OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Ìsìn
Kí nìdí tí ìsìn fi pọ̀ gan-an lónìí?
“Ní pípa àṣẹ Ọlọ́run tì, ẹ̀yin di òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ti ènìyàn mú ṣinṣin.”—Máàkù 7:8.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ jọ́sìn Ọlọ́run. (Mátíù 5:3) Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi dá ọ̀pọ̀ ìsìn sílẹ̀. Àmọ́ dípò kí wọ́n máa fi ẹ̀kọ́ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn, èrò tiwọn ni wọ́n fi ń kọ́ni.
Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ nípa àwùjọ ìsìn kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní pé: “Wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye; nítorí, fún ìdí náà pé wọn kò mọ òdodo Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbé tiwọn kalẹ̀, wọn kò fi ara wọn sábẹ́ òdodo Ọlọ́run.” (Róòmù 10:2, 3) Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìsìn tó wà lónìí ló ń fi “àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́.”—Máàkù 7:7.
Ṣé ó pọn dandan kéèyàn dara pọ̀ mọ́ ìsìn kan pàtó?
“Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.”—Hébérù 10:24, 25.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Ìwé Hébérù 10:25 lo gbólóhùn náà “kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.” Gbólóhùn yẹn fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn èèyàn máa péjọ lọ́nà tó wà létòletò láti jọ́sìn òun. Àmọ́, ṣé ohun tó bá wu kálukú ló lè gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run àti ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́? Rárá o. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé, kí gbogbo àwọn tó bá ń sin Ọlọ́run ní ọ̀nà tó fẹ́ “máa sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan” kí a sì “so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.” (1 Kọ́ríńtì 1:10) Ó tún sọ pé kí wọ́n ṣètò wọn ní ìjọ ìjọ, kí wọ́n sì “ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará” tó wà kárí ayé. (1 Pétérù 2:17; 1 Kọ́ríńtì 11:16) Ó sì ṣe pàtàkì kí àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run wà létòletò àti ní ìṣọ̀kan kí ìjọsìn wọn lè ní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti dá ìsìn tòótọ́ mọ̀?
“Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Nígbà tí Bíbélì ń ṣe àpèjúwe kan nípa bá a ṣe lè dá àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀, ó sọ pé: “Nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá wọn mọ̀. Àwọn ènìyàn kì í kó èso àjàrà jọ láti ara ẹ̀gún tàbí ọ̀pọ̀tọ́ láti ara òṣùṣú, wọ́n ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí?” (Mátíù 7:16) Kò dìgbà téèyàn bá jẹ́ onímọ̀ nípa ewéko kó tó lè mọ ìyàtọ̀ láàárín igi ọ̀pọ̀tọ́ àti òṣùṣú. Bákan náà, kò dìgbà téèyàn bá jẹ́ ògbóǹkangí nínú ìsìn kó tó lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké. Kí ni díẹ̀ lára ohun tá a fi ń dá ìsìn tòótọ́ mọ̀?
-
Ìsìn tòótọ́ máa ń fi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni, kì í kọ́ni ní ọgbọ́n orí èèyàn.—Jòhánù 4:24; 17:17.
-
Ìsìn tòótọ́ máa ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run, títí kan orúkọ rẹ̀, ìyẹn Jèhófà.—Jòhánù 17:3, 6.
-
Ìsìn tòótọ́ máa ń kéde pé Ìjọba Ọlọ́run ni ìrètí kan ṣoṣo táráyé ní kì í ṣe ìjọba èèyàn.—Mátíù 10:7; 24:14.
-
Ìfẹ́ tòótọ́ máa ń wà láàárín àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́. (Jòhánù 13:35) Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹ̀yà míì. Wọ́n máa ń lo àkókò wọn àti ohun tí wọ́n ní láti fi ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Wọ́n sì tún máa ń kọ́ wọn láti má ṣe lọ́wọ́ sí ogun tó wà káàkiri.—Míkà 4:1-4.
-
Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń fi ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù, wọn kì í fi ẹnu lásán jọ́sìn Ọlọ́run. Wọ́n sì máa ń gbé ìgbésí ayé wọn ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n ń wàásù.—Róòmù 2:21; 1 Jòhánù 3:18.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde, a sì ń sapá láti bọlá fún Ọlọ́run nínú ọ̀rọ̀ ẹnu àti ìwà wa. Gbìyànjú kí o lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa lọ́jọ́ kan, kó o lè rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.