Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÀWỌN Ọ̀DỌ́

Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Ẹ Máa Darí Ẹ

Bó Ò Ṣe Ní Jẹ́ Káwọn Ojúgbà Ẹ Máa Darí Ẹ

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

“Àwọn ọmọléèwé mi máa ń sọ pé ibi tí ayé kọjú sí ni mo kẹ̀yìn sí, ó sì máa ń dùn mí gan-an. Torí náà, nígbà tí mo wọ iléèwé gíga mo bẹ̀rẹ̀ sí í hu àwọn ìwà tí kò dára, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í múra lọ́nà tí kò bójú mu. Ìdí sì ni pé, ó wù mí gan-an pé kémi náà ní àwọn ọ̀rẹ́ tó máa gba tèmí dáadáa.”—Jennifer, ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16]. a

Ṣé ìwọ náà máa ń fẹ́ ṣe bíi tàwọn ojúgbà rẹ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe.

Tó bá jẹ́ pé gbogbo nǹkan táwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá fi lọ̀ ẹ́ náà lo máa ń ṣe, o ò yàtọ̀ sí ẹ̀rọ bọrọgidi kan tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa ń tì í ṣiṣẹ́, torí pé àwọn ẹlòmí ló ń darí ẹ. Kí nìdí tó o fi máa gbà kí àwọn míì sọ ẹ́ di ẹrú wọn?—Róòmù 6:16.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe ni ìwọ náà fẹ́ máa ṣe, ó lè sọ ọ́ di èèyàn burúkú.

“Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́ríńtì 15:33.

“Kì í kúkú ṣe pé a ò mọ ohun tí kò dára, àmọ́ táwọn ọ̀rẹ́ wa bá ni ká wá ṣe nǹkan ọ̀hún, kò ní sóhun tá a máa ṣe ju pé ká gbà pẹ̀lú wọn lọ, ká ṣáà lè tẹ́ wọn lọ́rùn!”—Dana.

Kì í ṣe gbogbo ìgbà náà ló jẹ́ pé àwọn ojúgbà rẹ ló ń fipa mú ẹ ṣe ohun tí kò dára.

“Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.”—Róòmù 7:21.

“Èmi gan-an ni mò ń fa ìṣòro fún ara mi. Ká sòótọ́, ọ̀nà táwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń gbà sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe ló máa ń jẹ́ kó wù mí gan-an láti ṣe àwọn nǹkan náà.”—Diana.

Ohun ìwúrí ló jẹ́ tí o kò bá gbà kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ fipá mú ẹ ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe.

“Di ẹ̀rí-ọkàn rere mú.”—1 Pétérù 3:16.

“Nígbà kan, ó ṣòro gan-an fún mi láti kọ̀ jálẹ̀ nígbà táwọn ọ̀rẹ́ mi bá ní kí n wá ṣe nǹkan tí mo mọ̀ pé kò dára. Àmọ́ ní báyìí, ojú kì í tì mí mọ́ láti dá yàtọ̀, mo sì máa ń dúró lórí ìpinnu mi. Kò sóhun tó dà bíi pé kéèyàn máa lọ sùn lálaalẹ́ pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.”—Carla.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Táwọn ọ̀rẹ́ rẹ bá ní kó o ṣe ohun tí kò dára, gbìyànjú kó o ṣe àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí:

Ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀. Bi ara rẹ pé, ‘Tí mo bá gbà láti ṣe ohun táwọn ojúgbà mi ní kí n ṣe yìí, tí ọwọ́ sì wá lọ tẹ̀ mí ńkọ́? Kí làwọn òbí mi á máa rò nípa mi? Báwo ló ṣe máa rí lára èmi fúnra mi?’—Ìlànà Bíbélì: Gálátíà 6:7.

“Àwọn òbí mi béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Tó o bá gbà láti ṣe ohun táwọn ojúgbà rẹ ní kó o ṣe, kí lo rò pé ó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ?’ Wọ́n jẹ́ kí n rí i pé tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun táwọn ojúgbà mi ń ṣe ni mo fẹ́ máa bá wọn ṣe, ó lè ba ayé mi jẹ́.”—Olivia.

Mú kí ohun tó o gbà gbọ́ túbọ̀ dá ẹ lójú. Bi ara rẹ pé, ‘Kí nìdí tí mo fi gbà pé ohun tí wọ́n ní kí n ṣe yìí lè ṣàkóbá fún èmi tàbí àwọn ẹlòmíì?’—Ìlànà Bíbélì: Hébérù 5:14.

“Nígbà tí mo ṣì kéré, tí wọ́n bá ti fi ohun tí kò dára lọ̀ mí, ńṣe ni mo kàn máa ń sọ pé mi ò ṣe tàbí kí n kàn ṣáà wá nǹkan kan sọ. Àmọ́ ní báyìí, mo máa ń ṣàlàyé dáadáa lórí ìdí tí mo fi máa ṣe nǹkan kan tàbí tí mi ò fi ní ṣe é. Ohun tí mo gbà gbọ́ nípa ohun tó dára àti ohun tí kò dára dá mi lójú gan-an. Èmi fúnra mi ni mò ń dá wọn lóhùn, kì í ṣe pé ẹnì kan ló ń sọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu.—Anita.

Máa ronú nípa irú èèyàn tó wù ẹ́ pé kó o jẹ́. Bi ara rẹ pé, ‘Irú èèyàn wo ló wù mí kí n jẹ́?’ Wá ronú nípa ohun táwọn ojúgbà ẹ ní kó o ṣe, kó o tún wá bi ara rẹ pé, ‘Kí ni irú èèyàn tó wù mí kí n jẹ́ máa ṣe tí wọ́n bá ní kó ṣe irú nǹkan báyìí?—Ìlànà Bíbélì: 2 Kọ́ríńtì 13:5.

“Ó tẹ́ mi lọ́rùn bí mo ṣe wà yìí, torí náà mi ò kì í da ara mi láàmú nípa ohun táwọn ẹlòmíì ń rò nípa mi. Ohun kan tiẹ̀ tún wá ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń nífẹ̀ẹ́ mi, torí bí mi ò ṣe kí ń díbọ̀n hùwà bíi tàwọn ẹlòmíì.”—Alicia.

Máa ro ẹ̀yìn ọ̀la. Tó bá jẹ́ pé o ṣì wà níléèwé, tá a bá fi máa rí ọdún tàbí oṣù bíi mélòó kan sígbà tá a wà yìí, àwọn tí ò ń wá bí wọ́n ṣe máa gba tìẹ báyìí lè wá dẹni tí kò ṣe pàtàkì sí ẹ mọ́.

“Nígbà tí mò ń wo fọ́tò kan témi àtàwọn ọmọ kíláàsì mi jọ yà, àwọn kan wà níbẹ̀ tí mi ò tiẹ̀ rántí orúkọ wọn mọ́ rárá. Àmọ́ nígbà tá a jọ wà níléèwé, ohun tí wọ́n bá sọ fún mi ṣe pàtàkì sí mi ju ohun témi fúnra mi gbà gbọ́ lọ. Ẹ ò rí i pé ìwà òmùgọ̀ gbáà nìyẹn!”—Dawn, tó ti pé ọmọ ọdún méjìlélógún [22] báyìí.

Múra Sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.’Kólósè 4:6.

“Àwọn òbí mi máa ń sọ pé kí èmi àti àbúrò mi obìnrin ronú nípa àwọn nǹkan kan tó lè ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn náà, àwa méjèèjì á wá ṣe ìdánrawò, bí ẹni pé ohun náà ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Èyí máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe nígbà tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀.”—Christine.

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.