Mo Rí Ojúlówó Ìfẹ́ àti Àlàáfíà
Mo Rí Ojúlówó Ìfẹ́ àti Àlàáfíà
Gẹ́gẹ́ bí Egidio Nahakbria ṣe sọ ọ́
Bí mo ṣe ń dàgbà, mi ò rí ìtọ́jú tó dára, kò sì sẹ́ni tó fi ìfẹ́ hàn sí mi. Ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ti wá dẹni táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́, ọkàn mi sì ti wá balẹ̀ gan-an. Báwo ni ọ̀ràn náà ṣe yí bìrí? Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé.
ỌDÚN 1976 ni wọ́n bí mi nínú ahéré kan tí ilẹ̀ rẹ̀ bu táútáú lórí àwọn òkè ńlá tó wà nílùú East Timor, tó jẹ́ apá kan orílẹ̀-èdè Indonesia nígbà yẹn. Tálákà paraku ni àwọn òbí mi, èmi sì ni ìkẹjọ nínú àwọn ọmọ mẹ́wàá tí wọ́n bí. Nítorí pé àwọn òbí mi kò lágbára láti bójú tó wa, wọ́n ní kí Kẹ́hìndé mi máa gbé lọ́dọ̀ àwọn, wọ́n sì ní kí èmi lọ máa gbé ọ̀dọ̀ ọmọ ẹ̀gbọ́n bàbá mi.
Ní December 1975, kó tó di pé wọ́n bí mi, orílẹ̀-èdè Indonesia gbéjà ko ìlú East Timor, èyí tó fa ogun abẹ́lé tí wọ́n jà fún ohun tó lé ní ogún ọdún. Nítorí èyí, ohun tí mo gbọ́njú mọ̀ láti kékeré ni ìwà ipá àti ìnira. Mo rántí bí àwọn sójà ṣe rọ́ wọ abúlé wa tí wọ́n sì fipá lé gbogbo wa pé kí á sá àsálà fún ẹ̀mí wa. Èmi àti ọmọ ẹ̀gbọ́n bàbá mi fẹsẹ̀ rìn títí a fi dé ibi àdádó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè ńlá kan, níbi tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn tó wá láti ìlú Timor ń gbé.
Àmọ́, àwọn sójà náà rí wa níbi tá a fara pa mọ́ sí, kò sì pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀jò bọ́ǹbù síbi tá a wà. Mi ò jẹ́ gbàgbé jìnnìjìnnì tó bá wa, bí àwọn èèyàn ṣe kú àti bí bọ́ǹbù ṣe ba àwọn nǹkan jẹ́. Nígbà tá a wá pa dà sí abúlé, ọkàn mi ò balẹ̀ mọ́, ojoojúmọ́ ni ẹ̀rù máa ń bà mí. Ọ̀pọ̀ lára àwọn aládùúgbò wa la ò rí mọ́ tàbí tí wọ́n ti kú, ẹ̀rù sì máa ń bà mí pé bóyá èmi ló máa kàn.
Nígbà ti mo fi máa di ọmọ ọdún mẹ́wàá, àìsàn ṣe ọmọ ẹ̀gbọ́n bàbá mi, àìsàn yẹn náà ló sì pa á, torí náà àwọn òbí mi ní kí n lọ máa gbé lọ́dọ̀ ìyá ìyá mi. Opó ni ìyá àgbà, ayé ti sú u, torí náà, ẹrù ìnira ló kà mí sí. Ṣe ló máa ń lò mí bí ẹrú. Lọ́jọ́ kan tí àìsàn ń ṣe mí tí mi ò sì lè ṣiṣẹ́, wọ́n lù mí bí ẹni lu bàrà, díẹ̀ báyìí ló kù kí ẹ̀mí mi bọ́. Àmọ́, Ọlọ́run bá mi ṣe é, ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n màmá mi wá mú mi pé kí n wá máa gbé pẹ̀lú ìdílé àwọn.
