Ṣé O Máa Ń Jẹ “Àsè Nígbà Gbogbo”?
“Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ yá gágá a máa jẹ àsè nígbà gbogbo.”—Òwe 15:15.
KÍ NI ìtumọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí? Ó ń sọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ bí inú wa bá dùn. Nǹkan tó bani lọ́kàn jẹ́ ni “ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́” máa ń gbé sọ́kàn, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó láyọ̀ torí pé ńṣe ni àwọn ọjọ́ rẹ̀ á máa “burú.” Àwọn nǹkan rere ni ẹni tí “ọkàn-àyà rẹ̀ yá gágá” máa ń gbé sọ́kàn, ńṣe ni inú irú èèyàn bẹ́ẹ̀ á máa dùn, ìyẹn sì ló máa jẹ́ kó lè máa jẹ “àsè nígbà gbogbo.”
Gbogbo wa la máa ń ní àwọn ìṣòro tó lè bà wá nínú jẹ́ nígbà míì. Síbẹ̀, àwọn nǹkan kan wà tá a lè máa ṣe táá máa fún wa láyọ̀ kódà láwọn àkókò tí nǹkan le koko. Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ.
Má ṣe jẹ́ kí àníyàn nípa ọ̀la mú kó o rẹ̀wẹ̀sì lónìí. Jésù Kristi sọ pé: “Ẹ má ṣe àníyàn nípa ọ̀la; nítorí ọ̀la ni nǹkan ti ọ̀la wà fún; wàhálà ti òní nìkan ti tó fún òní láìfi ti ọ̀la kún un.”—Mátíù 6:34, Ìròyìn Ayọ̀.
Gbìyànjú kó o máa ronú lórí àwọn nǹkan dáadáa tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ. Kódà láwọn ìgbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá mú ẹ, o ò ṣe kọ àwọn nǹkan dáadáa yẹn sílẹ̀, kó o sì máa fọkàn ro bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀? Bákan náà, má ṣe máa ronú ṣáá lórí àwọn àṣìṣe rẹ tàbí àwọn ohun tí kò dára tó o ti ṣe sẹ́yìn. Kọ́gbọ́n látinú àwọn àṣìṣe rẹ, kó o sì máa gbé ìgbé ayé rẹ lọ. Ńṣe ni kó o máa ṣe bíi ti àwọn awakọ̀ tó jẹ́ pé fírífírí ni wọ́n kàn máa ń wo gíláàsì tó ń jẹ́ kí wọ́n rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀yìn, àmọ́ tí wọn kì í tẹjú mọ́ ọn. Bákan náà, fi sọ́kàn pé “ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ [Ọlọ́run].”—Sáàmù 130:4.
Tí àníyàn bá bò ẹ́ mọ́lẹ̀, sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ẹnì kan tó lè dá ẹ lára yá. Òwe 12:25 sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” “Ọ̀rọ̀ rere” yìí lè wá látọ̀dọ̀ ẹbí wa kan tàbí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ kan tó ṣeé fọkàn tán tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ sí máa gbé wa ró.—Òwe 17:17.
Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ túbọ̀ láyọ̀ nígbèésí ayé wọn, kódà láwọn ìgbà tí nǹkan tiẹ̀ le koko pàápàá. Ǹjẹ́ káwọn ọ̀rọ̀ tó ṣeyebíye yẹn fún ìwọ náà láyọ̀.