó látinú oúnjẹ àti omi, àwọn ọmọdé ló sì pọ̀ jù lára wọn. Obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bọ́lá, tó ń gbé ní Nàìjíríà sọ pé: “Láwọn ọjà wa níbí, ìta gbangba làwọn oúnjẹ máa ń wà, tí àwọn eṣinṣin á máa kùn yùnmù lórí wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni òjò máa ń pa wọ́n, eruku á bò wọ́n, tí wọ́n á sì ṣí wọn kalẹ̀ sí atẹ́gùn. Tí mo bá ka ìròyìn nípa àìsàn téèyàn ń kó látinú oúnjẹ tàbí tí mo gbọ́ nípa rẹ̀, ṣe ni ẹ̀rù máa ń bà mí. Mo máa ń ronú nípa bí mo ṣe lè dáàbò bo ìdílé mi.”

Ǹjẹ́ èèyàn lè dáàbò bo ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ oúnjẹ tó lè fẹ̀mí ẹni wewu? Àjọ tó ń rí sí àyẹ̀wò oúnjẹ lórílẹ̀-èdè Kánádà, ìyẹn Canadian Food Inspection Agency, sọ pé: “Nígbàkigbà tí àwọn ilé ìtajà bá ta àwọn oúnjẹ tó lè ṣàkóbá fún ìlera, gbogbo ayé ló máa ń gbọ́. Ìyẹn sì dáa bẹ́ẹ̀. Àmọ́, tí a kò bá ṣe àwọn nǹkan tó yẹ ká ṣe láwọn ilé ìdáná tiwa alára, àwọn oúnjẹ wa lè dèyí tó léwu, a sì lè tipa bẹ́ẹ̀ kó àìsàn.”

Kí lo lè ṣe tí ìdílé rẹ kò fi ní kó àìsàn látinú oúnjẹ? A máa jíròrò ọ̀nà mẹ́rin tó o lè gbà dáàbò bo oúnjẹ rẹ.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

ÀWỌN WO LỌ̀RỌ̀ YÌÍ KÀN?

Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n lè tètè kó àìsàn látinú oúnjẹ, lára wọn ni:

● Àwọn ọmọdé tí kò tíì tó ọmọ ọdún márùn-ún

● Àwọn aláboyún

● Àwọn tó ti lé ní àádọ́rin [70] ọdún

● Àwọn tí èròjà tó ń gbógun ti àrùn nínú ara wọn kò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́

Tí ìwọ tàbí ẹni tẹ́ ẹ jọ fẹ́ jẹun bá wà lára àwọn tá a tò sókè yìí, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó o kíyè sára nígbà tó o bá ń gbọ́únjẹ, nígbà tó o bá ń bù ú sáwo àti nígbà tó o bá ń jẹ ẹ́.

[Credit Line]

Ibi tá a ti rí ìsọfúnni: New South Wales Food Authority, orílẹ̀-èdè Ọsirélíà.