ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ
Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Dárí Ji Ara Yín
OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
Tí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ bá ń jiyàn, o sábà máa ń rán an létí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá àti àwọn èdèkòyédè tó yẹ kẹ́ ẹ ti yanjú tipẹ́tipẹ́. Kí ló fà á? Ó lè jẹ́ pé ọ̀kan lára yín tàbí ẹ̀yin méjèèjì kò mọ béèyàn ṣe ń dárí jini.
O lè kọ́ béèyàn ṣe ń dárí jini. Àmọ́, jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó lè mú kó ṣòro fún tọkọtaya láti máa dárí ji ara wọn.
OHUN TÓ FÀ Á
Agbára. Àwọn kan kì í fẹ́ dárí ji ọkọ tàbí aya wọn torí kí wọ́n lè máa rí ohun kan lò gẹ́gẹ́ bí agbára lórí ọkọ tàbí aya wọn. Tí èdèkòyédè bá wá ṣẹlẹ̀ láàárín wọn, wọ́n á wá rán ọkọ tàbí aya wọn létí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kó bàa lè jẹ́ pé àwọn ló máa borí nínú èdèkòyédè náà.
Ìkùnsínú. Tẹ́ni kan bá ṣe ohun tó dunni gan-an, kì í lọ bọ̀rọ̀ lọ́kàn ẹni. Ọkọ tàbí aya lè sọ pé ‘Mo dárí jì ẹ́,’ àmọ́ kó ṣì di ọ̀rọ̀ náà sínú, bóyá kó tiẹ̀ máa wá bó ṣe máa gbẹ̀san.
Ìjákulẹ̀. Àwọn kan máa ń ronú pé táwọn bá ti ṣègbéyàwó, ṣe ni gbogbo nǹkan á máa dùn yùngbà ṣáá lọ́jọ́ gbogbo. Tí èdèkòyédè bá wá ṣẹlẹ̀, ṣe ni wọ́n á bínú rangbandan pé kò yẹ kí ẹni tí wọ́n ronú pé wọ́n á jọ mọwọ́ ara wọn láìkù síbì kan lè ní irú èrò bẹ́ẹ̀. Bí èèyàn bá ń retí ohun tó pọ̀ jù, àwọn àṣìṣe ọkọ tàbí aya rẹ̀ nìkan lonítọ̀hún á máa rí, kò sì ní fẹ́ dárí jì í.
Èrò tí kò tọ́ nípa ìdáríjì. Àwọn tọkọtaya kan kì í fẹ́ dárí jini torí wọn kò ní èrò tó tọ́ nípa ìdáríjì. Bí àpẹẹrẹ wọ́n lè máa ronú pé:
Bí mo bá dárí jì í, kò ní mọ bí ohun tó ṣe yẹn ṣe burú tó.
Bí mo bá dárí jì í, a jẹ́ pé mo gbọ́dọ̀ gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn.
Bí mo bá dárí jì í, ó máa ṣe ohun tó tún jù bẹ́ẹ̀ lọ sí mi lọ́jọ́ míì.
Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn nǹkan yìí kọ́ ni ìdáríjì túmọ̀ sí. Síbẹ̀, kì í sábà rọrùn láti dárí jini, pàápàá láàárín àwọn tọkọtaya, torí wọ́n sún mọ́ra gan-an.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Ní èrò tó tọ́ nípa ìdáríjì. Nígbà míì, tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ìdáríjì,” ó lè túmọ̀ sí láti “yááfì.” Nítorí náà, pé o dárí ji ẹnì kan kò fi gbogbo ìgbà túmọ̀ sí pé o gbọ́dọ̀ gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀ tàbí kó o wò ó bíi pé kò tó nǹkan. Nígbà míì, ó lè jẹ́ pé ó kàn yẹ kó o yááfì ọ̀ràn náà ni, kí ara lè tù ẹ́, kí ìgbéyàwó rẹ má sì forí ṣánpọ́n.
Mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tí o kò bá dárí jini. Àwọn kan tí wọ́n ní ìmọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó sọ pé téèyàn bá ń di ọ̀rọ̀ sínú ó lè ṣàkóbá tó pọ̀ fún ìlera àti ìmọ̀lára ẹni, ó lè fa ìdààmú ọkàn àti ẹ̀jẹ̀ ríru, ó sì tún lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó ẹni. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà.”—Éfésù 4:32.
Mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú dídárí jini. Tí tọkọtaya bá ń dárí ji ara wọn, á jẹ́ kí wọ́n lè máa fọkàn tán ara wọn pé kò sẹ́ni tó ní ohun burúkú lọ́kàn sí ara wọn láàárín àwọn méjèèjì, èyí ò sì ní jẹ́ kí wọ́n máa di ara wọn sínú. Tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìbínú ò ní gbà wọ́n lọ́kàn, wọn á sì túbọ̀ máa fẹ́ràn ara wọn.—Ìlànà Bíbélì: Kólósè 3:13.
Má ṣe retí ohun tó pọ̀ jù. Ó máa túbọ̀ rọrùn láti dárí jini tó o bá ń fi sọ́kàn pé ọkọ tàbí aya rẹ kì í ṣe ẹni pípé ó sì ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tirẹ̀. Ìwé kan tó ń jẹ́ Fighting for Your Marriage, tó dá lórí ohun téèyàn lè ṣe tí ìgbéyàwó rẹ̀ ò fi ní tú ká sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé ohun tí ọwọ́ rẹ kò tẹ̀ lò ń rò ṣáá, kò ní pẹ́ rárá ti wàá fi gbàgbé pé ọ̀pọ̀ nǹkan wà tó o ní. Ṣé ìgbà yìí lo ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ máa ronú nípa àwọn nǹkan tó wù ẹ́ kó o ní, àmọ́ tí ọwọ́ rẹ kò tẹ̀? Rántí pé aláìpé ni gbogbo wa, kò sì yọ ìwọ alára sílẹ̀.—Ìlànà Bíbélì: Jákọ́bù 3:2.
Wò ó bóyá o lè gbójú fo ohun tó ṣẹlẹ̀. Tí ọkọ tàbí aya rẹ bá tún ti sọ nǹkan tàbí tó ṣe nǹkan tó dùn ẹ́, bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ohun tó ṣẹlẹ̀ náà tiẹ̀ ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Ṣé ó tó nǹkan tí màá tìtorí rẹ̀ máa retí pé kó tọrọ àforíjì, àbí mo lè gbójú fò ó kí gbogbo nǹkan lè máa lọ geere?’—Ìlànà Bíbélì: 1 Pétérù 4:8.
Bí o kò bá lè gbójú fò ó, ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Fara balẹ̀ ṣàlàyé ohun tó bí ẹ nínú, kí o sì sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ lára rẹ. Má ṣe ro èròkérò nípa ọkọ tàbí aya rẹ, má sì ṣe sọ̀rọ̀ tó máa fi han pé tiẹ̀ nìkan ló yé ẹ jù, torí èyí máa jẹ́ kóun náà fẹ́ gbèjà ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ ṣe tó dùn ẹ́ ni kó o sọ.