Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó Dáa Kéèyàn Jí Ìwé Wò Kó Lè Gba Máàkì Tó Pọ̀?

Ṣé Ó Dáa Kéèyàn Jí Ìwé Wò Kó Lè Gba Máàkì Tó Pọ̀?

Ṣé Ó Dáa Kéèyàn Jí Ìwé Wò Kó Lè Gba Máàkì Tó Pọ̀?

ṢÉ ỌMỌ iléèwé ni ẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí wọ́n ń jí ìwé wò ní kíláàsì kí wọ́n lè gba máàkì tó pọ̀. Ká sòótọ́, ìṣòro yìí ti wá pọ̀ gan-an báyìí. Lọ́dún 2008, ìwádìí kan tí ilé ẹ̀kọ́ kan tó ń jẹ́ Josephson Institute ṣe láàárín nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan àti ààbọ̀ [30,000] àwọn ọmọ iléèwé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, fi hàn pé ó lé ní ìdá mẹ́fà nínú mẹ́wàá lára àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yẹn tó sọ pé àwọn jí ìwé wò nínú ìdánwò tí wọ́n ṣe lọ́dún yẹn. Àmọ́ àwọn kan tiẹ̀ sọ pé iye àwọn tó jí ìwé wò ju ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin lọ.

Jíjí ìwé wò ti di ìṣòro tó lé kenkà nílẹ̀ Yúróòpù, pàápàá dída iṣẹ́ àwọn ẹlòmíì kọ. Ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ Digithum sọ pé: “Àwọn Ìkànnì kan wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó máa ń ta àròkọ táwọn ọmọ iléèwé kọ àti ìwé táwọn kan fi ṣàkójọ ìwádìí wọn nígbà tí wọ́n fẹ́ gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga tàbí èyí tí wọ́n fi gboyè dókítà, èyí sì ti wá di ìṣòro tó túbọ̀ ń kọni lóminú.”

Kí nìdí tí jíjí ìwé wò tàbí rírẹ́ àwọn ẹlòmíì jẹ fi wá di ìṣòro tó ń kọni lóminú? Ṣé àwọn tó ń jí ìwé wò tiẹ̀ ń rí àǹfààní kankan nínú ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn? Ǹjẹ́ ó dáa kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ téèyàn ò bá tiẹ̀ ní gba máàkì tó pọ̀?

Kí Nìdí Tí Àṣà Yìí Fi Ń Pọ̀ Sí I?

Ìwà ọmọlúwàbí ti ń dín kù. Ìwé kan tó ń jẹ́ American School Board Journal sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́ ló gbà pé ìdí tí ìwà jíjí ìwé wò fi ń pọ̀ sí i ni pé ìwà ọmọlúwàbí ń dín kù láwùjọ wa, àwọn èèyàn kò sì mọ̀ ju tara wọn nìkan lọ.” Nígbà tí ọmọbìnrin kan ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ tí wọ́n jọ ṣe ìdánwò àṣekágbá, ó sọ pé: “Gbogbo wa la . . . jí ìwé wò torí ká lè rí yunifásítì tó dáa wọ̀. Ọmọ dáadáa ni wá, kò sí ọmọkọ́mọ nínú wa . . . Ohun tó kàn wù wá ni pé ká ṣáà ti rí yunifásítì tó dáa wọ̀.” Ìwà burúkú yìí tiẹ̀ ti ń ran àwọn òbí míì pàápàá. Gbogbo ohun tó jẹ wọ́n lógún kò ju pé kí àwọn ọmọ wọn ṣáà ti yege, torí náà, nígbà míì wọ́n máa ń fara mọ́ ọn pé kí àwọn ọmọ wọn jí ìwé wò tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ṣe bí ẹni pé ọ̀rọ̀ náà kò kàn wọ́n. Wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ àwọn ọmọ wọn dìdàkudà.

