Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Wo Ni Mo Fi Ń Ṣe Àwòkọ́ṣe?

Àwọn Wo Ni Mo Fi Ń Ṣe Àwòkọ́ṣe?

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Àwọn Wo Ni Mo Fi Ń Ṣe Àwòkọ́ṣe?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa

ÌDÍ tó fi yẹ kó o ní àwọn tí wàá fi ṣe àwòkọ́ṣe

IBI tó o ti lè rí wọn

BÓ O ṢE LÈ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn

ÌDÍ TÓ FI YẸ KÓ O NÍ ÀWỌN TÍ WÀÁ FI ṢE ÀWÒKỌ́ṢE

ÒÓTỌ́ Ọ̀RỌ̀: Ó ṣeé ṣe kó o fẹ́ máa hùwà bíi tàwọn èèyàn tó o bá kà sí pàtàkì. Irú èèyàn tó o bá kà sí pàtàkì ló máa pinnu irú ìwà tí wàá máa hù, bóyá ìwà rere tàbí búburú.

Ohun tó o nílò: Àwọn àpẹẹrẹ àtàtà tó yẹ ká fara wé.—Fílípì 3:17.

Ìṣòro tó wà níbẹ̀: Àwọn èèyàn tó gbajúmọ̀, irú bí àwọn olórin, eléré ìdárayá tàbí àwọn òṣèré orí ìtàgé ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fẹ́ láti fara wé, kódà bí ìwà wọn kò bá tiẹ̀ bójú mu.

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Bíbélì fi ìwà tẹ́nì kan ní wé aṣọ. (Kólósè 3:9, 10) Ká sọ pé o lọ sí ọjà láti lọ ra aṣọ, ṣé ọlọ́jà kan tí kò mọ aṣọ wọ̀ ni wàá fẹ́ kó pinnu irú aṣọ tí ìwọ máa wọ̀ fún ẹ? Kí wá nìdí tí wàá fi jẹ́ kí àwọn gbajúmọ̀ èèyàn tí kò níwà ọmọlúwàbí máa pinnu irú ẹni tí ìwọ máa jẹ́? Dípò tí wàá fi kọjú síbi tí ayé kọjú sí, tó o bá fi àwọn èèyàn tó níwà ọmọlúwàbí ṣe àwòkọ́ṣe, ìyẹn máa jẹ́ kí (1) o lè yan àwọn ìwà tó wù ẹ́ pé kó o máa hù, kí o sì (2) lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó ní irú ìwà yẹn dáadáa.

IBI TÓ O TI LÈ RÍ WỌN

Fi àmì sí òótọ́ tàbí irọ́ lábẹ́ gbólóhùn kọ̀ọ̀kan tó tẹ̀ lé e yìí.

1. Ẹni tó o bá máa fi ṣe àwòkọ́ṣe gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tó o ti rí sójú.

Òótọ́Irọ́

2. Ẹni tó o bá máa fi ṣe àwòkọ́ṣe gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni pípé.

Òótọ́Irọ́

3. O lè fi àwọn èèyàn tó pọ̀ ṣe àwòkọ́ṣe rẹ.

Òótọ́Irọ́

Àwọn Ìdáhùn

1. Irọ́. Kódà, o lè fi àwọn tó ti gbé láyé àtijọ́ ṣe àwòkọ́ṣe rẹ. Inú Bíbélì lo sì ti lè rí àwọn àpẹẹrẹ tó dáa jù lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ka orí 11 nínú ìwé Hébérù, wàá rí i pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan àwọn ọkùnrin àti obìnrin mẹ́rìndínlógún [16] tá a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ wọn. Nínú orí kejìlá, Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ohun kan tó ṣe pàtàkì, ó gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n “tẹjú mọ́” Jésù, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Hébérù 12:2) Jésù ni àwòkọ́ṣe wa tó tayọ jù.—Jòhánù 13:15. a

