OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Ìbẹ́mìílò
Ǹjẹ́ ó dára kéèyàn máa wá ọ̀nà láti bá òkú sọ̀rọ̀?
“Ẹ má ṣe yíjú sí àwọn abẹ́mìílò . . . láti di aláìmọ́ nípasẹ̀ wọn.”—Léfítíkù 19:31.
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ ohun tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ìyà kò jẹ èèyàn wọn tó ti kú. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń sọ pé: “O ò ṣe lọ sọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn abẹ́mìílò kó o lè bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀, bóyá wọ́n lè jẹ́ kó o mọ nǹkan kan nípa ẹni náà, kí ọkàn rẹ lè balẹ̀?”
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Láyé ọjọ́un, àwọn èèyàn máa ń fẹ́ bá àwọn òkú sọ̀rọ̀. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Òfin tí Jèhófà Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sọ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ń . . . wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí . . . tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú. Nítorí gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Diutarónómì 18:10-12) Bíbélì tún sọ pé gbogbo àwọn tó bá ń lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ́mìílò “kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—Gálátíà 5:19-21.
Ǹjẹ́ àwọn òkú lè ṣe nǹkan kan fún àwọn alààyè?
“Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.”—Oníwàásù 9:5.
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Ọ̀pọ̀ ló gbà gbọ́ pé àwọn òkú ṣì wà láàyè lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń fẹ́ bá òkú sọ̀rọ̀, bóyá kí wọ́n fẹ́ gbọ́ nǹkan kan lẹ́nu wọn tàbí kí wọ́n fẹ́ bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n fi àwọn alààyè lọ́rùn sílẹ̀.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Bíbélì sọ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá . . . Ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn àti owú [tí wọ́n ní kí wọ́n tó kú] ti ṣègbé nísinsìnyí.” (Oníwàásù 9:5, 6) Bí Bíbélì ṣe sọ gan-an ló rí, àwọn òkú kò mọ nǹkan kan! Àwọn òkú kò lè ronú, wọn ò lè ṣe nǹkan kan, wọn ò tiẹ̀ lè sin Ọlọ́run. Sáàmù 115:17 sọ pé: “Àwọn òkú kì í yin [Ọlọ́run], tàbí ẹnikẹ́ni tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ìdákẹ́jẹ́ẹ́.”
Kí la lè sọ nípa bí ọ̀rọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí bí wọ́n ṣe sọ ọ́ nígbà míì?
‘Ṣó yẹ kí àwọn èèyàn béèrè fún nǹkan lọ́wọ́ àwọn òkú nítorí àwọn alààyè?’—Aísáyà 8:19.
OHUN TÁWỌN KAN SỌ
Àwọn kan sọ pé àwọn abókùúsọ̀rọ̀ máa ń sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tó jẹ́ pé ẹni tó ti kú àti ìdílé rẹ̀ tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nìkan ló mọ̀ nípa rẹ̀.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
1 Sámúẹ́lì orí 28 sọ̀rọ̀ nípa Sọ́ọ̀lù Ọba tó di aláìṣòótọ́. Ó ṣe ohun tí Ọlọ́run ní wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe, ó lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Obìnrin kan tó máa ń bá òkú sọ̀rọ̀ ló lọ bá, obìnrin náà sì ṣe bíi pé òun bá ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tó ti kú sọ̀rọ̀, ìyẹn Sámúẹ́lì. Àmọ́ ṣe Sámúẹ́lì ló bá sọ̀rọ̀ lóòótọ́? Rárá o! Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ẹlòmíì ni obìnrin náà ń bá sọ̀rọ̀, ẹni náà ló ń díbọ́n bíi pé Sámúẹ́lì ló ń sọ̀rọ̀.
Ìránṣẹ́ Sátánì, “baba irọ́” ni ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú náà tó díbọ́n bíi pé òun ni Sámúẹ́lì. (Jòhánù 8:44) Kí nìdí táwọn ẹ̀mí burúkú, tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù, fi máa ń fẹ́ káwọn èèyàn rò pé ẹni tó ti kú ṣì wà láàyè? Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ ba Ọlọ́run lórúkọ jẹ́, wọ́n sì fẹ́ bẹnu àtẹ́ lu Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀.—2 Tímótì 3:16.
Ṣé ohun tá a wá ń sọ ni pé téèyàn bá ti kú, ó parí náà nìyẹn? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Bíbélì ṣèlérí pé àwọn òkú ṣì máa jí dìde. a (Jòhánù 11:11-13; Ìṣe 24:15) Ní báyìí, ọkàn wa balẹ̀ pé ìyà kankan kò jẹ àwọn èèyàn wa tó ti kú.
a Orí 7 ìwé náà Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? sọ pé “Ojúlówó Ìrètí Fáwọn Èèyàn Rẹ Tó Ti Kú.”