Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Òkú Lè Ran Alààyè Lọ́wọ́?

Ǹjẹ́ Òkú Lè Ran Alààyè Lọ́wọ́?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Òkú Lè Ran Alààyè Lọ́wọ́?

ỌJỌ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti gbà gbọ́ pé àwọn òkú lè dáàbò bo àwọn tó wà láàyè. Àpẹẹrẹ àtijọ́ kan tó fi hàn pé àwọn èèyàn ní ìgbàgbọ́ yìí ni ìtàn Odysseus, tí wọ́n tún ń pè ní Ulysses, èyí tí akéwì ilẹ̀ Gíríìkì tó ń jẹ́ Homer kọ. Gẹ́gẹ́ bí Homer ti sọ nínú ìtàn àròsọ rẹ̀, akọni inú ìtàn náà sapá kí ó lè mọ̀ bóyá òun máa pa dà dé ìlú òun ní erékùṣù Ithaca, torí náà ó lọ sí ìlú àwọn òkú láti béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ woṣẹ́woṣẹ́ kan tó jẹ́ òkú.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti tọ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ lọ, tí wọ́n sùn lórí ibojì àwọn baba ńlá wọn tàbí tí wọ́n rú àwọn ẹbọ lóríṣiríṣi kí wọ́n lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ń rú wọn lójú. Ǹjẹ́ òótọ́ ni pé àwọn òkú lè tọ́ àwọn alààyè sọ́nà?

Àṣà Tó Kárí Ayé

Ọ̀pọ̀ lára àwọn ìsìn tó lórúkọ lágbàáyé ló ń kọ́ àwọn èèyàn pé wọ́n lè bá àwọn òkú sọ̀rọ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopedia of Religion sọ pé: “Fífi agbára abàmì pe ẹ̀mí àwọn òkú jáde kí àwọn èèyàn lè bá wọn sọ̀rọ̀ jẹ́ ọ̀nà kan táwọn èèyàn gbà ń wádìí ohun tó máa ṣẹlẹ̀.” Ó wá fi kún un pé àṣà náà ti dèyí tó “kárí ayé.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia náà gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ó sọ pé, “àṣà bíbá òkú sọ̀rọ̀ lónírúurú ọ̀nà ti dèyí tó kárí ayé.” Abájọ tó fi jẹ́ pé nínú ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn, àwọn kan tó ń fi tọkàntọkàn ṣe ẹ̀sìn ń wá bí wọ́n ṣe máa rí ìsọfúnni gbà látọ̀dọ̀ àwọn òkú!

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Òótọ́ ni pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì dẹ́bi gan-an fún bíbá òkú sọ̀rọ̀, àmọ́ àkọsílẹ̀ wà pé àwọn èèyàn lọ́wọ́ nínú àṣà yìí láwọn àkókò tí ọ̀làjú kò tíì dé àti ìgbà tí ọ̀làjú bẹ̀rẹ̀.” Kí ni Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí?

Ṣó Yẹ Kó O Wádìí Ọ̀rọ̀ Lọ́wọ́ Òkú?

Láyé àtijọ́, Jèhófà Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ . . . ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú.” (Diutarónómì 18:9-13) Kí nìdí tí Jèhófà fi ka irú nǹkan bẹ́ẹ̀ léèwọ̀? Tó bá jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí alààyè bá òkú sọ̀rọ̀, Ọlọ́run ì bá gba àwa èèyàn láyè láti máa ní irú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àmọ́, ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, irú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kò ṣeé ṣe. Báwo la ṣe mọ̀?

Léraléra ni Ìwé Mímọ́ kọ́ni pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun. Wo ohun tí Oníwàásù 9:5 sọ: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” Sáàmù 146:3, 4, sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” Wòlíì Aísáyà pẹ̀lú sọ ohun kan náà pé àwọn òkú ti di “aláìlè-ta-pútú nínú ikú.”—Aísáyà 26:14.