2. Irọ́. Yàtọ̀ sí Jésù, kò tún sí ẹni pípé míì lẹ́yìn Ádámù. (Róòmù 3:23) Kódà, wòlíì Èlíjà gan-an tó jẹ́ akọni ‘jẹ́ ẹlẹ́ran-ara bí awa.’ (Jákọ́bù 5:17, Ìròhìn Ayọ̀) Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ rí nípa àwọn èèyàn bíi Míríámù, Dáfídì, Jónà, Màtá àti Pétérù. Bíbélì sọ àṣìṣe táwọn ọkùnrin àti obìnrin wọ̀nyí ṣe láìfi ohunkóhun pa mọ́. Síbẹ̀, tá a bá wo apá tó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé wọn, àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fún wa, torí náà, a lè fi wọ́n ṣe àwòkọ́ṣe wa.

3. Òótọ́. O lè ní àwọn èèyàn tó pọ̀ tí wàá fi ṣe àwòkọ́ṣe. Tí ẹnì kan nínú wọn bá jẹ́ òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ kára, òmíràn lè jẹ́ onísùúrù ẹ̀dá. Ẹlòmíì nínú wọn sì lè jẹ́ ẹni tó máa ń ní ẹ̀mí pé nǹkan máa dáa láìka ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ní sí. (1 Kọ́ríńtì 12:28; Éfésù 4:11, 12) Máa wo ibi tí àwọn ẹlòmíì dáa sí, wàá rí i pé wọ́n ní àwọn ìwà tó dáa tó o lè fara wé.—Fílípì 2:3.

BÓ O ṢE LÈ TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ WỌN

1. Kíyè sí àwọn tó o fi ṣe àwòkọ́ṣe rẹ dáadáa. Àpọ́sítélì sọ fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní pé: “Kí ẹ máa ṣakiyesi àwọn tí ó ń hùwà gẹ́gẹ́ bí àpẹrẹ tí a ti jẹ́ fún yín.”—Fílípì 3:17, Bíbélì Ìròhin Ayọ̀.

2. Sún mọ́ wọn. Tó bá ṣeé ṣe fún ẹ, lo àkókò pẹ̀lú àwọn èèyàn tó o bá fi ṣe àwòkọ́ṣe rẹ lóde òní. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”—Òwe 13:20.

3. Ronú nípa àwọn ìwà rere tí àwọn tó o fi ṣe àwòkọ́ṣe ní. Hébérù 13:7 sọ pé: “Bí ẹ sì ti ń fẹ̀sọ̀ ṣàgbéyẹ̀wò bí ìwà wọ́n ti rí, ẹ máa fara wé ìgbàgbọ́ wọn.”

Ṣé o ti múra tán láti ṣe àwọn nǹkan tá a sọ yìí? Kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú àlàfo tó wà ní ìsàlẹ̀ yìí.

Ohun Tí Màá Ṣe!

Yan ìwà kan tó wù ẹ́ pé kó o máa hù. (Ṣé wàá fẹ́ láti jẹ́ ẹni tí ara rẹ̀ máa ń yá mọ́ọ̀yàn, ọ̀làwọ́, òṣìṣẹ́ kára, ẹni tó lè mú nǹkan mọ́ra nígbà tí ìjákulẹ̀ bá dé tàbí ẹni tó ṣeé fọkàn tán?)

․․․․․

Yan ẹnì kan tó ní irú ìwà tó wù ẹ́ pé kó o ní yẹn. b

․․․․․

Tó o bá fi ẹnì kan ṣe àwòkọ́ṣe, kò túmọ̀ sí pé o ní láti sọ ara ẹ di onítọ̀hún yẹn. Ìwọ fúnra rẹ ṣì ní àwọn ibi tó o dáa sí. Àmọ́, tó o bá ní àwọn èèyàn dáadáa tó o fi ṣe àwòkọ́ṣe, ìyẹn á jẹ́ kí ìwọ náà máa ní ìwà tó dáa bó o ṣe ń dàgbà. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà wọn, ìwọ fúnra rẹ yóò di àwòkọ́ṣe fún àwọn ẹlòmíì.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.pr418.com

