ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | OJÚṢE ÒBÍ
Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Fífi Ọ̀rọ̀ Ìṣekúṣe Ránṣẹ́ Lórí Fóònù
OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO
Bóyá o ti gbọ́ pé àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń fi àwọn àwòrán àti ọ̀rọ̀ ìṣekúṣe ránṣẹ́ sí ara wọn lórí fóònù. O lè wá máa bi ara rẹ pé ‘Ṣé ọmọ mi lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣá?’
Báwo lo ṣe lè bá ọmọ rẹ jíròrò ọ̀rọ̀ yìí? Kó o tó dáhùn, jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ìdí tí àwọn ọ̀dọ́ kan fi máa ń fi àwòrán àti ọ̀rọ̀ tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìbálòpọ̀ ránṣẹ́ àti ìdí tí kò fi yẹ kó o fi ọ̀rọ̀ náà ṣe ọ̀rọ̀ ṣeréṣeré. a
ÌDÍ TÍ WỌ́N FI Ń DÁ ÀṢÀ NÁÀ
-
Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń fi àwọn ọ̀rọ̀ àti àwòrán tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìbálòpọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù láti fi bá ẹnì kan tí wọ́n fẹ́ràn tage.
-
Ọmọbìnrin kan lè fi àwòrán ìhòòhò ara rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọmọkùnrin kan torí pé ọmọkùnrin náà ń rọ̀ ọ́ ṣáá pé kó ṣe bẹ́ẹ̀.
-
Nígbà míì sì rèé, ọmọkùnrin kan lè fi àwòrán ìhòòhò ọmọbìnrin kan ránṣẹ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, bóyá láti fi dá wọn lára yá tàbí láti fi gbẹ̀san bí ọmọbìnrin náà ṣe já a jù sílẹ̀.
Ohun yòówù kó fà á, kókó ibẹ̀ ṣáà ni pé, tí ọmọ kan bá ti lè ní fóònù alágbèékà lọ́wọ́, ó lè kó o sí wàhálà. Ìwé kan tó ń jẹ́ CyberSafe sọ pé: “Bí èèyàn bá kàn fi ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán kan péré ránṣẹ́ látorí fóònù lásán, ó lè dá wàhálà tí kò ní lọ bọ̀rọ̀ sí ìgbésí ayé ẹni.”
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé gbàrà tí ẹnì kan bá ti fi àwòrán kan ránṣẹ́ sórí ìkànnì, onítọ̀hún kò láṣẹ lórí rẹ̀ mọ́, ohunkóhun sì làwọn tó bá rí àwòrán náà lè fi ṣe. Ìròyìn kan láti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé, ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún “fi àwòrán ìhòòhò ara rẹ̀ ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ látorí fóònù alágbèéká rẹ̀. Àmọ́ ńṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọléèwé rẹ̀ míì tún rí àwòrán náà gbà. A gbọ́ pé àwọn kan lára àwọn ọmọléèwé náà ń fi àwòrán náà ránṣẹ́ sáwọn míì, wọ́n sì tún ń fi ayé ni ọmọbìnrin náà lára. Èyí ló mú kí ọmọbìnrin náà gbẹ̀mí ara rẹ̀.”
Fífi àwòrán tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìbálòpọ̀ ránṣẹ́ tún lè di ọ̀ràn òfin. Bí àpẹẹrẹ, láwọn orílẹ̀-èdè kan, tí ọmọdé kan bá fi àwòrán tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ sí ọmọdé míì ńṣe ni ilé ẹjọ́ máa dá a lẹ́bi, tí wọ́n sì máa fi orúkọ irú ọmọ bẹ́ẹ̀ sára àwọn ọ̀daràn tó dá ẹ̀ṣẹ̀ ìbálòpọ̀! Ẹ̀yin òbí, ti ẹ kò bá ṣe àwọn ohun tó yẹ láti bójú tó àwọn ọmọ yín, ẹ̀yin náà lè jẹ̀bi lábẹ́ òfin orílẹ̀-èdè yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ọmọ yín dá.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
Ṣe àwọn òfin kan tó ṣe kedere. Òótọ́ ni pé o kò lè máa ṣọ́ ọmọ rẹ lọ́wọ́-lẹ́sẹ̀ kó o bàa lè mọ ohun tó ń ṣe lórí fóònù alágbèéká rẹ̀, àmọ́ o lè rí i dájú pé ọmọ rẹ mọ àwọn òfin tó o ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí, kó o sì jẹ́ kó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tó bá rú àwọn òfin náà. Ó sì yẹ kó o fi sọ́kàn pé gẹ́gẹ́ bí òbí, ojúṣe rẹ ló jẹ́ láti bójú tó bí ọmọ rẹ ṣe ń lo fóònù alágbèéká.—Ìlànà Bíbélì: Éfésù 6:1.
Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè ronú jinlẹ̀ lórí ìṣòro náà. O lè sọ pé: “Oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn máa ń sọ nípa fífi àwọn àwòrán tàbí ọ̀rọ̀ tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìbálòpọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù. Kí ni èrò tiẹ̀ nípa rẹ̀?” “Irú àwọn àwòrán wo lo rò pé kò bójú mu pé kéèyàn fi ránṣẹ́ lórí fóònù?” “Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ẹ̀sùn ọ̀daràn ni wọ́n máa fi ń kan àwọn ọmọdé tó bá ń fi àwòrán ìhòòhò ọmọdé mìíràn ránṣẹ́ látorí fóònù. Ṣé o rò pé ọ̀rọ̀ náà le tó bẹ́ẹ̀?” “Kí nìdí tó fi jẹ́ àṣà burúkú pé kéèyàn máa fi àwọn àwòrán àti ọ̀rọ̀ tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìbálòpọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù?” Tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí ọmọ náà bá ń sọ èrò rẹ̀, kó o sì ràn án lọ́wọ́ kó lè máa ronú nípa ohun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ yọ tó bá fi irú àwọn àwòrán tàbí ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ bẹ́ẹ̀ ránṣẹ́.—Ìlànà Bíbélì: Hébérù 5:14.
Ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tó o ti fi ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán ránṣẹ́ sẹ́nì kan
Fún un ní àpẹẹrẹ ohun kan tó lè ṣẹlẹ̀. O lè sọ fún ọmọbìnrin rẹ pé: “Ká sọ pé ọmọkùnrin kan ń rọ ọmọbìnrin kan pé kó fi àwòrán ìhòòhò ara rẹ̀ tàbí ti ẹlòmíì ránṣẹ́ sí òun tàbí pé kó fi ọ̀rọ̀ tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ sí òun. Kí ló yẹ kí ọmọbìnrin náà ṣe? Ṣé kó gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni torí kí ọmọkùnrin náà má bàa fi í sílẹ̀? Ṣé kó má ṣe gbà ni, àmọ́ kó ṣì máa bá ọmọkùnrin náà tage? Ṣé kó má ṣe bá ọmọkùnrin náà ṣọ̀rẹ́ mọ́ ni? Àbí ńṣe ni kí ọmọbìnrin náà sọ fún àgbàlagbà kan?” Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó bàa lè ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí. O lè lo irú ọ̀nà yìí náà láti jíròrò pẹ̀lú ọmọ rẹ ọkùnrin.—Ìlànà Bíbélì: Gálátíà 6:7.
Jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ ìdí pàtàkì tó fi yẹ kó máa hùwà rere. O lè béèrè irú àwọn ìbéèrè bíi: Ǹjẹ́ o mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn ní orúkọ rere? Irú ìwà wo lo fẹ́ káwọn èèyàn fi mọ̀ ẹ́? Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá kó ìtìjú bá ẹnì kan nípa fífi àwòrán tí kò bójú mu nípa onítọ̀hún ránṣẹ́ sórí fóònù ẹlòmíì? Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá ṣe ohun tó tọ́? Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó bàa lè “di ẹ̀rí-ọkàn rere mú.”—1 Pétérù 3:16.
Fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀. Bíbélì sọ pé ọgbọ́n tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá mọ́ níwà, kì í sì í ṣe àgàbàgebè. (Jákọ́bù 3:17) Ṣé bí ọ̀rọ̀ tiẹ̀ náà ṣe rí nìyẹn? Ìwé CyberSafe yẹn tún sọ pé: “Ó yẹ káwa òbí náà fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀, ká má ṣe wo àwọn àwòrán tí kò bójú mu, ká má sì ṣe lọ sórí àwọn ìkànnì tó ń gbé ìwàkiwà lárugẹ.”
a Lára ohun táwọn kan máa ń fi ránṣẹ́ ni àwòrán ẹni tó wà níhòòhò goloto, tàbí ti ẹni tó ṣí àwọn ibi kọ́lọ́fín ara sílẹ̀, tàbí kí wọ́n máa fi ọ̀rọ̀ tàbí fídíò ìbálòpọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù ẹlòmíì. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i, lọ sórí Ìkànnì jw.org, kó o sì ka àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè—Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Fífi Ọ̀rọ̀ àti Àwòrán Ìṣekúṣe Ránṣẹ́ Lórí Fóònù?”—Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN Ọ̀DỌ́.