Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Nǹkan Bá Tojú Sú Ọmọ Rẹ Obìnrin

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Nǹkan Bá Tojú Sú Ọmọ Rẹ Obìnrin

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Ọmọ rẹ obìnrin sọ pé gbogbo nǹkan tojú sú òun. Ó yà ẹ́ lẹ́nu láti gbọ́ bẹ́ẹ̀, lo bá bi ara rẹ pé, ‘Kí lọmọ ọdún mẹ́tàlá mọ̀ tó ń jẹ́ pé nǹkan tojú súni?’ ‘Kò tíì dàgbà tó ẹni tí nǹkan ń tojú sú!’ Kó tó di pé o sọ irú ọ̀rọ̀ yìí sí ọmọ rẹ, jẹ́ ká wo àwọn nǹkan bíi mélòó kan tó lè fayé sú àwọn ọmọbìnrin.

ÌDÍ TÓ FI MÁA Ń ṢẸLẸ̀

Àwọn àyípadà inú ara. Àwọn nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ọmọbìnrin bá bàlágà máa ń mú ìnira díẹ̀ lọ́wọ́. Ohun tó sì máa ń dá kún ìnira tàbí àìfararọ yìí ni pé tí ọmọbìnrin kan bá kíyè sí i pé àwọn ìyipadà kan ò tíì wáyé lára rẹ̀ bíi táwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tàbí tó jẹ́ pé ó tètè bàlágà ṣáájú àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Anna a tó ti pé ọmọ ogún ọdún báyìí sọ pé: “Láàárín àwọn ẹgbẹ́ mi, mo wà lára àwọn tó kọ́kọ́ wọ bùrèsíà, èyí kì í jẹ́ kí ara mi balẹ̀ rárá. Tí mo bá wà pẹ̀lú àwọn ojúgbà mi, ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò bẹ́gbẹ́ mu rárá!”

Ìmọ̀lára tó ń yí pa dà. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Karen, tó ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún báyìí sọ pé: “Ó máa ń tojú sú mi bí ìmọ̀lára mi ṣe máa ń yí pa dà bìrí. Inú mi á dùn lójú ọjọ́ àmọ́ nígbà tó bá fi máa di alẹ́ ńṣe ni màá kàn máa wa ẹkún mu bí omi. Ọ̀rọ̀ ara mi ò yé mi rárá. Mi ò sì mọ ohun tí mo lè ṣe sí i.”

Tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan oṣù. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Kathleen sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi ti ṣàlàyé bí nǹkan ṣe máa rí fún mi tẹ́lẹ̀, síbẹ̀ mi ò múra sílẹ̀ rárá nígbà tí mo kọ́kọ́ rí nǹkan oṣù mi. Àìmọye ìgbà ni mo máa ń wẹ̀ lójúmọ́, torí ó máa ń ṣe mí bíi pé mo dọ̀tí gan-an. Àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ò tiẹ̀ káàánú mi rárá, ńṣe ni wọ́n máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Níbi ti ara ti ń ni mí nítorí nǹkan oṣù tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í rí, eré làwọn ka gbogbo ẹ̀ sí.”

Ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Marie tó ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] báyìí náà sọ ohun tó jọ èyí, ó ní: “Nígbà tí mo wà láàárín ọmọ ọdún méjìlá sí mẹ́rìnlá, kò rọrùn rárá fún mi láti sọ pé mi ò bá àwọn ojúgbà mi ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe. Bí ẹnì kan bá sọ pé òun ò bá àwọn ọmọléèwé mi ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe, ńṣe ni wọ́n máa ń fayé ni onítọ̀hún lára.” Anita ọmọ ọdún mẹ́rìnlá sọ pé: “Fún àwọn tó wà ní ọjọ́ orí mi yìí, nǹkan pàtàkì ni pé kí èèyàn bẹ́gbẹ́ pé. Ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń báni táwọn ọ̀rẹ́ bá pani tì kì í ṣe kékeré.”

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Ran ọmọbìnrin rẹ lọ́wọ́ kó lè sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro rẹ̀. Ọmọ rẹ lè má kọ́kọ́ fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro rẹ̀. Torí náà, o gbọ́dọ̀ ṣe sùúrù kó o sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì tó sọ pé “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”—Jákọ́bù 1:19.

Má fojú kéré ohun tí ọmọ rẹ bá sọ fún ẹ. Rántí pé ọmọ rẹ ò nírìírí tó ẹ, kò ní irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ rí, kò sì mọ ohun tó lè ṣe sí i.—Ìlànà Bíbélì: Róòmù 15:1.

Má fi iṣẹ́ pá ọmọ rẹ lórí. Ìwé kan tó ń jẹ́ Teach Your Children Well, sọ pé àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n fi iṣẹ́ pá lórí “sábà máa ń sọ pé nǹkan tojú sú àwọn, àárẹ̀ tó sì máa ń ṣe wọ́n jù ni ẹ̀fọ́rí àti inú rírun.”—Ìlànà Bíbélì: Fílípì 1:9, 10.

Rí i pé ọmọbìnrin rẹ ń sinmi dáadáa. Bí nǹkan bá ti tojú sú àwọn ọmọbìnrin, ó sábà máa ń gba oorun lójú wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, bí wọn ò bá sùn dáadáa, wọn ò ní lè ronú bó ṣe yẹ, nǹkan ò sì ní yéé tojú sú wọn.—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 4:6.

Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè máa ṣohun tó máa mú kí ara tù ú tí nǹkan bá fẹ́ tojú sú u. Táwọn ọmọbìnrin kan bá ṣe eré ìdárayá, ó máa ń dín ìdààmú ọkàn wọn kù. Bíbélì sọ pé, “Ènìyàn a máa rí àǹfààní . . . tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá.” (1 Tímótì 4:8, Ìròhìn Ayọ̀) Ohun tó máa ń ran àwọn ọmọbìnrin míì lọ́wọ́ láti kápá ìdààmú ọkàn wọn ni pé, wọ́n máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣòro tí wọ́n bá ní. Brittany, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì kéré, mo máa ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣòro tí mi ò tíì lè yanjú. Èyí máa ń jẹ́ kí n mọ bí ìṣòro kan ṣe rí lára mi, á sì wá rọrùn fún mi láti wá ojúùtú sí ìṣòro náà tàbí kí n gbé e kúrò lọ́kàn.”

Fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀. Báwo lo ṣe máa ń ṣe tí nǹkan bá tojú sú ẹ? Ṣé o kì í wa nǹkan tó pọ̀ jù máyà débi pé ọkàn rẹ ò ní balẹ̀ tó o bá ń ṣe é? Ṣé o kì í fara ṣiṣẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ, débi pé o kì í ráyè fún àwọn nǹkan tó ṣè pàtàkì jù nígbèésí ayé rẹ? Fílípì 4:5 sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” Má gbàgbé pé ọmọ rẹ ń wò ẹ́, àpẹẹrẹ rẹ ló sì máa tẹ̀ lé, ìbáà jẹ́ rere tàbí búburú.

a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.