Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayé Tí Ọlọ́run Tún Ṣe Ṣé Wàá Fẹ́ Gbé Níbẹ̀?

Ayé Tí Ọlọ́run Tún Ṣe Ṣé Wàá Fẹ́ Gbé Níbẹ̀?

Ayé Tí Ọlọ́run Tún Ṣe Ṣé Wàá Fẹ́ Gbé Níbẹ̀?

● Àwọn àpilẹ̀kọ tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé ìròyìn Jí! yìí sọ ohun tí gbogbo èèyàn kárí ayé ń fẹ́, ìyẹn ni pé kí ayé yìí dáa. Ǹjẹ́ ìrètí kankan tiẹ̀ wà pé ayé yìí ṣì ń bọ̀ wá dáa?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣe ìwé ìròyìn yìí gbà gbọ́ pé Bíbélì ló sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún wa. Bíbélì nìkan ní ìwé mímọ́ tó ṣàlàyé ìtàn ẹ̀dá èèyàn láti ibi tó ti bẹ̀rẹ̀. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú, ohun tó sọ sì yàtọ̀ pátápátá sí èrò ọ̀pọ̀ èèyàn pé nǹkan ò lè dáa mọ́.

Ṣé wàá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí? Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é, ó sì ti wà ní èdè 244 báyìí. Ó lè béèrè ẹ̀dà kan ìwé náà lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ. Tó o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá ẹ wá, jọ̀wọ́ kọ ìsọfúnni tó bá yẹ sínú fọ́ọ̀mù tó wà nísàlẹ̀ yìí, kí o sì fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì tó bá yẹ lára èyí tó wà ní ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn yìí.

□ Mo fẹ́ gba ẹ̀dà kan ìwé yìí.

□ Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.