Àwọn ọ̀dọ́ fẹ́ yege bíi tàwọn ojúgbà wọn. Ọ̀gbẹ́ni Donald McCabe tó jẹ́ olùdásílẹ̀ àjọ kan tó máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lórí jíjẹ́ olóòótọ́ níléèwé, ìyẹn International Center for Academic Integrity, sọ pé àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tó ń jí ìwé wò gbà pé táwọn ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe làwọn tó ń jí ìwé wò tí wọ́n sì ń mú un jẹ á kàn máa rẹ́ àwọn jẹ.

Ipa tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé ń kó. Ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé ń mú kó rọrùn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti jí ìwé wò lọ́nà táwọn èèyàn kò lè tètè fura sí. Wọ́n lè gba ìsọfúnni nípa iṣẹ́ àṣetiléwá àtàwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kí wọ́n sì fún àwọn míì. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwọ̀nba díẹ̀ ni wọ́n máa ń rí mú nínú àwọn tó jí ìwé wò, èyí ló ń ki àwọn míì láyà láti máa jí ìwé wò.

Àwọn àpẹẹrẹ búburú tí wọ́n ń rí. Kì í ṣe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nìkan ló máa ń jí ìwé wò, àwọn àgbàlagbà náà máa ń rẹ́ àwọn ẹlòmíì jẹ lẹ́nu ìṣòwò wọn, nínú ìṣèlú, nínú eré ìdárayá àti lọ́pọ̀ ìgbà nínú ilé níbi táwọn òbí ti ń hùwà àìṣòótọ́ lórí ọ̀rọ̀ owó orí tàbí owó ìbánigbófò. Ọ̀gbẹ́ni David Callahan tó kọ ìwé The Cheating Culture tó dá lórí àṣà ìrẹ́jẹ sọ pé: “Táwọn tó wà ní ipò àṣẹ tàbí àwọn tó jẹ́ àwòkọ́ṣe láwùjọ bá ń rẹ àwọn èèyàn jẹ, ohun tí mo rò pé wọ́n ń dọ́gbọ́n sọ fáwọn ọ̀dọ́ ni pé kò sóhun tó burú nínú jíjí ìwé wò.” Àmọ́ ṣóòótọ́ ni? Ǹjẹ́ ó wá yẹ kéèyàn jí ìwé wò torí pé ó fẹ́ gba máàkì tó pọ̀?

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kó O Jí Ìwé Wò?

Ó yẹ kó o bi ara rẹ pé, ‘Kí nìdí téèyàn fi ń lọ sí ilé ìwé?’ Ìdí ni pé á lè jẹ́ kí akẹ́kọ̀ọ́ mọ bí yóò ṣe bójú tó àwọn ojúṣe tó bá ní, bí àpẹẹrẹ, á lè mọ bó ṣe lè fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ìṣòro tó lè wáyé níbi iṣẹ́, kó sì yanjú wọn? Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ti mọ́ lára láti máa jí ìwé wò kò ní lè mọ bó ṣe máa yanjú ìṣòro. Torí náà, àwọn tó bá ti mọ́ lára láti máa jí ìwé wò kàn ń bo ìkùdíẹ̀ káàtó wọn mọ́lẹ̀ ni, wọ́n sì ń fa ìlọsíwájú àti àṣeyọrí wọn sẹ́yìn.

Ọ̀gbẹ́ni Callahan tún sọ pé: “Àwọn tó bá ń ṣe nǹkan lọ́nà ẹ̀bùrú láti ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wọn, irú bíi kí wọ́n máa jí ìwé wò nílé ẹ̀kọ́, ṣe ni ìwà yẹn máa ń bá wọn dé ibi iṣẹ́ wọn.” Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ dà bíi aṣọ tàbí aago ayédèrú tó kàn fojú jọ ojúlówó lásán àmọ́ tí kì í tọ́jọ́.

