OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Ọtí Líle
Ǹjẹ́ ó dára kéèyàn máa mu ọtí?
“Wáìnì tí ń mú kí ọkàn-àyà ẹni kíkú máa yọ̀, láti mú kí òróró máa mú ojú dán, àti oúnjẹ tí ń gbé ọkàn-àyà ẹni kíkú ró.”—Sáàmù 104:15.
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Nínú ọ̀pọ̀ ìdílé, wọ́n máa ń mu ọtí nígbàkigbà tí wọ́n bá ń jẹun. Àwọn ìdílé kan sì wà tó jẹ́ pé wọn kì í fẹnu kan ọtí líle èyíkéyìí. Kí nìdí tí èrò àwọn èèyàn nípa ọtí fi yàtọ̀? Oríṣiríṣi nǹkan ló fà á tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀. Lára wọn ni àṣà ìbílẹ̀, ọ̀rọ̀ ìlera àti ẹ̀sìn.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì dẹ́bi fún mímu ọtí àmujù tàbí kéèyàn sọ ọtí di bárakú, ṣùgbọ́n a lè mú un ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Kódà, ọjọ́ pẹ́ tàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti máa ń mu ọtí wáìnì. Ó sì ju ọgọ́rùn-ún méjì [200] ìgbà lọ tí ọ̀rọ̀ náà wáìnì fara hàn nínú Bíbélì. (Jẹ́nẹ́sísì 27:25) Ìwé Oníwàásù 9:7 sọ pé: “Máa fi ayọ̀ yíyọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ kí o sì máa fi ọkàn-àyà tí ó yá gágá mu wáìnì rẹ.” Nítorí pé wáìnì máa ń mú kí inú èèyàn dùn, wọ́n sábà máa ń mu ún láwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣayẹyẹ, irú bí ayẹyẹ ìgbéyàwó. Èyí sì rán wa létí iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Jésù Kristi ṣe níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó kan, ìyẹn ìgbà tó sọ omi di “wáìnì àtàtà.” (Jòhánù 2:1-11) Wọ́n tún máa ń lo wáìnì gẹ́gẹ́ bí oògùn.—Lúùkù 10:34; 1 Tímótì 5:23.
Ǹjẹ́ Bíbélì sọ bí ọtí tó yẹ kéèyàn mu ṣe pọ̀ tó?
“Má ṣe di ẹrú fún ọ̀pọ̀ wáìnì.”—Títù 2:3.
KÍ NÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ?
Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ ìdílé ló ń jìyà torí pé bàbá àti ìyá tàbí ọ̀kan nínú wọn jẹ́ ọ̀mùtí paraku. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń ṣubú látàrí pé wọ́n ti mutí yó. Ọ̀pọ̀ jàǹbá, títí kan jàǹbá ọkọ̀ ló sì máa ń wáyé torí pé àwọn èèyàn mutí yó. Bí èèyàn bá sì ti wá sọ ọtí di bárakú, ó lè ṣàkóbá fún ọpọlọ, ọkàn, ẹ̀dọ̀ àti inú rẹ̀.
OHUN TÍ BIBÉLÌ SỌ
Ọlọ́run kò fẹ́ ká máa mu ọtí àmujù, kò sì fẹ́ ká máa jẹ àjẹjù. (Òwe 23:20; 1 Tímótì 3:2, 3, 8) Bí èèyàn ò bá kó ara rẹ̀ níjàánu nínú àwọn nǹkan yìí, kò ní rí ojú rere Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Afiniṣẹ̀sín ni wáìnì, aláriwo líle ni ọtí tí ń pani, olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣáko lọ kò gbọ́n.”—Òwe 20:1.
Ọ̀kan lára ọ̀nà tí ọtí lè gbà ṣàkóbá fún ẹni tí kò gbọ́n ni pé o lè mú kó nira fún un láti ṣe ohun tó tọ́. Ìwé Hóséà 4:11 sọ pé: “Wáìnì àti wáìnì dídùn ni ohun tí ń gba ète rere kúrò.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ John mú kó kẹ́kọ̀ọ́ kan tí kò lè gbàgbé láyé rẹ̀. * Nígbà kan, èdèkòyédè kan wáyé láàárín òun àti ìyàwó rẹ̀. Ló bá gba òtẹ́ẹ̀lì kan lọ, ó mutí yó kẹ́ri, ó sì bá obìnrin kan ṣèṣekúṣe. Nígbà tó yá ó kábàámọ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó sì sọ pé òun ò jẹ́ ṣerú ẹ̀ mọ́ láyé òun. Ó ṣe kedere pé, ọtí àmujù lè ṣàkóbá fún ìlera wa, ó lè mú ká ṣìwà hù, ó sì lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Bíbélì sì sọ pé àwọn ọ̀mùtípara, kò ní jogún ìyè àìnípẹ̀kun.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
Ìgbà wo ni kò yẹ kéèyàn mutí?
“Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 22:3.
KÍ NÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ?
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, World Book Encyclopedia sọ pé, “Oògùn tó lágbára gan-an ni ọtí.” Torí náà, láwọn ìgbà míì àti nínú àwọn ipò kan, kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn mutí rárá, ì báà tiẹ̀ jẹ́ díẹ̀.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Àwọn èèyàn sábà máa ń kó sínú “ìyọnu àjálù” nítorí pé wọ́n mu ọtí nìgbà tí kò yẹ. Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún.” Èyí sì kan ìgbà tí kò yẹ kéèyàn fẹnu kan ọtí rárá. (Oníwàásù 3:1) Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ orí ẹni kan lè ti kéré jù láti mu ọtí. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni ẹnì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ jáwọ́ nínú ọtí mímu. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni ẹlòmíì ń lo oògùn kan lọ́wọ́, tó sì jẹ́ pé irú oògùn bẹ́ẹ̀ kò gbọ́dọ̀ bá ọtí pàdé nínú ara. Fún ọ̀pọ̀ èèyàn, ìgbà tí wọ́n bá ń lọ sí ibiṣẹ́ àti ìgbà tí wọ́n bá wà ní ibiṣẹ́ jẹ́ “ìgbà tí a yàn kalẹ̀,” tí kò yẹ kí wọ́n mutí, pàápàá jù lọ tó bá jẹ́ pé ẹ̀rọ kan tó gba ìṣọ́ra gidigidi ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. Kò sí àní-àní pé àwọn tó jẹ́ ọlọgbọ́n gbà pé ẹ̀bùn iyebíye látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀mí àti ìlera jẹ́. (Sáàmù 36:9) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì nípa ọtí líle, ńṣe là ń fi hàn pé a mọyì àwọn ẹ̀bùn yìí.
^ ìpínrọ̀ 11 A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.