Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Lè Bá Wa Tún Ayé Ṣe?

Ta Ló Lè Bá Wa Tún Ayé Ṣe?

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ta Ló Lè Bá Wa Tún Ayé Ṣe?

“Àwọn èèyàn fẹ́ kí àwọn aṣáájú wọn dáhùn ìbéèrè yìí. Ojútùú ni wọ́n ń wá, wọn ò fẹ́ àṣetì, wọn ò sì fẹ́ àwáwí.”—Ọ̀GBẸ́NI BAN KI-MOON TÓ JẸ́ Ọ̀GÁ ÀGBÀ ÀJỌ ÌPARAPỌ̀ ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ LÓ SỌ BẸ́Ẹ̀.

BÍBÉLÌ sọ pé à ń gbé ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1) Àwọn ìròyìn tó ń bani lẹ́rù là ń gbọ́ nípa ogun, ìpániláyà, ọrọ̀ ajé tó túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i àti bí àwọn èèyàn ṣe ń ba àyíká jẹ́ lọ́nà tó lè yọrí sí àjálù.

Ǹjẹ́ ìrètí kankan tiẹ̀ wà pé nǹkan ṣì máa sunwọ̀n sí i? Ṣé àwọn ìjọba wa lè yanjú àwọn ìṣòro ayé yìí? Àbí ká kúkú wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí ibòmíì?

Ohun Tí Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè Máa Ń Sọ

Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló máa ń sọ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà máa ń sọ nínú ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè wọn pé ‘ìmọ̀ àwọn ṣọ̀kan lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run,’ wọ́n sì tún kọ ọ́ sára owó bébà àti owó ẹyọ wọn pé, “Ọlọ́run La Gbẹ́kẹ̀ Lé.”

Bẹ́ẹ̀ sì rèé, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni kò tiẹ̀ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà, bákan náà lọ̀rọ̀ rí láwọn orílẹ̀-èdè míì tó máa ń sọ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn. Kódà èrò àwọn èèyàn tó ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run pàápàá yàtọ̀ síra nípa ibi tí ọwọ́ Ọlọ́run mọ nínú ọ̀ràn aráyé.

● Àwọn kan sọ pé Ọlọ́run kì í dá sí ọ̀rọ̀ àwa èèyàn rárá, pé ṣe ló fi wá sílẹ̀ pé ká máa darí ara wa.

● Àwọn míì sọ pé àwọn ìjọba ni Ọlọ́run máa ń lò, pé ó máa bù kún ìsapá wọn láti bá wa tún ayé ṣe.

Èwo nínú ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí ló bá èrò tìẹ mu?

Rò ó wò ná: Tó bá jẹ́ òótọ́ ni ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ yẹn, a jẹ́ pé inú ìṣòro ńlá la wà yẹn. Tó bá sì jẹ́ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ kejì yẹn, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé Ọlọ́run wà lẹ́yìn orílẹ̀-èdè kan ju àwọn míì lọ ni? Bí orílẹ̀-èdè méjì bá ń bára wọn jagun, tí àwọn méjèèjì sì gbàdúrà tọkàntọkàn pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí àwọn lè ṣẹ́gun, ẹ̀yìn ta ni Ọlọ́run máa wà nínú àwọn méjèèjì?’ Àbí Ọlọ́run tiẹ̀ lè máà sí lẹ́yìn àwọn méjèèjì?

Ohun tí Bíbélì fi Kọ́ni

1. Ọlọ́run kò dá àwa èèyàn láti máa ṣàkóso ara wa. Bíbélì sọ pé: “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ látọjọ́ táláyé ti dáyé ń jẹ́rìí sí òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí. Ìjọba èèyàn kò tíì tún ayé ṣe, kódà pẹ̀lú àwọn ohun tí wọ́n ń sọ pé àwọn máa ṣe àtàwọn ohun tí wọ́n ní lọ́kàn láti ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.”—Oníwàásù 8:9.

2. Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa. Ọlọ́run ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa, ó sì mọ̀ ọ́n lára. Ó máa wá nǹkan ṣe sí í kó lè ràn wá lọ́wọ́. Ọ̀nà wo ló máa gbà ràn wá lọ́wọ́? Nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ “tí a kì yóò run láé.”—Dáníẹ́lì 2:44.

3. Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi kan. Ìjọba yìí ni ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ní ọkàn rere ń gbàdúrà fún nínú Àdúrà Olúwa tàbí Baba Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run tí wọ́n sábà máa ń gbà. Àwọn èèyàn ń fi àdúrà yẹn bẹ Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Kíyè sí i nínú àdúrà yẹn pé ọ̀run nìkan kọ́ ni Ìjọba Ọlọ́run máa wà, ó tún máa jẹ́ kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.

4. Ọlọ́run lágbára láti tún ayé yìí ṣe, ó sì máa lo Ìjọba rẹ̀ láti ṣe é. Tó o bá ń ṣiyèméjì nípa ohun tá a sọ yìí, wo ohun tí Bíbélì fi kọ́ni.

● Ọlọ́run dá èèyàn ní pípé ó fi wọ́n sínú ọgbà ìtura kan.—Jẹ́nẹ́sísì 1: 27-31.

● Ọlọ́run kò gbàgbé ohun tó ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé wa yìí láìka àwọn ìṣòro tá a ní sí.—Sáàmù 37:11, 29.

● Ọlọ́run ti ṣe àwọn ohun kan tó máa mú kó ṣeé ṣe fún ilẹ̀ ayé láti pa dà rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀, ìyẹn sì máa kan àwa èèyàn pẹ̀lú.—Jòhánù 3:16.

Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run àti bó ṣe máa bá wa tún ayé yìí ṣe? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a tẹ ìwé ìròyìn yìí máa dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́. O ò ṣe jíròrò àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ yìí pẹ̀lú wọn nígbà tí wọ́n bá wá ẹ wá sílé?

Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

Àwọn nǹkan wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa tún ṣe?

Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run máa tún ayé ṣe, báwo ló sì ṣe máa ṣe é?

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tí àwọn ìjọba èèyàn kò fi lágbára láti ṣe àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe kí ayé yìí lè dáa?​—Jeremáyà 10:23.

● Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà fi hàn pé òun bìkítà nípa wa?​—Jòhánù 3:16.

● Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa mú kó ṣeé ṣe fún ilẹ̀ ayé àtàwọn tó ń gbé nínú rẹ̀?​—Sáàmù 37:11, 29.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

Ǹjẹ́ àwọn ìjọba èèyàn lè yanjú ìṣòro ayé? Àbí ká wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí ibòmíì?