Mo ti pé ọmọ ọdún méjìlá nígbà yẹn, ìgbà yẹn ni mo sì tó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ìyàwó ọmọ ẹ̀gbọ́n màmá mi ṣàìsàn, èyí sì ba ọkọ wọn nínú jẹ́ gan-an. Kó má bàa di pé mò ń fi tèmi ni wọ́n lára, mo sá kúrò nílé mo sì dara pọ̀ mọ́ àwọn sójà tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Indonesia tí wọ́n ń gbé nínú igbó kìjikìji. Mo máa ń bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́, bí aṣọ fífọ̀, oúnjẹ sísè, mo sì máa ń tún inú àgọ́ wọn ṣe. Wọ́n tọ́jú mi dáadáa, inú èmi náà si dùn pé mo wúlò fún wọn. Àmọ́ lẹ́yìn oṣù mélòó kan, àwọn ẹbí mi mọ ibi tí mo wà, wọ́n sì ní kí àwọn sójà náà dá mi pa dà sí abúlé wa.
Mo Di Ajàfẹ́tọ̀ọ́-Ọmọnìyàn Lórí Ọ̀rọ̀ Ìṣèlú
Lẹ́yìn tí mo parí ilé ẹ̀kọ́ girama, mo lọ sí ìlú Dili tó jẹ́ olú ìlú East Timor, mo sì lọ sílé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásítì. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé àwọn ọ̀dọ́ tí ìgbésí ayé wa jọra. A jọ gbà pé ohun kan ṣoṣo tó lè mú kí orílẹ̀-èdè wa ní òmìnira, tí ìyípadà sì máa dé bá ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ni pé kí á kara bọ ìṣèlú. Àwa ọmọ iléèwé tá a jọ wà nínú àwùjọ yìí ṣètò ìwọ́de lórí ọ̀ràn ìṣèlú, èyí tí ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀ yọrí sí ìjà ìgboro. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi ló fara pa. Àwọn míì tiẹ̀ kú.
Nígbà tí East Timor fi máa gba òmìnira lọ́dún 2002, àwọn nǹkan ti bà jẹ́ ní orílẹ̀-èdè náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀mí èèyàn ló ti ṣòfò tí àìmọye sì ti sá kúrò nílùú. Mo retí pé nǹkan máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹnuure. Àmọ́, ohun tó gbòde kan ni àìríṣẹ́ṣe, ipò òṣì àti rògbòdìyàn ìṣèlú tí kò dáwọ́ dúró.
Ìgbà Ọ̀tun Dé Bá Mi
Lákòókò ti mò ń sọ yìí, àwọn ẹbí mi mélòó kan ń gbé pẹ̀lú mi, títí kan Andre tó jẹ́ ọmọ-ọmọ ẹbí ìyá mi kan, Andre yìí ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì paraku, mi ò nífẹ̀ẹ́ sí bí ìbátan mi yìí ṣe ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀sìn míì. Síbẹ̀, mo fẹ́ mọ ohun tó wà nínú Bíbélì, torí náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń ka Bíbélì tí Andre fi sínú yàrá rẹ̀. Ohun tí mo kà mú kó wù mí gan-an láti mọ púpọ̀ sí i.
Lọ́dún 2004, Andre fún mi ní ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi, mo sì pinnu pé màá lọ. Nítorí pé mi ò fara balẹ̀ ka ìwé ìkésíni náà dáadáa, mo ti dé síbi tí wọ́n ti máa ṣèpàdé náà ní wákàtí méjì ṣáájú àkókò. Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí náà dé, wọ́n bọ̀ mí lọ́wọ́, wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé inú àwọn dùn gan-an pé mo wá, títí kan àwọn tó jẹ́ ọmọ ìlú wa àtàwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì. Èyí wú mi lórí gan-an. Nígbà tí ẹni tó sọ ọ̀rọ̀ Ìrántí Ikú Kristi náà ń sọ̀rọ̀, mo kọ gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó kà sínú ìwé kan, mo sì pa dà yẹ̀ wọ́n wò nínú Bíbélì Kátólíìkì mi bóyá òótọ́ ni ohun tó sọ. Mo wá rí i pé kò sí ìyàtọ̀!
Ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, mo lọ ṣe ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì wa. Àmọ́, nítorí pé èmi àtàwọn mélòó kan pẹ́ dé, àlùfáà náà mú igi kan, ó sì fìbínú lé gbogbo wa jáde kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Bá a ṣe wà níta, àlùfáà náà parí ìsìn, ọ̀rọ̀ ìparí tó sọ fún àwọn ọmọ ìjọ ni pé, “Kí àlàáfíà Jésù máa wà pẹ̀lú yín.” Obìnrin kan wá fìgboyà sọ pé, “Báwo lo ṣe lè máa sọ̀rọ̀ nípa àlàáfíà nígbà tó jẹ́ pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ lé àwọn èèyàn kan kúrò nínú ṣọ́ọ̀ṣì tán ni?” Àlùfáà náà kò dá a lóhùn. Bí mo ṣe fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀ nìyẹn tí mi ò sì pa dà síbẹ̀ mọ́.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí mo sì máa ń tẹ̀ lé Andre lọ sípàdé wọn. Ẹnú ya àwọn ẹbí wa gan-an, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò wá. Ìyà-ìyà Andre kìlọ̀ fún wa pé: “Màá gbẹ́ kòtò màá sì sin ẹ̀yin ọmọ méjèèjì yìí sínú rẹ̀ tí ẹ kò bá ṣíwọ́ ẹ̀kọ́ tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sìn tuntun yẹn.” Àmọ́ gbogbo ìhàlẹ̀ rẹ̀ kò dá wa dúró. Ńṣe la pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ohunkóhun dá ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí dúró.
Mo Ṣe Àwọn Àyípadà
Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo wá rí i pé mi ò mọ ohun tí wọ́n ń pè ní ìfẹ́ rárá. Mi ò lójú àánú, tèmi nìkan ló máa ń yé mi, mi kì í sì lè fọkàn tán àwọn èèyàn. Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí mi. Nígbà tí mo ṣàìsàn tí àwọn ẹbí mi kò sì dá sí mi, àwọn Ẹlẹ́rìí wá kí mi, wọ́n sì bójú tó mi. Ìfẹ́ wọn kì í “ṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí pẹ̀lú ahọ́n, bí kò ṣe ní ìṣe àti òtítọ́.”—1 Jòhánù 3:18.
Láìka ti pé ìmúra mi kò jọ ti ọmọlúwàbí àti bí mo ṣe ní ìwà líle, àwọn Ẹlẹ́rìí fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” hàn sí mi, wọ́n sì fi “ìfẹ́ni ará” hàn sí mi. (1 Pétérù 3:8) Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé àwọn èèyàn fẹ́ràn mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í yíwà pa dà, mo sì dẹni tó kọ́ béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti ọmọnìkejì. Nípa bẹ́ẹ̀, mo ṣe ìrìbọmi láti fi hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Andre ṣèrìbọmi.
Ọlọ́run Bù Kún Mi Lásìkò Rògbòdìyàn
Lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, ó wù mí gan-an pé kí n ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn tí wọn kò rẹ́ni fìfẹ́ hàn sí wọn àtàwọn tí wọ́n ń hùwà ìrẹ́jẹ sí. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tàbí iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí àwa Ẹlẹ́rìí ṣe máa ń pè é. Ó túni lára gan-an pé kéèyàn máa kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ tó ń gbéni rò tó wà nínú Bíbélì ju pé kéèyàn máa lọ́wọ́ nínú ìwọ́de lórí ọ̀rọ̀ ìṣèlú àti kéèyàn máa ja ìjà ìgboro. Èmi náà wá dẹni tó ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ní ti gidi!