Àmọ́, onírúurú èèyàn ló gbà gbọ́ pé àwọn ti bá èèyàn àwọn tó ti kú sọ̀rọ̀ rí. Irú ìrírí bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀, torí náà, ó dájú pé ọ̀pọ̀ ti bá ẹnì kan láti ilẹ̀ àwọn ẹ̀mí sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n, bó ṣe wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lókè yìí, kì í ṣe àwọn òkú ni wọ́n bá sọ̀rọ̀. Tani wọ́n bá sọ̀rọ̀ nígbà náà?

Tani Wọ́n Ń Bá Sọ̀rọ̀?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì di ẹ̀mí èṣù. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-5; Júúdà 6, 7) Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí ló ń mú kí àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn èèyàn ṣì máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú. Láti lè mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ gba irọ́ yìí gbọ́, wọ́n máa ń dọ́gbọ́n ṣe bí àwọn tó ti kú nípa bíbá àwọn tó wà láàyè sọ̀rọ̀.

Bíbélì sọ nípa Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ Ọba Ísírẹ́lì pé, lẹ́yìn tí Jèhófà ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀ nítorí àìgbọràn rẹ̀, ó gbìyànjú láti bá wòlíì Sámúẹ́lì tó ti kú sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ abẹ́mìílò kan. Ẹ̀mí kan bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ lóòótọ́, àmọ́ kì í ṣe Sámúẹ́lì. Ní ti gidi, nígbà tí Sámúẹ́lì ṣì wà láàyè, kò fẹ́ rí ọba yìí, àti pé Sámúẹ́lì kórìíra àwọn tó ń bá òkú sọ̀rọ̀. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ẹ̀mí èṣù tó dọ́gbọ́n ṣe bíi Sámúẹ́lì ló bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀.—1 Sámúẹ́lì 28:3-20.

Ọ̀tá Ọlọ́run ni àwọn ẹ̀mí èṣù, ó sì léwu téèyàn bá ní àjọṣe pẹ̀lú wọn. Ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ fi pa á láṣẹ fún wa pé: “Ẹ má ṣe yíjú sí àwọn abẹ́mìílò, ẹ má sì ṣe wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn olùsàsọtẹ́lẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀, láti di aláìmọ́ nípasẹ̀ wọn.” (Léfítíkù 19:31) Ìwé Diutarónómì 18:11, 12 kìlọ̀ fún wa pé, “Ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú” ń ṣe “ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” Kódà, lára ìwà àìṣòótọ́ tí Jèhófà tìtorí rẹ̀ pa Ọba Sọ́ọ̀lù ni pé ó lọ béèrè “lọ́wọ́ abẹ́mìílò pé kí ó ṣe ìwádìí.”—1 Kíróníkà 10:13, 14.

Nígbà náà, ta ló yẹ kó o yíjú sí tó o bá nílò ìtọ́sọ́nà tó kọjá ọgbọ́n ẹ̀dá èèyàn, nígbà tí ọ̀rọ̀ bá ta kókó tàbí tí o kò mọ ohun tó yẹ kó o ṣe? Ìwé Mímọ́ sọ pé Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ “Olùkọ́ni Atóbilọ́lá.” Tí ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ bá ń ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tẹ́ ẹ sì ń fi ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ sílò lóòótọ́, ṣe ló máa dà bíi pé ‘etí yín yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn yín tí ń sọ pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”’ (Aísáyà 30:20, 21) Àwọn Kristẹni lónìí kò retí pé kí Ọlọ́run tòótọ́ bá àwọn sọ̀rọ̀ ní tààràtà, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń fi Bíbélì tọ́ wọn sọ́nà. Bẹ́ẹ̀ ni, ṣe ló dà bíi pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ń sọ pé: ‘Jẹ́ kí n máa tọ́ ẹ sọ́nà.’

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn tó ń wá bí wọ́n ṣe máa bá òkú sọ̀rọ̀?—Diutarónómì 18:9-13.

● Ṣé àwọn òkú lè kọ́ ẹni tó wà láàyè ní ohunkóhun? Kí nìdí tó o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?—Oníwàásù 9:5.

● Ta la lè yíjú sí fún ìtọ́ni láìsí ìbẹ̀rù?—Aísáyà 30:20, 21.