OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ
Amẹ́ríkà
Ìwé ìròyìn New York Times sọ pé “Tí òṣìṣẹ́ kan tó ń ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ àdáni bá ń mu sìgá, iye tó máa ná agbanisíṣẹ́ rẹ̀ lọ́dún kan . . . á fi $5,816 [èyí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ́nù kan náírà] ju ti ẹni tí kì í mu sìgá lọ.” Ìsọfúnni táwọn aṣèwádìí kan ní Ohio State University kó jọ jẹ́ ká mọ̀ pé àfikún owó yìí jẹ́ torí àyè táwọn tó ń mu sìgá ń gbà lẹ́nu iṣẹ́ láti fi mu sìgá tàbí owó tó máa ná wọn láti fi tọ́jú ara tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ lè wá síbi iṣẹ́. Ìṣòro míì ni pé wọn kì í lè ṣiṣẹ́ dáadáa, bóyá torí ràbọ̀ràbọ̀ tó máa ń bá àwọn tí sìgá bá ti wọnú ẹ̀jẹ̀ wọn.
Ítálì
“Ìwà àgàbàgebè kún ọwọ́ àwọn pásítọ̀, ìwà àwọn onígbàgbọ́ kò sì bá ohun tí wọ́n ń sọ mu. Àwọn nǹkan yìí ni kò jẹ́ káwọn èèyàn fojú pàtàkì wo ṣọ́ọ̀ṣì mọ́.”—Póòpù Francis.
Malaysia
Ìjọba orílẹ̀-èdè Malaysia rí eyín erin tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan tí wọ́n fi pa mọ́ sínú ọkọ méjì tó kó igi gẹdú. Àwọn tó ń jà fún ààbò àwọn ohun alààyè sọ pé, wọn ò tíì ká eyín erin tó pọ̀ tó báyìí mọ́ àwọn onífàyàwọ́ lọ́wọ́ rí. Orílẹ̀-èdè Tógò ni wọ́n ti ń kó o bọ̀, orílẹ̀-èdè Ṣáínà ni wọ́n sì ń kó o lọ.
Áfíríkà
Lọ́dún 2012, Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé ìdá mẹ́tàlélọ́gọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún lára ohun tó ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn jù lọ ni àwọn àrùn tó lè ranni bí, éédì, ìgbẹ́ gbuuru, ibà, ikọ́ ẹ̀gbẹ àti onírúurú àwọn àìsàn tó máa ń ṣe àwọn ọmọdé.
Ọsirélíà
Àwọn ètò kan tí èèyàn ti lè bá kọ̀ǹpútà ta tẹ́tẹ́ tí wọ́n ń ṣe sórí àwọn fóònù ìgbàlódé àtàwọn ẹ̀rọ míì ti wọ́pọ̀ gan-an lọ́wọ́ àwọn ọmọdé báyìí. Àwọn ètò orí fóònù kan wà tó jọra gan-an pẹ̀lú ohun tí wọ́n máa ń lò nílé tẹ́tẹ́, àmọ́ ti orí fóònù rọrùn láti jẹ. Ìjọba orílẹ̀-èdè kan ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú káwọn ọmọdé rí tẹ́tẹ́ títa bí ohun tí kò burú. “Ó sì lè mú kí wọ́n sọ tẹ́tẹ́ títa di bárakú lọ́jọ́ iwájú.”