‘Ọgbọ́n Ń ké Jáde’ Ṣé Ò Ń gbọ́ Ohun Tó Ń sọ?
“Ọgbọ́n kò ha ń bá a nìṣó ní kíké jáde, tí ìfòyemọ̀ sì ń bá a nìṣó ní fífọ ohùn rẹ̀ jáde? Ní orí àwọn ibi gíga, lẹ́bàá ọ̀nà, ibi ìsọdá àwọn òpópónà ni ó dúró sí. . . . Ibi àtiwọ àwọn ẹnu ọ̀nà ni ó ti ń ké tòò.”—ÒWE 8:1-3.
ỌGBỌ́N ṣe pàtàkì gan-an. Téèyàn ò bá gbọ́n, ìwà òmùgọ̀ ni yóò máa hù ṣáá. Àmọ́ ibo la ti lè rí ọgbọ́n gidi? Ohun tí ẹni tó kọ ìwé Òwe ní lọ́kàn ni ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá wa tí kò láfiwé. Èèyàn tún lè rí ọgbọ́n yẹn nínú ìwé kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó gbogbo èèyàn, ìyẹn Bíbélì. Gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò:
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia sọ pé, Bíbélì ni “ìwé tí a pín kiri jù lọ láyé. Wọ́n ti túmọ̀ rẹ̀ níye ìgbà tí ó pọ̀ àti sí iye èdè tí ó pọ̀, ju ti ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ.” Wọ́n ti túmọ̀ odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ sí ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀tàlá [2,600] èdè, tó fi jẹ́ pé ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó èyí tó pọ̀ jù nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.
Ọ̀nà míì tún wà tá a fi lè sọ pé “ọgbọ́n ń bá a nìṣó ní kíké jáde.” Mátíù 24:14 sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin [ayé yìí] yóò sì dé.”
Ọgbọ́n gidi ni “ìhìn rere” yìí jẹ́ tori ó ń tọ́ka sí ọgbọ́n tí Ọlọ́run á fi yanjú ìṣòro aráyé, ìyẹn Ìjọba Rẹ̀. Ọlọ́run ló ni Ìjọba náà, ó sì máa ṣàkóso lé gbogbo ayé lórí, kí gbogbo aráyé lè wà níṣọ̀kan, lábẹ́ ìjọba kan. (Dáníẹ́lì 2:44; 7:13, 14) Ìdí nìyẹn tí Jésù Kristi fi gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ní ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run ní ilẹ̀ tí ó tó igba ó lé mọ́kàndínlógójì [239]! Bẹ́ẹ̀ ni, ọgbọ́n Ọlọ́run, “ń ké tòò” àní ní “ibi àtiwọ àwọn ẹnu ọ̀nà.” Ṣé ò ń gbọ́ ohun tó ń sọ?