Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Bó O Ṣe Lè Bójú Tó Ọmọ Tó Ń Ṣe Ìjọ̀ngbọ̀n

Bó O Ṣe Lè Bójú Tó Ọmọ Tó Ń Ṣe Ìjọ̀ngbọ̀n

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Tí inú bá ti ń bí ọmọ rẹ tí kò ju ọmọ ọdún méjì lọ, á bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, á máa fẹsẹ̀ janlẹ̀, á sì máa da gbogbo nǹkan rú. O wá ń bi ara rẹ pé: ‘Ṣé nǹkan kan ò máa ṣe ọmọ mi báyìí? Àbí nǹkan kan wà tí mò ń ṣe tí kò dáa tó jẹ́ kó máa ṣe ìjọ̀ngbọ̀n ni? Ṣé ó máa fìwà yìí sílẹ̀?’

O ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè fi ìwà yìí sílẹ̀. Àmọ́, jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó lè mú kí ọmọ rẹ máa ṣe ìjọ̀ngbọ̀n.

OHUN TÓ FÀ Á

Àwọn ọmọdé ò mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n sọ bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Ìyẹn sì lè mú kí wọ́n máa ṣe ìjọ̀ngbọ̀n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ ìyẹn nìkan kọ́ ló ń fà á o.

Ronú nípa àwọn ìyípadà tó máa ń bá ọmọdé nígbà tó bá wà ní nǹkan bí ọdún méjì. Gbogbo nǹkan làwọn òbí máa ń ṣe fún un látìgbà tí wọ́n ti bí i. Bí àpẹẹrẹ, tó bá ń sunkún, kíá ni wọ́n á gbé e mọ́ra, tí wọ́n á sì rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún. Wọ́n á máa ronú pé: Àbí ara ọmọ náà kò yá ni? Ṣé ebi ló ń pa á ni? Àbí ó fẹ́ kí n rẹ òun lẹ́kún? Àbí ṣe ló fẹ́ kí n pààrọ̀ ìtẹ́dìí òun?’ Gbogbo ohun táwọn òbí bá rí i pé ó máa tu ọmọ náà lára ni wọ́n máa ń ṣe. Bó sì ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn torí ọmọ jòjòló kò lè dá ohunkóhun ṣe láìsí àwọn òbí rẹ̀.

Àmọ́, tí ọmọ náà bá ti ń pé ọmọ ọdún méjì, òun náà á ti bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé àwọn òbí ò sá kiri nítorí òun mọ́ bíi ti ìgbà kan. Kódà, dípò kí wọ́n máa ṣe ohun bá fẹ́, wọ́n ti wá ń retí pé ṣe ohun táwọn fẹ́. Nǹkan ti yí pa dà bìrí, kí ọmọ náà sì lè fi hàn pé inú òun ò dùn sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọ̀ngbọ̀n.

Kì í pẹ́ tí ọmọ fi máa mọ̀ pé yàtọ̀ sí bí àwọn òbí òun ṣe ń tọ́jú òun, wọ́n tún gbọ́dọ̀ máa tọ́ òun sọ́nà. Àwọn òbí rẹ̀ sì retí pé kó mọ̀ pé, ojúṣe òun ni láti “jẹ́ onígbọràn sí [wọn].” (Kólósè 3:20) Àmọ́, ọmọ náà máa ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti tán àwọn òbí rẹ̀ ní sùúrù, nípa ṣíṣe ìjọ̀ngbọ̀n lóríṣiríṣi.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Máa lo òye. Ọmọ rẹ kì í ṣe àgbàlagbà. Nítorí kò nírìírí tó láti ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀, ó lè ki àṣejù bọ̀ ọ́ tó bá ń bínú. Torí náà, máa fi ọ̀ràn ro ara rẹ wò.—Ìlànà Bíbélì:1 Kọ́ríńtì 13:11.

Má ṣe fara ya. O kò ní lè yanjú ìṣòro náà tí ìwọ náà bá bínú nítorí pé ọmọ rẹ ń ṣe ìjọ̀ngbọ̀n. Bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ohun tó ṣẹlẹ̀ ni kó o bójú tó, gbọ́kàn kúrò lórí ìjọ̀ngbọ̀n tó ń ṣe. Tó o bá ń rántí ìdí tí àwọn ọmọdé fi máa ń ṣe ìjọ̀ngbọ̀n, á jẹ́ kó o máa ṣe sùúrù.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 19:11.

Dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tí ọmọ rẹ fẹ́, tó bá tún ti fẹ́ nǹkan míì ó ṣeé ṣe kó tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọ̀ngbọ̀n. Torí náà, fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ̀ pé ohun tó o fẹ́ ló gbọ́dọ̀ ṣe.—Ìlànà Bíbélì: Mátíù 5:37.

Tó o bá ń rántí ìdí tí àwọn ọmọdé fi máa ń ṣe ìjọ̀ngbọ̀n, á jẹ́ kó o máa ṣe sùúrù

Ṣe sùúrù. Má ṣe ronú pé ọmọ rẹ kàn máa ṣíwọ́ ṣíṣe ìjọ̀ngbọ̀n lọ́sàn-án kan òru kan, pàápàá tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà tó bá ti ń ṣe ìjọ̀ngbọ̀n lo máa ń jẹ́ kó ṣohun tó fẹ́. Àmọ́, tó o bá ń ṣohun tó yẹ kó o ṣe nígbà gbogbo, ó ṣeé ṣe kí ìjọ̀ngbọ̀n ọmọ rẹ dín kù. Tó bá sì yá, kò ní ṣe ìjọ̀ngbọ̀n mọ́. Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra.”—1 Kọ́ríńtì 13:4.

O tún lè gbìyànjú àwọn àbá yìí:

  • Tí ọmọ rẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọ̀ngbọ̀n, gbé e mọ́ra (tó bá ṣeé ṣe), má ṣe jẹ́ kó ráyè da àwọn nǹkan rú, má sì jẹ́ kó ṣe ara rẹ̀ léṣe. Má ṣe jágbe mọ́ ọmọ rẹ. Ṣe sùúrù títí ara rẹ̀ fi máa wálẹ̀. Tó bá yá, ó máa rí i pé ìjọ̀ngbọ̀n kò ṣàǹfààní kankan.

  • Mọ ibì kan láàárín ilé tó o lè gbé ọmọ rẹ sí tó bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọ̀ngbọ̀n. Gbé e síbẹ̀ kó o sì sọ fún un pé ó dìgbà tí ara rẹ̀ bá balẹ̀ kó tó lè jáde níbẹ̀.

  • Tí ọmọ rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọ̀ngbọ̀n ní gbangba, mú un lọ síbi tó ti máa ku ẹ̀yin méjèèjì nìkan. Má ṣe torí pé àwọn èèyàn ń wò yín kó o wá ṣe ohun tí ọmọ náà fẹ́. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọmọ rẹ máa ronú pé tóun bá ti fẹ́ kó o ṣe ohun kan àfi kóun ṣe ìjọ̀ngbọ̀n.