JÍ! November 2013 | Ohun Mẹ́ta Tí Owó Kò Lè Rà

Ohun ìní tara lè gbàfiyèsí wa ju àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù nígbèésí ayé​—àwọn ohun tí owó kò lè rà. Gbé àpẹẹrẹ mẹ́ta yẹ̀ wò.

Ohun Tó Ń Lọ Láyé

Lára ẹ ní: Sún-kẹrẹ-fà-kẹrẹ ọkọ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ ní Ṣáínà, bí wọ́n ṣe ń fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn du àwọn èèyàn ní Améníà, àwọn ewu tó wà nínú lílo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ní Japan àti bẹ́ẹ̀-bẹ́ẹ̀-lọ.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Bí Ọ̀rẹ́ Ìwọ Àtẹnì Kan Bá Ti Ń Wọra Jù

Ṣé o máa ń sọ pé, ‘Ọ̀rẹ́ lásán ni wá?’ Tó bá rí bẹ̀, ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Bíbélì tó máa jẹ́ kó o rí ìdí tí kò fi yẹ kí o ronú bẹ́ẹ̀.

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó ati fífi ara rora láwọn ọ̀nà tó ń mú ara gbóná.

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Dárí Ji Ara Yín

Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún wa láti dárí jini? Wo bí àwọn ìmọ̀ràn inú Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́.

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ìsoríkọ́

Kọ́ nípa ohun tó máa ń fa ìsoríkọ́ àti bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti kápá àwọn èrò tí kò tọ́.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ohun Mẹ́ta Tí Owó Kò Lè Rà

Owó máa ń jẹ́ ká lè ra àwọn nǹkan kan tá a nílò, àmọ́ owó ò lè ra àwọn ohun tó máa ń fún wa láyọ̀ jù.

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Bí Tata Katydid Ṣe Ń Gbọ́ràn Jọni Lójú Gan-an

Bí etí tata katydid kékeré yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ dà bíi ti èèyàn. Báwo ní ìwádìí nípa tata yìí á ṣe dá kún ìtẹ̀síwájú lágbo àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀?

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Kí Lo Lè Ṣe Tó O Bá Ní Àìsàn Tó Ò Ń Bá Fínra? (Apá 1)

Àwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin sọ ohun tó ń jẹ́ kí wọ́n lè máa fara da àìsàn tó ń ṣe wọ́n, kínú wọn sì máa dùn.

Ohun Táwọn Ojúgbà Rẹ Sọ Nípa Fífi Nǹkan Falẹ̀

Gbọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́ sọ nípa ewu tó wà nínú kéèyàn máa fi nǹkan falẹ̀ àti àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa jára mọ́ ohun tó ní í ṣe.