OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Ohun Tó Ń Mú Ọkàn Fà Sí Ìṣekúṣe
Ǹjẹ́ Bíbélì dẹ́bi fún wíwo ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe?
“Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Mátíù 5:28.
ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ FI KÀN Ẹ́
Lóde òní, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi tó o yíjú sí tí kò sí àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe, ohun tó sì gbòde kan nìyẹn. Àmọ́ tó o bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, tó o sì fẹ́ láyọ̀, ó yẹ kó o mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Lóòótọ́, Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ní tààràtà. Àmọ́ wíwo àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe kò bá àwọn ìlànà Bíbélì mu.
Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọpé tí ọkùnrin tó ti gbéyàwó bá ń “bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan” tí kì í ṣe aya rẹ̀, tó sì ń wù ú pé kó bá a lò pọ̀, ó lè mú kó ṣe panṣágà. Ìlànà Bíbélì yìí kan gbogbo ẹni tó ti lọ́kọ tàbí aya àtàwọn tí kò tí ì ṣègbéyàwó. Tó bá ń “bá a nìṣó ní wíwo” àwòrán ìṣekúṣe, tó sì ń wù ú pé kó ní ìbálòpọ̀ tí kò tọ́, ìwà tí inú Ọlọ́run kò dùn sí ló ń hù yẹn.
Téèyàn ò bá ṣèṣekúṣe ńkọ́, àmọ́ tó ń wo ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe?
“Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín di òkú . . . ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò.”—Kólósè 3:5.
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Àwọn kan tó ń ṣèwádìí sọ pé téèyàn bá ń wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe, kò túmọ̀ sí pé ó máa ṣe ìṣekúṣe. Àmọ́, ṣé inú Ọlọ́run dùn sí wíwo àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì sọ pé “ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn” wà lára àwọn ohun tí inú Ọlọ́run kò dùn sí. (Éfésù 5:3, 4) Torí náà, àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe kò lè mú inú Ọlọ́run dùn. Lóde òní, lára àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ni àwọn fídíò tó ń gbé àwòrán àwọn tó ń ṣe panṣágà jáde àti àwòrán àwọn ọkùnrin méjì tàbí obìnrin méjì tó ń bára wọn lò pọ̀, títí kan oríṣiríṣi ìwà ìṣekúṣe míì. Ó dájú pé téèyàn bá ń wo irú àwọn ìṣekúṣe bẹ́ẹ̀, ó burú jáì lójú Ọlọ́run ju ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn lọ pàápàá.
Ẹnu àwọn tó ń ṣèwádìí ò kò lórí bóyá wíwo àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe lè mú kéèyàn ṣe ìṣekúṣe. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ lọ́nà tó ṣe kedere pé inú Ọlọ́run kò dùn sí àwọn ohun tó ń mú ọkàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe, kò sì lè jẹ́ kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run. Ìmọ̀ràn Bíbélì ni pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín di òkú . . . ní ti àgbèrè [àti] ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo.” (Kólósè 3:5) Àwọn tó ń wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń mú ara wọn gbóná.
Báwo lo ṣe lè jáwọ́ nínú wíwo ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe?
“Ẹ máa wá ohun rere, kì í sì í ṣe ohun búburú . . . Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere.”—Ámósì 5:14, 15.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì sọ pé nígbà kan, àwọn kan wà tí ìṣekúṣe ti jàrábà, àwọn míì jẹ́ ọ̀mùtípara, àwọn míì sì ń jalè; àmọ́ wọ́n jáwọ́ nínú ìwàkíwà yìí. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é? Ìmọ̀ràn Bíbélì ni wọ́n tẹ̀ lé tí wọ́n fi lè kórìíra ohun búburú.
Téèyàn bá ń ro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀, ìyẹn ohun tó lè jẹyọ nídìí wíwo ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe, á rọrùn fún un láti kórìíra ìwàkíwà yìí. Ìwádìí kan tí wọ́n gbé jáde láìpẹ́ yìí ní Ilé Ẹ̀kọ́ Yunifásítì kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé àwọn kan tí wọ́n máa ń wo àwòrán ìṣekúṣe “máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn, wọ́n máa ń fẹ́ dá wà, àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì kì í gún régé,” ọ̀pọ̀ nǹkan ìbànújẹ́ míì sì máa ń ṣẹlẹ̀ sí wọn. Bá a sì ti sọ ṣáájú pé wíwo ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe kì í mú inú Ọlọ́run dùn, ó tún máa ń fa aburú tó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Kì í jẹ́ kéèyàn lè sún mọ́ Ọlọ́run.
Bíbélì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fẹ́ràn àwọn ohun tó dáa. Bá a bá ṣe tẹra mọ́ Bíbélì kíkà tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ tá a ní fún ìlànà ìwà rere Ọlọ́run ṣe máa jinlẹ̀ tó. Ìfẹ́ yẹn ló máa jẹ́ ká lè kórìíra àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe, ká sì lè ronú bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Èmi kì yóò gbé ohun tí kò dára fún ohunkóhun ka iwájú mi.”—Sáàmù 101:3.