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà lóde òní náà lè jẹ́ àwòkọ́ṣe gidi fún wa. Lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwọn òbí wa, àwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò wa, àwọn tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ nínú wọn lára àwọn tá a jọ wà nínú ìjọ Kristẹni tàbí ẹlòmíì tó jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà tó o mọ̀ dáadáa tàbí tó o ti kà nípa rẹ̀.

b Ọ̀nà míì tó o lè gbà ṣe ohun tá a sọ yìí ni pé kó o kọ́kọ́ yan ẹni tó o bá fẹ́ fi ṣe àwòkọ́ṣe. Lẹ́yìn náà, béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: ‘Irú ìwà wo gan-an ló mú kí ẹni yìí wù mí?’ Fi ẹni yẹn ṣe àwòkọ́ṣe rẹ, kó o sì máa sapá láti fara wé ìwà tó wù ọ́ lára rẹ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]

Kí nìdí tí wàá fi jẹ́ kí àwọn gbajúmọ̀ èèyàn tí kò níwà ọmọlúwàbí máa pinnu irú ẹni tí ìwọ máa jẹ́?

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

Layla—Èrò tó dáa ni Sandra ọ̀rẹ́ mi máa ń ní nípa àwọn nǹkan. Ó tún mọ Bíbélì dáadáa. Torí náà, ṣe ló máa ń dà bíi pé ó ti mọ ohun tó yẹ kó ṣe nípa àwọn ìṣòro tó bá wáyé. Mo lè lọ bá a nígbàkigbà tí mo bá níṣòro, yálà ìṣòro náà le tàbí kò le.

Terrence—Ọ̀rẹ́ mi ni Kyle àti David, wọn kì í fi ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ṣeré. Ìgbà gbogbo ni wọ́n máa ń múra tán láti ran àwọn èèyàn tó bá níṣòro lọ́wọ́ tí wọ́n á sì gbé ìṣòro tiwọn tì sí ẹ̀gbẹ́ kan. Àpẹẹrẹ àtàtà ni wọ́n jẹ́ fún mi.

Emmaline—Mọ́mì mi ni mo fi ṣe àwòkọ́ṣe mi. Torí wọ́n mọ Bíbélì dáadáa bí ẹni mowó, wọ́n sì máa ń wá ọ̀nà láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Mọ́mì mi gbà pé àǹfààní ńlá ni ìṣẹ́ ìwàásù jẹ́, kì í ṣe iṣẹ́ tó ń súni. Mo gbóṣùbà fún wọn torí ìyẹn!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

TÚBỌ̀ KÀ SÍ I NÍPA RẸ̀!

Ǹjẹ́ o mọ bí o ṣe lè rí àwọn èèyàn tó jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà tó o lè fi ṣe àwòkọ́ṣe? Ka Hébérù orí 11, kó o sì fi ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tàbí obìnrin tí wọ́n mẹ́nu kàn níbẹ̀ ṣe àwòkọ́ṣe. Bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìwà àtàtà tí ẹni yẹn ní àti ọ̀nà tó o lè gbà ṣe bíi tirẹ̀.

O lè rí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i, tí wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà, tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn tó o lè fi ṣe àwòkọ́ṣe nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní àti Ìkejì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Wo akọ́lé tá a pè ní “Atọ́ka Àwòkọ́ṣe” lọ́wọ́ ẹ̀yìn ìwé méjèèjì.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?

Béèrè pé kí àwọn òbí rẹ sọ fún ẹ nípa àwọn tí wọ́n fi ṣe àwòkọ́ṣe wọn nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́ àti ní báyìí tí wọ́n ti dàgbà. Àǹfààní wo ni wọ́n ti rí nínú bí wọ́n ṣe ní àwọn tí wọ́n fi ṣe àwòkọ́ṣe?