Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Oúnjẹ Aṣaralóore Máa Wà Fún Gbogbo Èèyàn Láìpẹ́!

Oúnjẹ Aṣaralóore Máa Wà Fún Gbogbo Èèyàn Láìpẹ́!

Oúnjẹ Aṣaralóore Máa Wà Fún Gbogbo Èèyàn Láìpẹ́!

Ọ̀PỌ̀ nǹkan lo lè ṣe láti dáàbò bo oúnjẹ rẹ. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan míì wà tó kọjá agbára rẹ. Bí àpẹẹrẹ, kò sí bí ìwọ fúnra rẹ ṣe lè yẹ gbogbo oúnjẹ wò kó o to rà á tàbí kó o to sè é. Ó lè pọn dandan pé kó o ra oúnjẹ tí wọ́n ti sè tí wọ́n sì gbé wá láti ọ̀nà jíjìn. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn kẹ́míkà gbẹ̀mígbẹ̀mí tó wà nínú afẹ́fẹ́, omi tàbí ilẹ̀ ti kó wọnú àwọn kan lára oúnjẹ tó o rà.

Nínú ìròyìn kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Dídènà Àwọn Àìsàn Téèyàn Ń Kó Látinú Oúnjẹ: Ìṣòrò Tó Ń Kojú Gbogbo Ayé,” àwọn ọ̀gá àgbà nínú Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé, “mímú kí oúnjẹ wà láìséwu kì í ṣe ìṣòro tí ijọba orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan lè dá yanjú; àfi kí gbogbo orílẹ̀-èdè fọwọ́ sowọ́ pọ̀.” Ìṣòro tó kárí ayé ni kíkó àìsàn látinú oúnjẹ!

Àmọ́, ọ̀pọ̀ lè máa ṣe kàyéfì nípa ìdí tó fi dá wa lójú pé oúnjẹ aṣaralóore máa wà fún gbogbo èèyàn láìpẹ́. Ohun tó mú kí ó dá wa lójú ni pé, “Jèhófà, Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé” ṣèlérí pé òun máa yanjú ìṣòro aráyé lórí ọ̀rọ̀ oúnjẹ. (Jóṣúà 3:13) Àwọn kan lè sọ pé bí oúnjẹ ṣe ń ṣàkóbá fáwọn èèyàn fi hàn pé Ọlọ́run kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Àmọ́ rò ó wò ná: Bí ọ̀kan lára àwọn tó máa ń gbé oúnjẹ fún oníbàárà nílé oúnjẹ bá fi ìwà àìbìkítà mú kí oúnjẹ aládùn kan bà jẹ́, ǹjẹ́ a lè sọ pé olórí alásè ló jẹ̀bi? Ó dájú pé a ò ní sọ bẹ́ẹ̀.

Lọ́nà kan náà, àwa èèyàn la fà á tí oúnjẹ aṣaralóore tó wà láyé fi bà jẹ́, kì í ṣe Ẹlẹ́dàá. Ẹ̀dá èèyàn lo fà á tí oúnjẹ gbẹ̀mígbẹ̀mí fi gbalégbòde. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 11:18.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, Ọlọ́run ti ṣe ohun tó fi hàn pé oúnjẹ tó ṣara lóore ni òun fẹ́ ká máa jẹ. Òun ló dá ayé àtàwọn igi “tí ó fani mọ́ra ní wíwò” tí ó sì tún “dára fún oúnjẹ.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:9) Kódà lẹ́yìn tí àìsàn ti kọlu aráyé, Jèhófà Ọlọ́run fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní àwọn ìtọ́ni tó ṣe pàtó tó máa jẹ́ kí wọ́n lè dáàbò bo oúnjẹ àti ara wọn.—Wo àpótí tá a pè ní “Òfin Ìlera Tó Yẹ Kéèyàn Máa Tẹ̀ Lé.”

Irú oúnjẹ wo ni Ọlọ́run fẹ́ ká máa jẹ? Bíbélì sọ fún wa pé: “Ó ń mú kí koríko tútù rú jáde fún àwọn ẹranko, àti ewéko fún ìlò aráyé, láti mú kí oúnjẹ jáde wá láti inú ilẹ̀, àti wáìnì tí ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀, láti mú kí òróró máa mú ojú dán, àti oúnjẹ tí ń gbé ọkàn-àyà ẹni kíkú ró.” (Sáàmù 104:14, 15) Bíbélì tún sọ pé “gbogbo ẹran tí ń rìn, tí ó wà láàyè, lè jẹ́ oúnjẹ” fún wa.—Jẹ́nẹ́sísì 9:3.

Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa ọjọ́ iwájú àwa èèyàn ni pé: “Dájúdájú, òun yóò sì rọ òjò sí irúgbìn rẹ, èyí tí o fún sí ilẹ̀, àti gẹ́gẹ́ bí èso ilẹ̀, èyíinì ni oúnjẹ, tí yóò di sísanra àti olóròóró. Ní ọjọ́ yẹn, ohun ọ̀sìn rẹ yóò máa jẹko ní pápá ìjẹko aláyè gbígbòòrò.” (Aísáyà 30:23) Dípò àwọn àkòrí tó máa ń bani nínú jẹ́ tó ń jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn lónìí, láìpẹ́, ohun tí a ó máa kà ni “Oúnjẹ aṣaralóore ti wà fún gbogbo èèyàn!”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

Ẹlẹ́dàá wa ṣèlérí pé ọjọ́ ọ̀la máa dára àti pé a máa rí oúnjẹ aṣaralóore tó pọ̀ jẹ

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]

“ÒFIN ÌLERA TÓ YẸ KÉÈYÀN MÁA TẸ̀ LÉ”

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin Mósè. Òfin yìí dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn àìsàn téèyàn lè kó nínú oúnjẹ. Gbé àwọn ìtọ́ni yìí yẹ̀ wò:

● Yẹra fún àwọn ohun èlò tó dọ̀tí àti àwọn abọ́ tó ti fara kan òkú ẹranko èyíkéyìí: “Ohun èlò èyíkéyìí tí a bá ń lò ni kí a fi sínú omi, yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́, lẹ́yìn náà, yóò sì di ohun tí ó mọ́.”—Léfítíkù 11:31-34.

● Má ṣe jẹ òkú ẹran: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran èyíkéyìí.”—Diutarónómì 14:21.

● Má ṣe jẹ́ kí oúnjẹ tó o jẹ kù pẹ́ nílẹ̀ kó o tó jẹ ẹ́: “Ní ọjọ́ kejì, ohun tí ó bá ṣẹ́ kù lára rẹ̀ ni a lè jẹ pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ohun tí ó bá ṣẹ́ kù lára ẹran ẹbọ náà ní ọjọ́ kẹta ni kí a fi iná sun.”—Léfítíkù 7:16-18.

Ẹnú ya Dókítà A. Rendle Short gan-an pé Òfin Mósè ní “òfin ìlera tó yẹ kéèyàn máa tẹ̀ lé tó mọ́gbọ́n dáni tó sì ṣeé múlò nípa ìmọ́tótó,” tó fi jẹ́ pé tá a bá fi wéra pẹ̀lú òfin àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká, kò láfiwé.