Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

3. Fara Balẹ̀ Gbọ́únjẹ Kó O Sì Tọ́jú Rẹ̀ Dáadáa

3. Fara Balẹ̀ Gbọ́únjẹ Kó O Sì Tọ́jú Rẹ̀ Dáadáa

3. Fara Balẹ̀ Gbọ́únjẹ Kó O Sì Tọ́jú Rẹ̀ Dáadáa

NÍ ÍSÍRẸ́LÌ àtijọ́, ọkùnrin kan kò bìkítà nípa irú oúnjẹ tó fẹ́ sè, ó kó tàgíìrì jọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé “kò mọ ohun tí ó jẹ́.” Ó da ohun tí kò mọ̀ yìí sínú ọbẹ̀ tó ń sè. Ẹ̀rù ba àwọn tó fẹ́ jẹun, torí ńṣe ni wọ́n rí oúnjẹ náà bíi pé májèlé wà nínú rẹ̀, wọ́n sì figbe ta pé: “Ikú ń bẹ nínú ìkòkò náà.”—2 Àwọn Ọba 4:38-41.

Àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí i pé, tí ẹnì kan kò bá bìkítà nípa oúnjẹ tó ń sè, kò yẹ kéèyàn jẹ irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ lè ṣeni léṣe tàbí kí ó gbẹ̀mí ẹni. Torí náà, tí o kò bá fẹ́ kó àìsàn látinú oúnjẹ, ó dára kó o mọ bó o ṣe lè fara balẹ̀ se oúnjẹ àti bó o ṣe lè tọ́jú oúnjẹ dáadáa. Wo àwọn àbá mẹ́rin yìí ná:

Bó o ṣe lè mú kí yìnyín ara ẹran yòrò.

“Ẹ̀ka tó ń bójú tó iṣẹ́ àgbẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn, U.S. Department of Agriculture sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹran tí wọ́n mú jáde látinú ẹ̀rọ amú-nǹkan-dì lè ti yòrò lórí àtẹ, inú rẹ̀ lọ́hùn-ún ṣì lè le gbagidi, àwọn apá ibi tó wà níta tí yìnyín ara rẹ̀ ti yòrò lè mú kí ẹran náà léwu. Nítorí pé ńṣe ni èyí á mú kí kòkòrò bakitéríà tó wà lára rẹ̀ máa pọ̀ sí i bó ṣe ń yòrò.” Nítorí náà, o lè fi ẹran náà sínú fìríìjì tàbí sínú ẹ̀rọ amú-nǹkan-gbóná tí wọ́n ń pè ní microvave kí ó lè yòrò tàbí kó o dì í sínú ọ̀rá tí kò ní ihò kó o wá gbé e sínú omi tútù.

Sè é dáadáa.

Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé ti sọ, “téèyàn bá se oúnjẹ dáadáa, ó máa pa àwọn kòkòrò téèyàn kò lè fojú rí.” Tó o bá ń se oúnjẹ, ní pàtàkì ọbẹ̀ ata àtàwọn ọbẹ̀ míì, rí i pé ọbẹ̀ náà hó dáadáa. a Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èèyàn kò lè fi ojú lásán mọ̀ bóyá àwọn oúnjẹ kan ti jinná, ńṣe ni àwọn tó ń se oúnjẹ máa ń tọ́ oúnjẹ náà wò tàbí kí wọ́n lo ohun èlò tí wọ́n fi máa ń mọ̀ bóyá oúnjẹ ti jinná, ìyẹn meat thermometer.

Má ṣe jẹ́ kó pẹ́ kó o tó jẹ ẹ́.

Má ṣe gbé oúnjẹ kalẹ̀ títí á fi tutù nini kó o to jẹ ẹ́, má ṣe jẹ́ kó pẹ́ rárá, kódà o lè jẹ ẹ́ gbàrà tó o bá sè é tán, kí oúnjẹ náà má bàa dèyí tí kò ṣeé jẹ mọ́. Jẹ́ kí àwọn oúnjẹ tó yẹ kó gbóná wà ní gbígbóná, kí o sì jẹ́ kí èyí tó yẹ kó tutù wà ní tútù. O lè kó ẹran yíyan sínú ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń yan nǹkan tá à ń pè ní oven tàbí sínú ayaran lórí ẹyín iná, kí iná lè máa rà á.

Tọ́jú oúnjẹ tó bá ṣẹ́ kù lọ́nà tó yẹ.

Ní orílẹ̀-èdè Poland, ìyá kan tó ń jẹ́ Anita sọ pé gbàrà tí òun bá ti se oúnjẹ tán ni ìdílé òun máa ń jẹun. Àmọ́, tí oúnjẹ bá ṣẹ́ kù, ó sọ ohun tó máa ń ṣe, ó ní, “lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí mo bá ti se oúnjẹ tán, mo máa ń bù ú sínú abọ́ kéékèèké, màá wá gbé e sínú ẹ̀rọ amú-nǹkan-dì. Torí bí oúnjẹ inú abọ́ náà kò ṣe pọ̀, kò ní pẹ́ kó tó yòrò nígbà tá a bá ti nílò rẹ̀.” Tó bá jẹ́ pé inú fìríìjì lo tọ́jú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ sí, rí i pé ẹ jẹ ẹ́ láàárín ọjọ́ mẹ́ta sí mẹ́rin.

Láwọn ilé oúnjẹ, kì í ṣe ìwọ lo máa se oúnjẹ tó o fẹ́ jẹ, ẹlòmíì ni. Torí náà, báwo lo ṣe lè dáàbò bo ìdílé rẹ nígbà tẹ́ ẹ bá lọ jẹun nílé oúnjẹ?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn oúnjẹ kan, bí adìyẹ, tòlótòló, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, máa ń pẹ́ kí wọ́n tó jinná ju àwọn ẹran míì lọ.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ: “Nígbà tí àwọn ọmọ mi bá ń se oúnjẹ, mo máa ń rán wọn létí pé kí wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n kọ sára agolo, bébà tàbí ọ̀rá tí oúnjẹ náà wà nínú rẹ̀.”—Yuk Ling, Hong Kong