Àwọn tó ń jí ìwé wò tàbí tí wọ́n ń hùwà àìṣòótọ́ ń fi ara wọn sínú ewu, torí pé tí wọ́n bá rí wọn mú, wọ́n máa jìyà ohun tí wọ́n ṣe. Ìtìjú ńlá ló sì máa jẹ́ fún wọn. Kódà, wọ́n tún lè lé wọn kúrò níléèwé tàbí kí wọ́n fi ìyà jẹ wọ́n lọ́nà míì tó le gan-an. Abájọ tí Bíbélì fi kìlọ̀ pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Ìbẹ̀rù pé wọ́n máa mú ẹ tó o bá jí ìwé wò tàbí tó o hùwà àìṣòótọ́ kọ́ ló yẹ kó sún ẹ láti jẹ́ olóòótọ́. Àwọn ìdí pàtàkì míì wà tó fi yẹ kó o jẹ́ olóòótọ́.

Jíjẹ́ Olóòótọ́ Ló Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí

Àwọn ọ̀dọ́ tó bá gbọ́n máa ń gbìyànjú láti ní àwọn ìwà tó dáa tó máa wúlò fún wọn jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn, kì í ṣe ní ilé ẹ̀kọ́ wọn nìkan. Nítorí náà, wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára ní ilé ẹ̀kọ́, wọ́n sì máa ń gbìyànjú láti ní àwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ kí wọ́n gbayì, èyí táá jẹ́ kí àwọn tó máa gbà wọ́n sí iṣẹ́ lọ́jọ́ iwájú mọyì wọn, tí àwọn fúnra wọn á sì máa láyọ̀ títí di ọjọ́ alẹ́ wọn.

A lè rí àwọn ìlànà yìí nínú Bíbélì, àǹfààní ló sì máa jẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tó bá mú un lò. Ìwé 2 Tímótì 3:16, 17 sọ pé irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jorge tó wà ni kíláàsì kẹta níléèwé girama sọ pé: “Àwọn ọmọ kíláàsì mi jí ìwé wò torí pé wọ́n fẹ́ gba máàkì tó pọ̀ láì làágùn. Ṣùgbọ́n èmi fẹ́ ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sì. Nínú Òwe 14:2, Bíbélì sọ pé ‘ẹni tí ń rìn nínú ìdúróṣánṣán rẹ̀ ń bẹ̀rù Jèhófà, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ oníwà wíwọ́ ní àwọn ọ̀nà rẹ̀ ń tẹ́ńbẹ́lú Rẹ̀.’ Mo mọ̀ pé kò sí ohun tó pa mọ́ lójú Ọlọ́run. Torí náà èmi kì í jí ìwé wò tàbí ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti jí ìwé wò.”

Ó lè jẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń gbìyànjú láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ló mọ̀wé jù ní kíláàsì tàbí kí wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ mọ̀wé. Ṣùgbọ́n àwọn ló gbọ́n jù torí pé wọ́n ń fi ìpìlẹ̀ àṣeyọrí wọn nígbèésí ayé lélẹ̀ sórí àpáta ràbàtà. (Sáàmù 1:1-3; Mátíù 7:24, 25) Láfikún sí i, ó dá wọn lójú pé Ẹlẹ́dàá ń tì wọ́n lẹ́yìn, inú rẹ̀ sì ń dùn sí wọn.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

ÀWỌN ÌLÀNÀ TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ

● “Ètè òtítọ́ ni a ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in títí láé, ṣùgbọ́n ahọ́n èké yóò wà fún kìkì ìwọ̀nba ìṣẹ́jú kan.”—Òwe 12:19.

● “Ènìyàn tí ó ń ṣe àwọn ìṣe ìṣòtítọ́ yóò gba ọ̀pọ̀ ìbùkún.”—Òwe 28:20.

● “Nítorí Ọlọ́run tòótọ́ tìkára rẹ̀ yóò mú gbogbo onírúurú iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun fífarasin, ní ti bóyá ó dára tàbí ó burú.” —Oníwàásù 12:14.

● “A ti dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.”—Hébérù 13:18.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]

Ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé ń mú kó rọrùn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti jí ìwé wò lọ́nà táwọn èèyàn kò lè tètè fura sí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń jí ìwé wò dà bí aago ayédèrú tó kàn dà bíi pé ó dáa lójú lásán