Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Bí Ọ̀rẹ́ Ìwọ Àtẹnì Kan Bá Ti Ń Wọra Jù

Bí Ọ̀rẹ́ Ìwọ Àtẹnì Kan Bá Ti Ń Wọra Jù

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

O ní ọ̀rẹ́kùnrin tàbí ọ̀rẹ́bìnrin kan tí ọ̀rọ̀ yín wọ̀ gan-an. Ẹ jọ máa ń sọ̀rọ̀ gan-an, kò sì sí ohun tí ẹ ò lè bá ara yín sọ. O máa ń sọ pé ‘Ọ̀rẹ́ lásán ni wá,’ àmọ́ o mọ̀ pé ọkọ tàbí ìyàwó rẹ máa rò pé nǹkan kan wà láàárín yín tó bá gbọ́ bẹ́ ẹ ṣe jọ ń sọ̀rọ̀.

O lè ti rí i pé ẹ ti sún mọ́ra jù, ó sì yẹ kó o wá nǹkan ṣe sí i. Àmọ́, jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó lè fà á tí wàá fi sún mọ́ ẹni tí kì í ṣe aya tàbí ọkọ rẹ tó bẹ́ẹ̀.

OHUN TÓ FÀ Á

Ìtẹ́lọ́rùn. Òótọ́ ni pé ó máa ń gbádùn mọni tí ọkùnrin àti obìnrin bá gba ti ara wọn. Inú wa máa ń dùn tá a bá mọ̀ pé ẹnì kan mọyì wa, ó sì máa ń jẹ́ ká gbà pé ìrísí wa fani mọ́ra. Tó bá ṣe díẹ̀ tó o ti ṣègbéyàwó, ó lè ṣẹlẹ̀ pé o bẹ̀rẹ̀ sí í finú han ẹnì kan tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ, kó sì máa wù ẹ́ láti wà pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́ o yẹ kó o rántí pé: Tó o bá sọ ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ di alábàárò, ó máa lẹ́yìn o. Tí ọkàn rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ, ó lè da àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ rú. Ìyẹn sì túmọ̀ sí pé o ti fi ìfẹ́ tó yẹ kó o fi hàn sí ọkọ tàbí aya rẹ dù ú.

• Bi ara rẹ pé, ‘Kí lohun tó yẹ kí ọkọ tàbí aya mi máa ṣe fún mi tí mo ti jẹ́ kí ọ̀rẹ́ mi yìí máa ṣe fún mi?’

Ohun kan ló tì ẹ́ débẹ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó bá ṣègbéyàwó máa ní “ìpọ́njú” láwọn ọ̀nà kan. (1 Kọ́ríńtì 7:28) Bí àpẹẹrẹ, nígbà míì ó lè ṣe ẹ́ bíi pé ọkọ tàbí aya rẹ pa ẹ́ tì tàbí kò mọyì rẹ, inú sì lè máa bí ẹ nítorí èdèkòyédè kan tẹ́ ò tíì yanjú. Ó sì lè jẹ́ pé ọkọ tàbí aya rẹ̀ kò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa èdèkòyedè náà, èyí sì ti tojú sú ẹ, ìyẹn ló fà á tó o fi yan ẹlòmíì lọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn kan tí wọ́n ní ìmọ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó sọ pé tí tọkọtaya kan kò bá yanjú ìṣòro kan tó le, irú àwọn tọkọtaya bẹ́ẹ̀ kò ní láyọ̀, kódà ó lè yọrí sí ìkọ̀sílẹ̀.

• Bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ìṣòro kan wà láàárín èmi àti ọkọ tàbí aya mi tó lè mú kí n máa wá ọ̀rẹ́ míì tí màá fi ṣe alábàárò?’

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Gbà pé ìṣòro wà. Bíbélì sọ pé: “Ṣé ọkùnrin kan lè wa iná jọ sí oókan àyà rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kí ẹ̀wù rẹ̀ gan-an má sì jóná?” (Òwe 6:27) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ìjàngbọ̀n lò ń fà lẹ́sẹ̀ tó o bá jẹ́ kí ọkàn ẹ máa fà sí ẹlòmíì lẹ́yìn tó o ti ṣe ìgbéyàwó. (Jákọ́bù 1:14, 15) Kì í ṣe ohun tó lè jẹ́ àbájáde rẹ̀ nìkan ló yẹ kó o máa rò. Ti pé ọkàn rẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹlòmíì lásán ti dá ìṣòro sílẹ̀. O ti lọ ń fún ẹlòmíì ní àfiyèsí tó yẹ kó o fún aya tàbí ọkọ rẹ, ẹ̀tọ́ rẹ̀ lo sì fi ń dù ú yẹn.

Má ṣe tan ara rẹ. Torí àwọn nǹkan kan tó o gbádùn nípa ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, báwo ni ì bá ṣe rí ká sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ yìí lo fẹ́ dípò ọkọ tàbí aya rẹ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o ti ń fi àwọn kùdìẹ̀- kudiẹ aya tàbí ọkọ rẹ wé àwọn ibi tí ọ̀rẹ́ rẹ yìí dára sí. Èyí kò sì dáa rárá! Rántí pé, bí nǹkan ṣe rí lára rẹ nígbà tó o pàdé ọ̀rẹ́ rẹ yìí náà ló ṣeé ṣe kó rí lára rẹ nígbà tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé aya tàbí ọkọ rẹ kó tó di pé ẹ fẹ́ra yín.—Ìlànà Bíbélì: Jeremáyà 17:9.

Pinnu ibi tí ọ̀rẹ́ yín máa mọ. Àwọn èèyàn máa ń fi ẹ̀rọ atanilólobó sí ọkọ̀ tàbí ilé wọn kí olè má bàa jà wọ́n. O lè ṣe ohun tó jọ ọ́ láti dáàbò bo ìgbéyàwó rẹ. Bíbélì sọ pé “ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ.” (Òwe 4:23) Báwo lo ṣe lè ṣe é? O lè lo àwọn àbá yìí:

  • Jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o ti ṣègbéyàwó, bóyá kó o fi àwòrán aya tàbí ọkọ rẹ síbi iṣẹ́ rẹ.—Ìlànà Bíbélì: Jẹ́nẹ́sísì 2:24.

  • Pinnu ohun tó o lè fàyè gbà àti ohun tí o kò jẹ́ fàyè gbà látọ̀dọ̀ ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya rẹ. Bí àpẹẹrẹ, kò ní bójú mu kó o máa sọ ìṣòro ìgbéyàwó rẹ fún irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ tàbí kí ọkùnrin tàbí obìnrin tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ gbé ẹ jáde lọ jẹun.

  • Bó bá jẹ́ pé ìwọ àti ẹnì kan tí kì í ṣe aya tàbí ọkọ rẹ ti sún mọ́ra jù, fòpin sí àjọṣe yín. Tó o bá rò pé ìyẹn ti le jù fún ẹ láti ṣe, ó yẹ kó o bi ara rẹ pé, kí nìdí tó fi nira fún mi? Má ṣe àwáwí nípa ìdí tó o fi fẹ́ máa bá ẹni náà ṣọ̀rẹ́, ṣe ni kó o ṣe ohun tó máa dáàbò bo ìgbéyàwó yín, kó o sì wà lẹ́yìn ọkọ tàbí aya rẹ gbágbáágbá.—Ìlànà Bíbélì: Òwe 5:18, 19.