Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ | MASSIMO TISTARELLI

Ẹnì Kan Tó Ń Ṣe Rọ́bọ́ọ̀tì Sọ Ìdí Tó Fi Gba Ọlọ́run Gbọ́

Ẹnì Kan Tó Ń Ṣe Rọ́bọ́ọ̀tì Sọ Ìdí Tó Fi Gba Ọlọ́run Gbọ́

Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Massimo Tistarelli ní Yunifásítì Sassari lórílẹ̀-èdè Ítálì. Ó wà lára àwọn olóòtú gbajúgbajà ìwé ìròyìn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Ó sì ti kópa nínú ìwádìí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó lé ní ọgọ́rùn-ún lórí ẹ̀kọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí àwa èèyàn ṣe ń dá ojú ẹlòmíì mọ̀ àti bá a ṣe ń ṣe àwọn nǹkan míì, irú bí mímú bọ́ọ̀lù tẹ́nì kan jù sí wa láti ọ̀ọ́kán. Ó wá ń fìyẹn ṣe ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì tí ojú rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ bí ojú àwa èèyàn. Àwọn tó ṣe ìwé yìí fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò nípa iṣẹ́ tó ń ṣe àti ohun tó mú kó gbà pé Ọlọ́run wà.

Ẹ jọ̀ọ́ sà, inú ẹ̀sìn wo ni wọ́n bí yín sí?

Ọmọ ìjọ Kátólíìkì làwọn òbí mi, àmọ́ wọn kì í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà, mi ò gbà pé Ọlọ́run wà. Wọ́n kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, pé gbogbo nǹkan kàn ṣàdédé wà ní, mo sì gbà pé bó ṣe rí nìyẹn lóòótọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà yẹn, mi ò gbà pé Ẹlẹ́dàá wà, mo mọ̀ pé ohun kan ní láti wà tó ju àwa èèyàn lọ. Torí náà, mo lọ ṣèwádìí nínú ẹ̀sìn Búdà, Híńdù àti ẹ̀sìn Táò. Àmọ́ àwọn ẹ̀kọ́ wọn ò dáhùn ohun tó ń jẹ mí lọ́kàn.

Kí ló jẹ́ kẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ sí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì?

Láti kékeré ni mo ti nífẹ̀ẹ́ sí oríṣiríṣi ẹ̀rọ. Wọ́n máa ń ra àwọn ohun ìṣeré ọmọdé tó ń lo iná mànàmáná fún mi. Mo sì máa ń tú u palẹ̀ tí màá sì tún un tò. Torí pé onímọ̀ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ni bàbá mi, ṣe ni mo máa ń da ìbéèrè bò wọ́n kí n lè mọ bí rédíò àti fóònù ṣe ń ṣiṣẹ́.

Irú iṣẹ́ wo lẹ kọ́ níléèwé?

Mo kọ́ nípa àwọn ẹ̀rọ tó ń báná ṣiṣẹ́ ní Yunifásítì Genoa, lórílẹ̀-èdè Ítálì. Mo sì ṣe ìwádìí lórí bí ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì ṣe ń ṣiṣẹ́. Ìyẹn ni mo fi gboyè ọ̀mọ̀wé. Ìwádìí yẹn tún ní í ṣe pẹ̀lú bí ojú àwa èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́. Mo sì lo ìmọ̀ yẹn láti ṣe ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì tí ojú rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ bí ojú àwa èèyàn.

Kí ló mú kẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ sí bí ojú àwa èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́?

Ìdí ni pé ojú jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun àgbàyanu tó wà lára wa. Kì í ṣe ojú wa nìkan ló ń jẹ́ ká ríran, ọpọlọ wa gan-an ló ń jẹ́ ka mọ ohun tá a rí. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ téèyàn bá fẹ́ mú bọ́ọ̀lù tó jù sí òfuurufú. Bí ẹni yẹn bá ṣe ń sáré lọ síbi tí bọ́ọ̀lù yẹn wà, ẹyinjú rẹ̀ máa gbé àwòrán bọ́ọ̀lù náà síbi tí wọ́n ń pè ní retina, nínú ojú. Àwòrán yẹn sì máa wà níbẹ̀ láìka pé ojú ẹni yẹn àti bọ́ọ̀lù yẹn kò dúró lójú kan. Bí ẹni yẹn bá tún ṣe tẹjú mọ́ bọ́ọ̀lù yẹn sí tún máa mú kí àwòrán rẹ̀ dúró sínú ojú.

Bákan náà, ojú ẹni yẹn á tún ti ṣírò bí bọ́ọ̀lù yẹn ṣe ń yára sí àti apá ibi tó ti fẹ́ balẹ̀. Ó yà mí lẹ́nu gan-an láti rí i pé inú ojú ni ìṣírò yẹn ti ń bẹ̀rẹ̀, torí pé ojú onítọ̀hún máa ṣírò bí bọ́ọ̀lù náà ṣe jìnnà tó. Àwọn iṣan ìfura tó ń gbé ìsọfúnni lọ sínú ọpọlọ á wá gbé àwòrán náà látinú ojú lọ sínú ọpọlọ. Ọpọlọ ló máa jẹ́ kí onítọ̀hún mọ ibi tó ti máa rí bọ́ọ̀lù náà mú. Ẹ ò rí i pé àgbàyanu niṣẹ́ Ọlọ́run.