Lọ́dún 2006, ìjà ìṣèlú àti ẹ̀yà tún bẹ́ sílẹ̀ ní ìlú East Timor. Àìgbọ́ra-ẹni-ye tó ti wà nílẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ni àwọn ẹgbẹ́ tó ń bára wọn jà yìí tún ń fà. Wọ́n wá gbógun ti ìlú Dili, èyí sì mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn tó
wá láti ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè náà sá àsálà fún ẹ̀mí wọn. Èmi àtàwọn míì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sá lọ sí ìlú Baucau, ìyẹn ìlú ńlá kan tó wà ní nǹkan bí ọgọ́fà [120] kìlómítà ní apá ìlà oòrùn ìlú Dili. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú pọ́n wa níbi tá a sá lọ, Ọlọ́run bù kún wa torí pé ó ṣeé ṣe fún wa láti dá ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀, èyí tó jẹ́ ìjọ àkọ́kọ́ tí wọ́n máa dá sílẹ̀ yàtọ̀ sí èyí tó wà ní ìlú Dili.Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 2009, mo rí ìwé gbà pé kí n lọ sí àkànṣe ilé ẹ̀kọ́ kan tó wà fún àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, tí wọ́n máa ṣe nílùú Jakarta lórílẹ̀-èdè Indonesia. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú Jakarta gbà mí sílé, wọ́n sì tọ́jú mi gan-an. Ìfẹ́ àtọkànwá tí wọ́n fi hàn sí mi yìí wú mi lórí gan-an ni. Mo wá mọ̀ pé mo jẹ́ ara “ẹgbẹ́ àwọn ará” kárí ayé, ìyẹn ara ìdílé kan tó kárí ayé, tí wọ́n dìídì nífẹ̀ẹ́ mi.—1 Pétérù 2:17.
Àlááfíà Dé!
Lẹ́yìn tí mo parí ilé ẹ̀kọ́ yìí, mo pa dà sí ìlú Baucau, ibẹ̀ ni mo ṣì ń gbé títí di báyìí. Inú mi ń dùn níbí yìí bí mo ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Ọlọ́run, bí àwọn kan ṣe ran èmi náà lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ní abúlé àdádó kan lẹ́yìn ìlú Baucau, àwọn èèyàn bí ogún ni èmi àti àwọn ará kan máa ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, títí kan àwọn àgbàlagbà mélòó kan tí kò mọ̀ ọ́n kọ, mọ̀ ọ́n kà. Gbogbo wọn pátá ló máa ń wá sípàdé, mẹ́ta nínú wọn sì ti di ara ìdílé wa nípa tẹ̀mí, wọ́n ti ṣèrìbọmi, a sì jọ ń sin Jèhófà nínú ìjọ.
Láwọn ọdún mélòó kan sẹ́yìn, mo pàdé Felizarda, ọmọbìnrin onínúure kan tí ara rẹ̀ yọ̀ mọ́ni, ó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì, ó sì tẹ̀ síwájú gan-an títí ó fi ṣèrìbọmi. A ṣègbéyàwó ní ọdún 2011. Inú mi dùn láti sọ pé Andre tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí mi ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú East Timor. Kódà èyí tó pọ̀ jù lára àwọn mọ̀lẹ́bí wa ni kò ta kò mí mọ́, títí kan ìyà-àgbà Andre, tó sọ pé òun máa gbé wa sin.
Nígbà kan rí, inú máa ń bí mi, mi ò rẹ́ni fìfẹ́ hàn sí mi, mi ò sì já mọ́ nǹkan kan. Àmọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín mo wá rí ojúlówó ìfẹ́ àti àlàáfíà!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Egidio nígbà tó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn lórí ọ̀ràn ìṣèlú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Egidio àti Felizarda pẹ̀lú àwọn ará tí wọ́n jọ wà ní Ìjọ Baucau, nílùú East Timor