Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

1. Ṣọ́ Ohun Tó O Máa Rà

1. Ṣọ́ Ohun Tó O Máa Rà

1. Ṣọ́ Ohun Tó O Máa Rà

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o ní láti dé ọjà tó o bá fẹ́ ra àwọn nǹkan tó o máa ń jẹ, àyàfi tó bá jẹ́ pé ìwọ fúnra rẹ lò ń ṣọ̀gbìn oúnjẹ rẹ. Tó o bá lọ sọ́jà, báwo lo ṣe lè mọ oúnjẹ tó ń ṣara lóore, kó o sì mọ bí wàá ṣe rà á?

Mọ ìgbà tó yẹ kó o ra àwọn nǹkan.

Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìtọ́jú oúnjẹ lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, ìyẹn Food Safety Information Council, sọ pé: “Àwọn oúnjẹ tí kò lè tètè bà jẹ́ ni kó o kọ́kọ́ rà. Lẹ́yìn tó o bá ti ra gbogbo nǹkan tó o fẹ́ rà tán ni kó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ra àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń kó sínú ẹ̀rọ amú-ǹkan-tutù [fìríìjì] àti ẹ̀rọ amú-ǹkan-dì.” Bákan náà, tó bá kù díẹ̀ kó o máa lọ sílé ni kó o tó lọ ra àwọn oúnjẹ gbígbóná.

Má ṣe ra àwọn oúnjẹ tó ti pẹ́ lórí igbá.

Tó bá ṣeé ṣe, gbìyànjú láti máa ra àwọn èlò oúnjẹ tí kò tíì pẹ́ lórí igbá. a Ruth, ìyá ọlọ́mọ méjì, tó ń gbé ní Nàìjíríà sọ pé: “Àárọ̀ kùtù ni mo sábà máa ń lọ sí ọjà, kí n lè rí nǹkan rà nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kó wọn dé.” Inú ọjà gangan ni Elizabeth tó ń gbé ní Mẹ́síkò náà ti máa ń ra àwọn nǹkan tó nílò, ó sọ pé: “Mo máa ń ra àwọn èso àti ewébẹ̀ tó tutù yọ̀yọ̀ níbẹ̀, fúnra mi ni mo sì máa ń ṣa èyí tí mo fẹ́. Ẹran òòjọ́ ni mo máa ń rà. Tí mo bá ti mú èyí tí màá lò, mo máa ń kó èyí tó kù sínú ẹ̀rọ amú-ǹkan-dì.”

Yẹ oúnjẹ tó o fẹ́ rà wò dáadáa.

Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé àwọ̀ ara ohun tí mo fẹ́ rà yìí ṣì jọ̀lọ̀? Ṣé ẹran yìí kò máa rùn?’ Tó bá jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fi nǹkan wé ohun tó o fẹ́ rà, tàbí pé ó wà nínú nǹkan, yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa. Àwọn kòkòrò tó lè pani lára lè wọnú oúnjẹ náà bí ohun tí wọ́n fi wé e tàbí tí wọ́n kó oúnjẹ náà sí bá ti ní ihò.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Chung Fai, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Hong Kong, tó máa ń ra èlò oúnjẹ nílé ìtajà ńlá sọ pé: “Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o wo déètì tí oúnjẹ náà máa bà jẹ́ lára agolo, bébà tàbí ọ̀rá náà.” Kí nìdí? Àwọn ọ̀mọ̀ràn kìlọ̀ pé kódà bí oúnjẹ kan tí déètì tó wà lára rẹ̀ fi hàn pé ó ti bà jẹ́ bá tiẹ̀ dára lójú, tí òórùn rẹ̀ fani mọ́ra, tó sì dùn lẹ́nu, ó ṣì lè fa àìsàn.

To àwọn ẹrù náà dáadáa.

Tó o bá ní báàgì kan tó máa ń gbé lọ sọ́jà, máa fi omi gbígbóná àti ọṣẹ fọ̀ ọ́ déédéé. Báàgì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni kó o máa kó ẹran àti ẹja sí, kí wọ́n má bàa ba àwọn oúnjẹ míì jẹ́.

Ọjà tí kò jìnnà sílé wọn ni tọkọtaya kan ní orílẹ̀-èdè Ítálì, ìyẹn Enrico àti Loredana ti máa ń rajà. Wọ́n sọ pé: “Bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, kò sídìí pé à ń rìn jìnnà jù ká tó délé, torí bẹ́ẹ̀, ohun tá a rà kò ní bà jẹ́.” Tó bá máa gbà ẹ́ tó ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú kó o tó délé, yáa fi nǹkan wé ohun tí wọ́n mú jáde fún ẹ látinú ẹ̀rọ amú-nǹkan-dì, débi pé yìnyín ara rẹ̀ kò ní tíì yọ́ tán kó o tó délé.

Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, wàá mọ ohun tó o lè ṣe kí oúnjẹ rẹ má bàa ṣàkóbá fún ẹ lẹ́yìn tó o bá délé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà: “Ohun 1—Máa Ṣọ́ Oúnjẹ Jẹ,” tó wà nínú Jí! April–June 2011

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ: “Mo kọ́ àwọn ọmọ mi pé kí wọ́n tó ra oúnjẹ bí ìpápánu, tó wà nínú agolo, ike, bébà, tàbí ọ̀rá, kí wọ́n máa yẹ ara oúnjẹ náà wò kí wọ́n lè mọ déètì tó máa bà jẹ́.”—Ruth, Nàìjíríà