Kí ló mú kẹ́ ẹ gbà pé Ẹlẹ́dàá wà?

Lọ́dún 1990, mo fi oṣù bíi mélòó kan ṣe ìwádìí ní yunifásítì tí wọ́n ń pè ní Trinity College, ní Dublin, lórílẹ̀-èdè Ireland. Nígbà tí èmi àti Barbara, ìyàwó mi ń pa dà lọ sílé, à ń ronú nípa bí ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ wa ṣe máa rí. A tún yà lọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sì fún mi ní ìwé kan tó sọ nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ìyẹn Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe é. Àwọn ìwádìí tí wọ́n fara balẹ̀ ṣe sínú ìwé náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ìgbà yẹn ni mo wá rí i pé èmi gan-an ò lóye ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tí mo gbà gbọ́ dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, mo rò pé àwọn ìwádìí tí àwọn awalẹ̀pìtàn ṣe ti ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n lẹ́yìn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Kódà, bí mo ṣe túbọ̀ ń ṣèwádìí lórí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, bẹ́ẹ̀ ni mo wá ń rí i pé àsọdùn lásán ni.

Mo ronú jinlẹ̀ nípa àwọn rọ́bọ́ọ̀tì tí mò ń ṣe. Ohun tí Ẹlẹ́dàá ti ṣe ni mo kúkú ń wò láti fi ṣe é

Mo tún ronú jinlẹ̀ nípa àwọn rọ́bọ́ọ̀tì tí mò ń ṣe. Ohun tí Ẹlẹ́dàá ti ṣe ni mo kúkú ń wò láti fi ṣe é. Mi ò tíì lè ṣe ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì tó máa lè mú bọ́ọ̀lù lófurufú bí àwa èèyàn ṣe máa mú un. Bí ẹ bá ṣe fi kọ̀ǹpútà sọ fún rọ́bọ́ọ̀tì pé kó mú bọ́ọ̀lù náà ló máa mú un. Kò lè lo ìdánúṣe láti mú un lọ́nà míì. Ọ̀nà táwa èèyàn ń gbà kẹ́kọ̀ọ́ yàtọ̀ fíìfíì sí tàwọn ẹ̀rọ àtọwọ́dá. Àwọn ẹ̀rọ náà kò sì ṣàdédé wà, ẹnì kan ló ṣe é. Ọ̀kan nìyẹn lára àwọn ohun tó mú kí n gbà pé ó ní láti jẹ́ pé ẹnì kan ló dá àwa èèyàn.

Kí ló mú kẹ́ ẹ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ohun kan ni pé, èmi àtìyàwó mi fẹ́ràn bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe máa ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ìwádìí tí wọ́n máa ń ṣe kí wọ́n tó tẹ àwọn ìwé wọn jáde máa ń wú mi lórí gan-an. Mo máa ń fẹ́ mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nǹkan, torí náà mo máa ń ṣèwádìí gan-an. Bí àpẹẹrẹ, mo nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì. Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa wọn, ó jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì lóòótọ́. Lọ́dún 1992, èmi àtìyàwó mi ṣèrìbọmi, a sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ǹjẹ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tẹ́ ẹ ní kò ti dín ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run kù báyìí?

Rárá o, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì gan-an ló jẹ́ kí n túbọ̀ nígbàgbọ́ dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bí àwa èèyàn ṣe ń dá ojú ẹlòmíì mọ̀. Láàárín wákàtí mélòó kan tá a bá bímọ tuntun ni ọmọ náà ti máa ń dá ojú àwọn èèyàn mọ̀. Kì í ṣòro fún wa rárá láti dá ojú èèyàn mọ̀, ì báà jẹ́ pé ẹni náà wà láàárín èrò. Tá a bá wo ojú ẹnì kan, a tún lè fòye mọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀. Síbẹ̀, a lè má mọ̀ rárá pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtagbà ìsọfúnni ló ń wáyé lọ́nà tó yára kánkán láàárín ojú àti ọpọlọ wa. Èyí ló ń jẹ́ ká lè dá ẹni tá a bá rí mọ̀.

Ó dá mi lójú gan-an pé ojú wa jẹ́ ẹ̀bùn àtàtà látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run. Mo mọyì onírúurú ẹ̀bùn tó fi jíǹkí wa, títí kan Bíbélì. Èyí sì máa ń mú kó máa wù mí láti sọ nípa Ọlọ́run fún àwọn èèyàn. Àròjinlẹ̀ ti jẹ́ kí n rí i pé Ọlọ́run ló yẹ ká fi ògo fún nítorí gbogbo iṣẹ́ àrà tó ti ṣe.