4. Máa Ṣọ́ra Tó O Bá Ń Jẹun Níta
4. Máa Ṣọ́ra Tó O Bá Ń Jẹun Níta
Ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jeff, ẹni ọdún méjìdínlógójì [38] ni, ara rẹ̀ sì le dáadáa. Lọ́jọ́ kan, òun àti ìdílé rẹ̀ lọ jẹun nílé oúnjẹ kan nítòsí ìlú Pittsburgh, ìpínlẹ̀ Pennsylvania lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ní oṣù kan lẹ́yìn náà, kòkòrò àrùn kan tó máa ń mú kí ẹ̀dọ̀ ṣíwọ́ iṣẹ́ ṣekú pa Jeff. Kí ló fà á? Irú àlùbọ́sà eléwé kan wà nínú oúnjẹ rẹ̀, èyí tó mú kí ó ní àrùn mẹ́dọ̀wú, ti ìpele àkọ́kọ́, ìyẹn hepatitis A.
NÍ orílẹ̀-èdè kan ní ìwọ̀ oòrùn ayé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ilé oúnjẹ ni wọ́n ń ná ìdajì gbogbo owó tí wọ́n ń ná sórí oúnjẹ sí. Ní orílẹ̀-èdè yìí kan náà, tá a bá dá àwọn àìsàn táwọn èèyàn ń kó nínú oúnjẹ sí méjì, èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá kan ni àwọn èèyàn ń kó látinú oúnjẹ tí wọ́n ń rà ní ilé oúnjẹ.
Òótọ́ ni pé tó bá jẹ́ pé ilé oúnjẹ lo ti fẹ́ lọ jẹun, ẹlòmíì ló lọ ra àwọn ohun èlò tí wọ́n sè, tó ṣe ìmọ́tótó ilé ìdáná náà, tó sì se oúnjẹ náà. Àmọ́, ìwọ lo máa pinnu ibi tó o ti máa jẹun, ohun tí wàá jẹ àti bó o ṣe máa di èyí tí wàá rà lọ sílé.
● Wo àyíká rẹ dáadáa.
Daiane tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Bí èmi àti ìdílé mi bá ṣe ń wọ ilé oúnjẹ kan nígbà àkọ́kọ́, mo máa ń wò yíká láti mọ̀ bóyá àwọn tábìlì, aṣọ orí tábìlì, àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń se oúnjẹ àtàwọn òṣìṣẹ́ ilé oúnjẹ náà wà ní mímọ́ tónítóní tí wọ́n sì wà létòlétò. Tí mo bá kíyè sí pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa kúrò níbẹ̀, tá a sì máa wá ilé oúnjẹ míì lọ.” Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera máa ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé oúnjẹ látìgbàdégbà, kí wọ́n lè mọ̀ bóyá wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní, wọ́n sì máa ń tẹ àbájáde àbẹ̀wò wọn síta kí gbogbo èèyàn lè rí i.
● Ṣọ́ra tó o bá fẹ́ mú oúnjẹ lọ sílé.
Àjọ tó ń rí sí àbójútó oúnjẹ àti oògùn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn U.S. Food and Drug Administration, sọ pé: “Tó o bá fẹ́ gbé oúnjẹ tó o jẹ kù lọ sílé, tó o sì mọ̀ pé o kò ní délé láàárín wákàtí méjì lẹ́yìn náà, má wulẹ̀ mú oúnjẹ náà lọ sílé.” Torí náà, tó o bá fẹ́ mú oúnjẹ lọ sílé lẹ́yìn tó o jẹun tán, rí i pé ilé lo lọ tààràtà, kó o sì gbé oúnjẹ náà sínú fìríìjì.
Tó o bá ń fi àwọn ohun mẹ́rin tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí sílò, wàá lè túbọ̀ dáàbò bo oúnjẹ rẹ.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ RẸ: “A kọ́ àwọn ọmọ wa pé kí wọ́n máa ṣọ́ra fún àwọn oúnjẹ tó lè ṣàkóbá fún ara.”—Noemi, Philippines